Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ÀWỌN ÒǸKÀWÉ WA BÉÈRÈ PÉ . . .

Ta Ló Dá Ọlọ́run?

Ta Ló Dá Ọlọ́run?

Finú yàwòrán bàbá kan tó ń bá ọmọkùnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún méje sọ̀rọ̀. Bàbá yìí sọ fún ọmọ rẹ̀ pé: “Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ni Ọlọ́run ti dá ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀. Ó tún dá oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀.” Ọmọ náà ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí fúngbà díẹ̀, ló bá sọ pé: “Bàámi, ta ló wá dá Ọlọ́run?”

Ni bàbá rẹ̀ bá dá a lóhùn pé: “Kò sí ẹni tó dá Ọlọ́run. Kò sì sí ìgbà kankan tí Ọlọ́run kò sí.” Bí bàbá yẹn ṣe dá ọmọ yẹn lóhùn tẹ́ ẹ lọ́rùn nígbà yẹn. Àmọ́ bó ṣe wá ń dàgbà, ló túbọ̀ ń wù ú láti mọ púpọ̀ sí i nípa ẹni tí ó dá Ọlọ́run. Lójú rẹ̀, kò dà bí ohun tó ṣeé ṣe pé kí ẹnì kan wà láìsí ẹni tó dá a. Ó ronú pé, àgbáálá ayé pàápàá ní ìbẹ̀rẹ̀, ẹnì kan ṣáà ló dá a, báwo ló ṣe wá jẹ́, ‘Ta ló dá Ọlọ́run gan-an?’

Báwo ni Bíbélì ṣe dáhùn ìbéèrè yìí? Òótọ́ ọ̀rọ̀ tí bàbá yìí sọ náà ni Bíbélì jẹ́ ká lóye. Mósè kọ̀wé pé: “Jèhófà, . . . àní kí a tó bí àwọn òkè ńlá, tàbí kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí bí ilẹ̀ ayé àti ilẹ̀ eléso gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú ìrora ìrọbí, àní láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin, ìwọ ni Ọlọ́run.” (Sáàmù 90:1, 2) Wòlíì Aísáyà náà sọ pé: “Ṣé o kò tíì mọ̀ ni tàbí ṣé o kò tíì gbọ́ ni? Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé, jẹ́ Ọlọ́run fún àkókò tí ó lọ kánrin”! (Aísáyà 40:28) Bákan náà, nínú Bíbélì, ìwé Júúdà sọ pé Ọlọ́run ti wà “fún gbogbo ayérayé tí ó ti kọjá.”—Júúdà 25.

Àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyẹn jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run jẹ́ “Ọba ayérayé.” Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sì sọ nìyẹn. (1 Tímótì 1:17) Èyí fi hàn pé kò sí ìgbà kan tí Ọlọ́run kò sí, láìka àìmọye ọdún tó wù ká a kà sẹ́yìn, Ọlọ́run ti wà, yóò sì máa wà títí láé. (Ìṣípayá 1:8) Ìdí tó sì fi jẹ́ Olódùmarè náà nìyẹn torí pé ó ti wà láti ayérayé.

Kí nìdí tó fi ṣòro láti gbà gbọ́ pé láti ayérayé ni Ọlọ́run ti wà? Ìdí ni pé ìgbésí ayé àwa èèyàn kúrú gan-an, a ò sì ní àkókò tó pọ̀ tó láti lóye nǹkan bí Jèhófà ṣe máa ń lóye rẹ̀. Àìmọye ọdún ni Jèhófà ti wà, ó sì máa wà títí ayérayé ni, nítorí náà ẹgbẹ̀rún ọdún dà bí ọjọ́ kan lójú rẹ̀. (2 Pétérù 3:8) Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà yìí: Kòkòrò kan wà tí wọ́n ń pè ní tata. Lẹ́yìn tí kòkòrò yìí bá ti dàgbà, kì í lò ju nǹkan bí àádọ́ta [50] ọjọ́ lọ. Ǹjẹ́ o rò pé tata yìí lè lóye bí àwa èèyàn ṣe ń lo àádọ́rin [70] tàbí ọgọ́rin [80] ọdún láyé? Kò dájú! Bíbélì jẹ́ ká lóye pé a dà bí tata ní ìfiwéra pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá. Lọ́nà kan náà, agbára ìrònú wa kéré gan-an ní ìfiwéra pẹ̀lú ti Ọlọ́run. (Aísáyà 40:22; 55:8, 9) Torí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn nǹkan kan wà nípa Jèhófà tó kọjá òye àwa èèyàn.

Lóòótọ́, ó lè ṣòro láti gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ti wà láti ayérayé, àmọ́ ó bọ́gbọ́n mu láti gbà bẹ́ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé ẹnì kan ló dá Ọlọ́run, ẹni yẹn gan-an ló yẹ ká máa pè ní Ẹlẹ́dàá, kì í ṣe Ọlọrun. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká lóye pé, Jèhófà ni ó “dá ohun gbogbo.” (Ìṣípayá 4:11) Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé kò sí àgbáálá ayé wa yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 1:1, 2) Báwo ló ṣe wá di pé ó wà? Ó dájú pé ẹnì kan ti wà ṣáájú kí àgbáálá ayé wa yìí tó wà, òun ló sì ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó tún ti wà ṣáájú Jésù àtàwọn áńgẹ́lì. (Jóòbù 38:4, 7; Kólósè 1:15) Ó wá ṣe kedere pé, òun nìkan ló wà látìbẹ̀rẹ̀. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé kò sí ẹni tó dá Ọlọ́run.

Àgbáálá ayé yìí àti àwa èèyàn inú rẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run kan ti wà láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. Òun ló ṣètò gbogbo nǹkan tó wà láyè àti lọ́run, Ọlọ́run yìí ti wà látayébáyé. Òun náà ló sì fi èémí ìyè sínú gbogbo nǹkan tó wà.—Jóòbù 33:4.