Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ǹjẹ́ àwọn áńgẹ́lì lè ràn wá lọ́wọ́?

Bí àwọn áńgẹ́lì ṣe ran Dáníẹ́lì tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́ láyé àtijọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lónìí láti rí àǹfààní tó wà nínú ìhìn rere tá à ń polongo

Jèhófà Ọlọ́run ti kọ́kọ́ dá ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì kó tó dá àwa èèyàn. (Jóòbù 38:4, 7) Ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára làwọn áńgẹ́lì, wọ́n sì jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Nígbà míì, Ọlọ́run máa ń rán wọn wá sáyé láti tọ́ wa sọ́nà kí wọ́n sì dáàbò bò wá. (Sáàmù 91:10, 11) Lóde òní, àwọn áńgẹ́lì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí àǹfààní tó wà nínú ìhìn rere táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń polongo fáráyé.—Ka Ìṣípayá 14:6, 7.

Ṣé ó tọ́ ká máa gbàdúrà sí àwọn áńgẹ́lì fún ìrànlọ́wọ́? Rárá o. Ìdí ni pé àdúrà jẹ́ apá kan ìjọsìn wa, Ọlọ́run nìkan ló sì yẹ ká jọ́sìn. (Ìṣípayá 19:10) Ìránṣẹ́ Ọlọ́run làwọn áńgẹ́lì jẹ́, àṣẹ tí Ọlọ́run bá sì pa fún wọn ni wọ́n máa tẹ̀ lé kì í ṣe tàwa èèyàn. Torí náà, Ọlọ́run nìkan ló yẹ ká máa gbàdúrà sí nípasẹ̀ Jésù.—Ka Sáàmù 103:20, 21; Mátíù 26:53.

Ǹjẹ́ àwọn áńgẹ́lì búburú wà?

Bí àwa èèyàn ṣe lómìnira láti yan ohun tó bá wù wá, bẹ́ẹ̀ náà làwọn áńgẹ́lì lómìnira láti yàn bóyá rere làwọn á ṣe tàbí búburú. Àmọ́, ibi tí ọ̀rọ̀ náà burú sí ni pé ọ̀pọ̀ àwọn áńgẹ́lì yàn láti máa ṣe ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́. (2 Pétérù 2:4) Sátánì ni áńgẹ́lì tó kọ́kọ́ ya ọlọ̀tẹ̀, nígbà tó yá, àwọn áńgẹ́lì míì dara pọ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì di ẹ̀mí èṣù. Ní báyìí, Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kò sí lọ́run mọ́, wọ́n ti lé wọ́n wá sórí ilẹ̀ ayé.—Ka Ìṣípayá 12:7-9.

Bí ìwà ibi àti ìwà ipá ṣe túbọ̀ ń peléke sí i láti ọdún 1914 fi hàn pé Ọlọ́run máa tó pa Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ run. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run máa sọ ayé yìí di Párádísè tó máa dùn ún gbé fáwa èèyàn.—Ka Ìṣípayá 12:12; 21:3, 4.