Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÓ O ṢE LÈ RÍ Ẹ̀KỌ́ KỌ́ LÁTINÚ KÍKA BÍBÉLÌ

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ka Bíbélì?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ka Bíbélì?

“Èrò mi ni pé ó máa ṣòro fún mi láti lóye Bíbélì.”—Jovy

“Mo ronú pé kíka Bíbélì kì í gbádùn mọ́ni.”—Queennie

“Nígbà tí mo bá rí bí Bíbélì ṣe tóbi tó, ńṣe ló máa ń sú mi.”—Ezekiel

Ṣé o ti ronú nípa kíka Bíbélì, àmọ́ tí o kò kà á torí pé o ní irú èrò tí àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn lókè yìí ní? Kíka Bíbélì máa ń ka ọ̀pọ̀ èèyàn láyà. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé Bíbélì lè jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè láyọ̀, kó o sì máa gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀? Tó o bá wá mọ̀ pé àwọn ọ̀nà kan wà tó o lè gbà kà á, tí wàá sì gbádùn ẹ̀ ńkọ́? Ṣé wàá fẹ́ láti gbìyànjú ẹ̀ wò, kó o sì rí ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú kíka Bíbélì?

Àwọn kan ti ka Bíbélì, ó sì ti ṣe wọ́n láǹfààní. Jẹ́ ká gbọ́ ohun tí díẹ̀ lára wọn sọ.

Ezekiel, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ogún [20] ọdún, sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, mo dà bí ẹni tó ń wa mọ́tò láìjẹ́ pé ó ní ibi kan lọ́kàn tó fẹ́ lọ. Ṣùgbọ́n kíka Bíbélì ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi túbọ̀ ní ìtúmọ̀. Ó ní àwọn ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí mo lè máa lò lójoojúmọ́.”

Frieda, tí òun náà ti lé lọ́mọ ogún [20] ọdún, sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, ńṣe ni mo máa kanra lódìlódì. Àmọ́ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, mo tí mọ bí mo ṣe lè kápá rẹ̀. Ní báyìí, àwọn èèyàn ti ń sún mọ́ mi, mo sì ti láwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀ sí i.”

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Eunice tó ti lé lẹ́ni àádọ́ta [50] ọdún, sọ nípa Bíbélì pé, “Bíbélì ti ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìwà tó dáa.”

Bíi tàwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí àti ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn míì, kíka Bíbélì lè ran ìwọ náà lọ́wọ́ láti gbádùn ìgbésí ayé rẹ. (Aísáyà 48:17, 18) Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Bíbélì lè ṣe fún ẹ, lára wọn ni (1) ṣíṣe ìpinnu tó tọ́, (2) yíyan ọ̀rẹ́ tòótọ́, (3) fífara da ìdààmú, (4) èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, wàá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni gbogbo ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì ti wá, torí náà o kò ní kọsẹ̀ tó o bá fi wọ́n sílò. Ọlọ́run kò lè fún wa ní ìmọ̀ràn burúkú.

Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì. Àmọ́, kí làwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti bẹ̀rẹ̀, kó o sì gbádùn rẹ̀?