Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ | ANTONIO DELLA GATTA

Ohun Tó Mú Kí Àlùfáà Kan Fi Ṣọ́ọ̀ṣì Sílẹ̀

Ohun Tó Mú Kí Àlùfáà Kan Fi Ṣọ́ọ̀ṣì Sílẹ̀

LẸ́YÌN tí Antonio Della Gatta ti fi ọdún mẹ́sàn-án kẹ́kọ̀ọ́ nílùú Róòmù, ó gba oyè àlùfáà lọ́dún 1969. Nígbà tó yá, ó di olórí ilé ẹ̀kọ́ ìsìn nítòsí Naples nílẹ̀ Ítálì. Nígbà tó wà níbẹ̀, ó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ ó sì ṣàṣàrò gan-an, ó wá rí i pé ẹ̀sìn Kátólíìkì kò bá ẹ̀kọ́ Bíbélì mu rárá. Òun àtàwọn tó ń kọ ìwé ìròyìn Jí! jọ sọ̀rọ̀, ó sì ṣàlàyé àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i kó tó di pé ó mọ Ọlọ́run.

Báwo ni nǹkan ṣe rí nígbà tó o wà ní kékeré?

Wọ́n bí mi ní Ítálì lọ́dún 1943. Abúlé kékeré kan ni wọ́n ti tọ́ èmi, àwọn ẹ̀gbọ́n àtàwọn àbúrò mi dàgbà. Iṣẹ́ àgbẹ̀ àti káfíńtà ni bàbá mi ń ṣe. Ẹ̀sìn Kátólíìkì làwọn òbí mi ń ṣe, a ò sì fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn náà ṣeré.

Kí nìdí tó o fi fẹ́ di àlùfáà?

Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo fẹ́ràn láti máa gbọ́rọ̀ àwọn àlùfáà ní ṣọ́ọ̀ṣì. Ohùn wọn máa ń tù mí lára gan-an, orí mi sì máa ń wú bí wọ́n ṣe máa ń darí ìsìn. Torí náà, mo pinnu pé màá di àlùfáà. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá, ìyá mi mú mi lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn ọmọkùnrin níṣẹ́ àlùfáà, ibẹ̀ sì ni mò ń gbé.

Ṣé wọ́n kọ́ yín lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tẹ́ ẹ lọ sílé ẹ̀kọ́ àlùfáà?

A ò fi bẹ́ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún, ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ mi fún mi ní ẹ̀dà Ìwé Ìhìn Rere, ìyẹn àkọsílẹ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ rẹ̀, mo sì kà á léraléra. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, mo lọ sí Róòmù kí n lè kẹ́kọ̀ọ́ ní yunifásítì àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tó wà lábẹ́ àṣẹ póòpù. Mo kọ́ èdè Látìn, èdè Gíríìkì, ẹ̀kọ́ ìtàn, ìmọ̀ ọgbọ́n orí, ẹ̀kọ́ nípa ìṣesí ẹ̀dá àti ẹ̀kọ́ ìsìn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń ka àkọ́sórí látinú Bíbélì, a sì máa ń gbọ́ tí wọ́n ń ka Bíbélì nígbà ìwàásù ọjọ́ Sunday, àmọ́ a kì í dìídì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Nígbà tó o di àlùfáà, tó o sì ń bójú tó àwọn nǹkan kan nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì, ṣé ìwọ náà máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́?

Iṣẹ́ àbójútó ni mò ń ṣe. Àmọ́ mò ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nígbà tí Ìgbìmọ̀ Vatican Kejì bá ní kí n ṣe bẹ́ẹ̀.

Kí nìdí tó o fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì nípa ṣọ́ọ̀ṣì rẹ?

Ohun mẹ́ta ló ń dà mí láàmú. Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń lọ́wọ́ nínú òṣèlú. Ìwàkiwà kún ọwọ́ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Kátólíìkì, àwọn ọmọ ìjọ sì ń ṣe bó ṣe wù wọ́n torí kò sẹ́ni tó ń bá wọn wí. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì kan ò tọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, báwo ni Ọlọ́run ìfẹ́ á ṣe máa fìyà jẹ àwọn èèyàn títí láé lẹ́yìn tí wọ́n ti kú? Bákan náà, ṣé Ọlọ́run fẹ́ ká máa fi ìlẹ̀kẹ̀ gbàdúrà sí òun ní àgbà-tún-gbà? *

Kí lo ṣe sọ́rọ̀ náà?

Mo gbàdúrà pẹ̀lú omijé lójú pé kí Ọlọ́run tọ́ mi sọ́nà. Mo tún ra Bíbélì Jerusalem Bible ti Kátólíìkì, èyí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀ jáde lédè Italian, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Lẹ́yìn náà, láàárọ̀ ọjọ́ Sunday kan bí mo ṣe ń fi aṣọ mi kọ́ lẹ́yìn tí mo ṣe ìsìn Máàsì tán ni ọkùnrin méjì wá sí ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn wa. Wọ́n ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn. A fi ohun tó ju wákàtí kan sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, wọ́n sì jẹ́ kí n mọ àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ pé a lè fi dá ẹ̀sìn tòótọ́ mọ̀.

Kí lèrò ẹ nípa àwọn àlejò náà?

Mo mọyì bí ohun tí wọ́n sọ ṣe dá wọn lójú àti bó ṣe rọ̀ wọ́n lọ́rùn láti tọ́ka sí ohun tó wà nínú ẹ̀dà Bíbélì ti Kátólíìkì. Nígbà tó yá, Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì tó ń jẹ́ Mario bẹ̀rẹ̀ sí í wá sọ́dọ̀ mi. Onísùúrù èèyàn ni, kì í sì í yẹ àdéhùn, torí ni gbogbo àárọ̀ ọjọ́ Sátidé, kò sí bójú ọjọ́ ti lè burú tó, á ti dé láago mẹ́sàn-án, á sì tẹ aago ẹnu ọ̀nà ilé ẹ̀kọ́ ìsìn wa.

Kí ni àwọn àlùfáà yòókù rò nípa àwọn tó ń wá sọ́dọ̀ ẹ?

Mo ní kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ wa nígbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́, ṣùgbọ́n kò sẹ́nì kankan nínú wọn tó ka ẹ̀kọ́ náà sí. Àmọ́ ní tèmi o, mo gbádùn ẹ̀ gan-an. Mo mọ àwọn ohun àgbàyanu tó ti ń rú mi lójú tipẹ́, irú bí ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi àti ìyà.

Ṣé àwọn olórí yín ò gbìyànjú láti yí ẹ lérò pa dà pé o ò gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Lọ́dún 1975, mo lọ sí Róòmù léraléra láti lọ ṣàlàyé èrò mi fún àwọn olórí ẹ̀sìn mi. Wọ́n gbìyànjú láti yí èrò mi pa dà, àmọ́ kò sẹ́ni tó lo Bíbélì lára wọn. Níkẹyìn ní January 9 ọdún 1976, mo kọ̀wé sáwọn adarí wa ní Róòmù láti sọ fún wọn pé mi ò ṣe Kátólíìkì mọ́. Lọ́jọ́ méjì lẹ́yìn náà, mo fi ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn náà sílẹ̀, mo sì wọ ọkọ̀ ojú irin lọ síbi àpéjọ kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, àpéjọ yẹn ni ìpàdé àkọ́kọ́ tí mo lọ látìgbà tí mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gbogbo nǹkan tí wọ́n ṣe níbẹ̀ ló yàtọ̀ pátápátá sí àwọn nǹkan tí mo mọ̀ tẹ́lẹ̀! Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ló ní Bíbélì tiẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì ń ṣí i báwọn tó ń sọ̀rọ̀ ṣe ń jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì lóríṣiríṣi.

Kí ni ìdílé rẹ rò nípa gbogbo ohun tó o ṣe yẹn?

Ọ̀pọ̀ lára wọn ta kò mí gan-an. Àmọ́ nígbà tó yá, mo gbọ́ pé ọ̀kan lára àwọn àbúrò mi ọkùnrin bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Lombardy, ní apá àríwá Ítálì. Mo lọ sọ́dọ̀ ẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ sì bá mi wá iṣẹ́ àti ibi tí màá máa gbé. Nígbà tó yá lọ́dún yẹn, mo ṣèrìbọmi, mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àsìkò yìí gan-an ni mo sún mọ́ Ọlọ́run lóòótọ́

Ǹjẹ́ o kábàámọ̀ gbogbo ohun tó o ṣe yìí?

Rárá o! Àsìkò yìí gan-an ni mo sún mọ́ Ọlọ́run lóòótọ́, torí inú Bíbélì ni ohun tí mo mọ̀ nípa Ọlọ́run ti wá, kì í ṣe látinú ìmọ̀ ọgbọ́n orí tàbí ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ti ṣọ́ọ̀ṣì. Ní báyìí mo lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ìdánilójú àti òótọ́ ọkàn.

^ Wo Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ.