Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÓ O ṢE LÈ BORÍ ÀNÍYÀN

Àníyàn Nípa Owó

Àníyàn Nípa Owó

Baálé ilé ni Paul, ó sì ní ọmọ méjì. Ó sọ pé: “Nígbà kan owó ọjà fò sókè lọ́sàn-án kan orù kan lórílẹ̀-èdè wa, gbogbo nǹkan sì di ọ̀wọ́n gógó, àtijẹ àtimu pàápàá di ìṣòro. Ńṣe la máa ń tò sórí ìlà fún ọ̀pọ̀ wákàtí, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, nígbà tá a bá fi máa dé iwájú, oúnjẹ á ti tán. Ebi pa àwọn èèyàn débi pé ńṣe ni wọ́n rù hangogo, kódà ebi pa àwọn kan kú sójú títì. Gbogbo nǹkan tá à ń rà pátá ló gbowó lórí gegere. Nígbà tó yá, owó wa kò níye lórí mọ́. Gbogbo owó tí mo ní ní báńkì, owó ìbánigbófò mi àti owó ìfẹ̀yìntì mi pátá ló ṣòfò.”

Paul

Paul mọ̀ pé, òun nílò “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́,” kí òun àti ìdílé rẹ̀ lè máa rí oúnjẹ jẹ. (Òwe 3:21) Ó sọ pé: “Iṣẹ́ mànàmáná ni mò ń ṣe àmọ́ gbogbo iṣẹ́ tó bá ṣáà ti yọjú ni mò ń gbà. Owó tí wọ́n ń san fún mi kéré gan-an sí iye tó yẹ kí n gbà. Nígbà míì, oúnjẹ làwọn kan máa gbé fún mi tàbí ohun èèlò míì. Tí wọ́n bá fún mi ní ọṣẹ mẹ́rin, màá lo méjì màá sì ta méjì tó kù. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo rí ogójì [40] ọmọ adìyẹ gbà. Nígbà tí wọ́n dàgbà, mo tà wọ́n, mo sì fowó rẹ̀ ra ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] míì. Nígbà tó yá, mo fi àádọ́ta [50] adìyẹ ṣe pàṣípààrọ̀ fún àpò àgbàdo lílọ̀ méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì wúwo tó àpò sìmẹ́ǹtì kan. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni ìdílé mi àtàwọn míì fi jẹ ẹ́.”

Paul mọ̀ pé ohun tó dáa jù téèyàn lè ṣe nírú ipò yìí ni pé kó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pátápátá. Tá a bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, yóò ràn wá lọ́wọ́. Ní ti àwọn ohun kòṣeémáàní ìgbésí ayé, Jésù sọ pé: “Ẹ sì jáwọ́ nínú àníyàn àìdánilójú; nítorí . . . Baba yín mọ̀ pé ẹ nílò nǹkan wọ̀nyí.”—Lúùkù 12:29-31.

Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé olórí ọ̀tá Ọlọ́run, ìyẹn Sátánì, ti fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mú ọ̀pọ̀ èèyàn láti máa fi gbogbo ìgbésí ayé wọn kó ohun ìní jọ. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe àníyàn nípa àwọn ohun tó wù wọ́n yálà wọ́n nílò rẹ̀ àbí wọn ò nílò rẹ̀. Wọ́n sì ń ṣe kìràkìtà  kí wọ́n lè ní àwọn nǹkan tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ nílò. Ọ̀pọ̀ ló sì máa ń di onígbèsè, wọ́n á wá gbà tipátipá pé ‘ayá-nǹkan ni ìránṣẹ́ awínni.’—Òwe 22:7.

Àwọn kan máa ń kù gìrì ṣe ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu. Paul sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ ń gbé ládùúgbò ló fi ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ síṣẹ́ olówó ńlá nílẹ̀ òkèèrè. Àwọn kan nínú wọn kò sì rí iṣẹ́ tí wọ́n wá lọ torí wọn kò ní ìwé ìgbélùú tó yẹ. Wọ́n wá dẹni tó ń sun ojú títì, wọ́n á máa sá kiri kí ọwọ́ ìjọba má báa tẹ̀ wọ́n. Wọn ò ṣe ohun táá mú kí Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́. Àmọ́ ńṣe lèmi àti ìdílé mi pinnu láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́ ká lè kojú ìṣòro ìṣúnná owó.”

TẸ̀ LÉ ÌMỌ̀RÀN JÉSÙ

Paul ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Jésù sọ pé: ‘Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un.’ Torí náà, ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọ́run lójoojúmọ́ kò ju pé kó fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa, kí ebi má baà pa wá kú. Ọlọ́run sì pèsè fún wa lóòótọ́ bí Jésù ti ṣèlérí. Kì í ṣe gbogbo ìgbà la máa ń rí oúnjẹ tó wù wá jẹ. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan mo lọ tò sórí ìlà láti ra oúnjẹ, láì tiẹ̀ mọ irú oúnjẹ tí wọ́n ń tà. Nígbà tó fi máa kàn mí, mo rí i pé yúgọ́ọ̀tì ni. Èmi ò sì fẹ́ràn yúgọ́ọ̀tì. Àmọ́ oúnjẹ náà ni, òun la sì mu sùn lálẹ́ ọjọ́ náà. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé jálẹ̀ gbogbo àkókò yẹn, èmi àti ìdílé mi ò sùn lébi rí.” *

Ọlọ́run ti ṣèlérí pé: “Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.”—Hébérù 13:5

“Nǹkan ti wá ń sàn fún wa báyìí. Àmọ́ a ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí pé ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run kò ní jẹ́ ká máa ṣàníyàn. Ó dájú pé Jèhófà * ò ní fi wá sílẹ̀, tá a bá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nìṣó. A ti wá rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú Sáàmù 34:8 tó sọ pé: ‘Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere; aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó sá di í.’ Torí náà, tí ètò ọrọ̀ ajé bá tiẹ̀ tún dẹnu kọlẹ̀, a ò ní bẹ̀rù.

Ọlọ́run máa ń pèsè ‘oúnjẹ òòjọ́’ fáwọn olóòótọ́

“Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yé wa pé oúnjẹ láwa èèyàn nílò láti gbé ẹ̀mí wa ró, kì í ṣe iṣẹ́ tàbí owó. À ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí Ọlọ́run máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé: ‘Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ yóò wá wà lórí ilẹ̀.’ Àmọ́ kó tó di ìgbà náà, ‘bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.’ Ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí tún máa ń fún wa lókun, ó ní: ‘Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí òun ti wí pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” Kí a lè jẹ́ onígboyà gidi gan-an, kí a sì sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà.”’” *

Ká tó lè bá ‘Ọlọ́run rìn,’ ó gba pé ká ní ojúlówó ìgbàgbọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 6:9) Yálà a ní ìṣòro ìṣúnná owó báyìí àbí bóyá lọ́jọ́ iwájú, a ti kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì lára Paul torí ìgbàgbọ́ tó ní àti ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ tó lò.

Àmọ́ tó bá wá jẹ́ pé ìṣòro ìdílé ló ń fa àníyàn ńkọ́?

^ ìpínrọ̀ 10 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.