Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NÌDÍ TÍ NǸKAN BURÚKÚ FI Ń ṢẸLẸ̀ SÁWỌN ÈÈYÀN RERE?

Kí Nìdí Tí Nǹkan Burúkú Fi Ń Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Èèyàn Rere?

Kí Nìdí Tí Nǹkan Burúkú Fi Ń Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Èèyàn Rere?

Nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run * ló ṣẹ̀dá ohun gbogbo, òun sì ni Olódùmarè, àwọn èèyàn máa ń sọ pé òun ló wà nídìí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé títí kan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ibi tó gbòde kan. Ṣùgbọ́n, ohun tí Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run tòótọ́ náà ni pé:

  • “Olódodo ni Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.”—Sáàmù 145:17.

  • “Gbogbo ọ̀nà [Ọlọ́run] jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; Olódodo àti adúróṣánṣán ni.”—Diutarónómì 32:4.

  • “Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.”—Jákọ́bù 5:11.

Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n, ṣé òun ló wà lẹ́yìn àwọn èèyàn tó ń hùwà burúkú ni? Rárá o. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà lábẹ́ àdánwò, kí ó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.’” Kí nìdí? “Nítorí a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Ọlọ́run kì í dán àwọn èèyàn wò tàbí kó mú kí wọ́n máa hùwà burúkú. Bákan náà, Ọlọ́run kọ́ ló wà nídìí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ibi tó ń ṣẹlẹ̀ láyé, òun sì kọ́ ló ń ti àwọn èèyàn lẹ́yìn láti máa ṣe búburú. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ta ló wà nídìí àwọn aburú yìí tàbí kí ló fa àwọn láabi tó ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí?

ÈÈYÀN LÈ ṢE KÒŃGẸ́ IBI LÁÌRÒTẸ́LẸ̀

Bíbélì sọ ìdí pàtàkì kan tí àwa èèyàn fi ń jìyà, ó sọ pé: “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” (Oníwàásù 9:11) Aburú lè ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn ò rò tẹ́lẹ̀. Téèyàn bá wá rìn sásìkò irú aburú bẹ́ẹ̀, ó lè pani lára. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] sẹ́yìn, Jésù Kristi sọ̀rọ̀ nípa àjálù kan tó mú ẹ̀mí èèyàn méjìdínlógún [18] lọ nígbà tí ilé gogoro kan wó pa wọ́n. (Lúùkù 13:1-5) Kì í ṣe nítorí bí wọ́n ṣe ń lo ìgbésí ayé wọn ló mú kí ilé gogoro yẹn wó lù wọ́n, bí ko ṣe pé abẹ́ ilé náà ni wọ́n wà nígbà tí ó wo lulẹ̀. Láìpẹ́ yìí ní January ọdún 2010, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára kan wáyé ní orílẹ̀-èdè Haiti. Ìjọba ilẹ̀ Haiti sọ pé ohun tó ju ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] èèyàn ló kú. Láìka irú ẹni yòówù kí wọ́n jẹ́ àti ipò tí wọ́n lè wà láwùjọ, gbogbo wọn pátápátá ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni àìsàn rí, ó lè kọlu ẹnikẹ́ni nígbàkigbà.

Kí nìdí tí Ọlọ́run kò fi dáàbò bo àwọn èèyàn rere kúrò nínú ewu?

Àwọn kan tiẹ̀ ń béèrè pé: ‘Ṣé Ọlọrun kò lè dáwọ́ àwọn àjálù burúkú yìí dúró ni àti pé kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi dáàbò bo àwọn èèyàn rere kí wọ́n má bàa ṣe kòńgẹ́ aburú?’ Ká ní Ọlọ́run fẹ́ dáàbò bó wọ́n, ó gbọ́dọ̀ ti mọ̀ ṣáájú kí àwọn nǹkan burúkú yẹn tó ṣẹlẹ̀. Òótọ́ ni pé Ọlọ́run lágbára láti mọ ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, àmọ́ ó yẹ ká wá bi ara wa pé, ǹjẹ́ gbogbo nǹkan ni Ọlọ́run máa ń lo agbára rẹ̀ láti mọ̀?—Aísáyà 42:9.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pe: ‘Ọlọ́run ń bẹ ní ọ̀run; Ohun gbogbo tí ó ní inú dídùn sí ni ó máa ń ṣe.’ (Sáàmù 115:3) Jèhófà kì í ṣe nǹkan nítorí kí àwọn èèyàn  lè mọ bó ṣe lágbára tó, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó bá rí pé ó pọn dandan ló máa ń ṣe. Ohun tó sì máa ń ṣe nìyẹn tó bá fẹ́ mọ̀ nípa ọjọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìwà búburú àwọn èèyàn gbilẹ̀ ní ìlú Sódómù àti Gòmórà ìgbàanì, Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé, èmi yóò “sọ̀ kalẹ̀ lọ kí n lè rí bóyá wọ́n hùwà látòkè délẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú igbe ẹkún tí wọ́n ń ké lé e lórí tí ó ti wá sọ́dọ̀ mi, bí kò bá sì jẹ́ bẹ́ẹ̀, èmi a lè mọ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:20, 21) Àkọsílẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé ṣáájú ìgbà yẹn, Jèhófà yàn láti má mọ bí ìwà burúkú àwọn èèyàn ní àwọn ìlú náà ṣe pọ̀ tó. Lọ́nà kan náà, Jèhófà lè yàn láti má mọ gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Jẹ́nẹ́sísì 22:12) Kì í ṣe pé agbára rẹ̀ ni ò gbé e tàbí nǹkan kan dí i lọ́wọ́ o. Ẹ ṣáà mọ pé “pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀,” ìyẹn sì fi hàn pé Ọlọ́run máa ń lo agbára rẹ̀ láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe àti pé kì í fipá mú àwọn èèyàn láti ṣe ohun tó fẹ́. * (Diutarónómì 32:4) Kí wá ni kókó ọ̀rọ̀ gan-an? Kókó ọ̀rọ̀ ni pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run lágbára láti mọ nǹkan ṣáájú kó tó ṣẹlẹ̀, ó máa ń dìídì yan èyí tó bá fẹ́ láti mọ̀.

Kí nìdí tí Ọlọ́run kò fi dáàbò bo àwọn èèyàn rere kúrò lọ́wọ́ ìwà ọ̀daràn?

ṢÉ ÀFỌWỌ́FÀ ÀWA ÈÈYÀN NI?

Ẹ̀bi díẹ̀ wà lọ́wọ́ àwa èèyàn fún àwọn nǹkan ibi tó ń ṣẹlẹ̀. Kíyè sí ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ń ṣáájú kéèyàn tó hùwà burúkú, ó ní: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀; ẹ̀wẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti ṣàṣeparí rẹ̀, a mú ikú wá.” (Jákọ́bù 1:14, 15) Téèyàn bá fàyè gba èròkerò tó máa ń wá síni lọ́kàn láti mú kéèyàn hùwà burúkú, àbájáde rẹ̀ kì í dáa rárá. (Róòmù 7:21-23) Ìtàn fi hàn pé, àwọn ìwà ibi tó burú jáì ló ń tọwọ́ àwọn èèyàn ṣẹlẹ̀, èyí sì ti dá kún ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn. Síwájú sí i, àwọn èèyàn burúkú máa ń nípa lórí àwọn ẹlòmíràn láti hùwà ìbàjẹ́, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, bí ìwà ibi ṣe ń gbilẹ̀ sí i nìyẹn.—Òwe 1:10-16.

Àwọn ìwà ibi tó burú jáì ló ń tọwọ́ àwọn èèyàn ṣẹlẹ̀, èyí sì ti dá kún ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn

Ọ̀pọ̀ lè máa wò ó pé ó yẹ kí Ọlọ́run dáwọ́ ìwà ibi dúró kó má sì fàyè gba àwọn èèyàn láti máa hùwà burúkú. Àmọ́ ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo bí Ọlọ́run ṣe dá àwa èèyàn. Ìwé Mímọ́ sọ pé Ọlọ́run dá èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀. Ohun tó fà á nìyẹn tí a fi ní àwọn ànímọ́ tó ní, ìdí sì nìyẹn tá a fi fìwà jọ ọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Ọlọ́run fún wa lómìnira láti yan ohun tó wù wá, ìyẹn ni pé, a lè yàn láti ṣègbọràn sí i ká sì máa ṣe ohun tó tọ lójú rẹ̀. (Diutarónómì 30:19, 20) Tó bá jẹ́ pé ńṣe ni Ọlọrun fipá mú àwa èèyàn láti ṣe ohun tó fẹ́, ǹjẹ́ kò ní dàbí pé ó gba òmìnira tó fún wa? Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lèèyàn á kàn dàbí ẹ̀rọ tí kò lè dá nǹkan kan ṣe fúnra rẹ̀! Ohun tó máa túmọ̀ sí náà nìyẹn tó bá jẹ́ pé kádàrá tàbí àyànmọ́ ló ń darí ohun tí à ń ṣe àti ohun gbogbo tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa. Ṣùgbọ́n inú wá dùn pé Ọlọ́run buyì kún wa  nípa fífún wa ní àǹfààní láti yan ohun tó wù wá! Èyí kò wá túmọ̀ sí pé, títí láé ni àṣìṣe àwa èèyàn àti àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó wa yóò máa pọ́n wa lójú.

ṢÉ ÒFIN KÁMÀ LÓ FÀ Á TÍ A FI Ń JÌYÀ?

Tó o bá bi onísìn Híńdù tàbí Búdà ní ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé yìí, èsì tó máa fún ẹ ni pé: “Òfin Kámà, ìyẹn òfin àṣesílẹ̀-làbọ̀wábá ló fà á tí nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn rere. Irú ìgbé ayé téèyàn bá gbé ló máa pinnu irú ìyà tó máa jẹ tó bá tún ayé wá.” *

Ká lè mọ̀ bóyá òfin Kámà jẹ́ òótọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, á dáa ká kọ́kọ́ mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ikú. Nígbà tí Ọlọ́run ṣẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ nínú ọgbà Édẹ́nì, ìyẹn Ádámù, ó sọ fún un pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Ká ní Ádámù ṣègbọràn sí àṣẹ yẹn ni, títí láé ni kò bá máa gbé láyé. Ṣùgbọ́n, ó ṣàìgbọràn, ó sì kú gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe sọ. Nígbà tó wá bí àwọn ọmọ, ‘ikú tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.’ (Róòmù 5:12) Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 6:23) Bíbélì tún ṣàlàyé síwájú sí i pé: “Ẹni tí ó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” (Róòmù 6:7) Ká sọ ọ́ lọ́nà míì, èèyàn kò ní jìyà kankan mọ́ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn tó bá kú.

Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló gbà pé ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn ní i ṣe pẹ̀lú ohun tí òfin Kámà sọ. Ẹni tó bá gba òfin yìí gbọ́ sábà máa ń gba kámú pé ìyà tó tọ́ sí òun àti àwọn ẹlòmíràn làwọn ń jẹ. Àmọ́, òótọ́ kan ni pé, ẹ̀kọ́ yìí kò fúnni ní ìrètí pé ìwà burúkú máa kásẹ̀ nílẹ̀. Wọ́n gbà gbọ́ pé ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn fi máa bọ́ lọ́wọ́ ìyà ni pé kí onítọ̀hún má tún ayé wá mọ́. Ọ̀nà tó sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó máa hùwà ọmọlúwàbí láwùjọ kó sì lọ gba ìmọ̀ àrà ọ̀tọ̀ kan. Ẹ̀kọ́ yìí yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. *

ẸNI TÓ DÁ WÀHÁLÀ SÍLẸ̀!

Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Sátánì Èṣù tó jẹ́ “olùṣàkóso ayé” yìí ló wà nídìí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn?—Jòhánù 14:30

Sátánì Èṣù gan-an lẹni tó dá gbogbo wàhálà yìí sílẹ̀. Ańgẹ́lì dáradára kan ni tẹ́lẹ̀, àmọ́ kò “dúró ṣinṣin nínú òtítọ́” òun ló sì fà á tí ẹ̀ṣẹ̀ fi pọ̀ láyé. (Jòhánù 8:44) Òun ló wà nídìí ọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Jésù Kristi pè é ní “ẹni burúkú náà” àti “olùṣàkóso ayé.” (Mátíù 6:13; Jòhánù 14:30) Sátánì ni ọ̀pọ̀ jù lọ ọmọ aráyé ń ṣègbọràn sí. Wọ́n ń jẹ́ kó máa tì wọ́n ṣe ohun tí kò bá ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run mu. (1 Jòhánù 2:15, 16) Ìwé 1 Jòhánù 5:19 sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” Àwọn ańgẹ́lì burúkú míì náà dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú iṣẹ́ ibi rẹ̀. Bíbélì fi hàn pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà,” èyí ló sì fa “ègbé,” ìyẹn ìpọ́njú tó ń bá aráyé. (Ìṣípayá 12:9, 12) Nítorí náà, Sátánì Èṣù gan-an ni olórí àwọn tó ń fa ìwà ibi àti ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn.

Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé Ọlọ́run kọ́ ló fa ìwà ibi, òun sì kọ́ ló fa ìpọ́njú tó ń bá ọmọ aráyé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló pinnu láti mú ìwà ibi kúrò, gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó kàn yóò ṣe jẹ́ ká mọ̀.

^ ìpínrọ̀ 3 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

^ ìpínrọ̀ 11 Tó o bá fẹ́ mọ̀ síwájú sí i nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà burúkú, wo orí 11 nínú ìwé náà Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

^ ìpínrọ̀ 16 Tó o bá fẹ́ mọ̀ síwájú sí i nípa ohun tó pilẹ̀ ohun tí wọ́n ń pè ní Òfin Kámà, wo ojú ìwé 8 sí 12 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

^ ìpínrọ̀ 18 Tó o bá fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì fí kọ́ni nípa ipò tí àwọn òkú wà àti ìrètí tó wà fún àwọn tó ti kú, wo orí 6 àti 7 nínú ìwé náà, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?