Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Àwọ̀ Ṣe Ń Nípa Lórí Rẹ?

Báwo Ni Àwọ̀ Ṣe Ń Nípa Lórí Rẹ?

Bó o ṣe ń wò yí ká, ojú àti ọpọlọ rẹ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti kó ìsọfúnni jọ. O lè rí èso kan kó sì wù ẹ́ jẹ. O tún lè gbójú sókè wo ọ̀run kó o sì mọ̀ bóyá òjò máa rọ̀ tàbí kò ní rọ̀. Bó o ṣe ń ka ọ̀rọ̀ tó wà lójú ìwé yìí ni wàá ti máa ronú lórí ìtumọ̀ ohun tó ò ń kà. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọ̀ àwọn nǹkan yìí ló ń ní ipa lórí rẹ? Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?

Àwọ̀ tí èso tó o rí yẹn ní ló máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ó ti pọ́n, ìyẹn sì lè jẹ́ kó wù ẹ́. Àwọ̀ ojú ọ̀run ló jẹ́ kó o mọ bí ojú ọjọ́ ṣe máa rí. Bó o ti ń ka àwọn ọ̀rọ̀ inú àpilẹ̀kọ yìí, ó tù ẹ́ lára, torí pé àwọ̀ ìwé àti yíńkì tí wọ́n fi kọ ọ̀rọ̀ sórí rẹ̀ yàtọ̀ síra. Ìwọ fúnra rẹ lè má mọ̀ pé o máa ń fi bí àwọ̀ àwọn nǹkan ṣe rí lóye ohun tó ń lọ ní àyíká rẹ. Àmọ́, ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ̀ pé àwọ̀ máa ń nípa lórí bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ?

ÀWỌ̀ LÈ FI BÍ NǸKAN ṢE RÍ LÁRA WA HÀN

Tó o bá wà nínú ilé ìtajà kan, oríṣiríṣi àwọn nǹkan tí wọ́n fi páálí tàbí àwọn ọ̀rá aláràbarà wé lè wọ̀ ẹ́ lójú. Bóyá o mọ̀ tàbí o kò mọ̀, ńṣe ni àwọn tó ń polówó ọjà máa ń mọ̀ọ́mọ̀ yan oríṣiríṣi àwọ̀ tí wọ́n mọ̀ pé ó máa wu àwọn èèyàn, yálà wọ́n jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, ọkùnrin tàbí obìnrin. Àwọn tó máa ń ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn tó ń ṣe aṣọ àtàwọn ayàwòrán mọ̀ pé àwọ̀ tí ohun kan bá ní lè gbé èrò kan jáde lọ́kàn ẹni.

Àwọn èèyàn máa fún àwọ̀ ní ìtumọ̀ tó yàtọ̀ síra torí pé àṣà àti ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, nílẹ̀ Éṣíà wọ́n gbà pé àwọ̀ pupa túmọ̀ sí oríire tàbí ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ayẹyẹ. Ṣùgbọ́n ní àwọn apá kan ní ilẹ̀ Áfíríkà, nǹkan ọ̀fọ̀ ni wọ́n máa ń lo àwọ̀ pupa fún. Àmọ́ ṣá o, láìka ibi tí a ti dàgbà sí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àwọn àwọ̀ kan wà tó máa ń mú kí nǹkan rí bákàn náà lára wa. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àwọ̀ mẹ́ta yẹ̀ wò, ká sì wo ipa tí wọ́n máa ń ní lórí wa.

ÀWỌ̀ PUPA máa ń tàn yòò. Àwọn èèyàn máa ń fi àwọ̀ pupa ṣàpẹẹrẹ ohun tó bá jẹ mọ́ okun, ogun àti ewu. Ó máa ń tètè fi bí nǹkan ṣe rí lára èèyàn hàn, ó máa ń mú kí ara èèyàn yá gágá, kí ọkàn lù kìkì, ó sì tún lè mú kí ẹ̀jẹ̀ ru.

Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ Hébérù tí a tú sí pupa, wá látinú ọ̀rọ̀ tí ó túmọ̀ sí “ẹ̀jẹ̀.” Bíbélì máa ń lo àwọ̀ tó pupa tó ń tàn yòò tàbí àwọ̀ rírẹ̀dòdò láti fi ṣàpèjúwe aṣẹ́wó kan tó jẹ́ apààyàn. Aṣẹ́wó yìí wọ aṣọ aláwọ̀ àlùkò àti aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, ó sì jókòó “lórí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tí ó kún fún àwọn orúkọ ọ̀rọ̀ òdì.”—Ìṣípayá 17:1-6.

ÀWỌ̀ EWÉ òdìkejì gbáà ló jẹ́ sí àwọ̀ pupa, ńṣe ni àwọ̀ yìí máa ń mú ara tù wá. Àwọ̀ ewé jẹ mọ́ ìfọ̀kànbalẹ̀, wọ́n sábà máa ń lò ó fún ohunkóhun tó bá ní í ṣe pẹ̀lú àlàáfíà. Abájọ tí ara ṣe máa ń tù wá pẹ̀sẹ̀ tí a bá wà láàárín ọgbà tí ewé rẹ̀ tutù tàbí lórí àwọn òkè tí ewé tútù wà níbẹ̀. Nínú Bíbélì, ìwé Jẹ́nẹ́sísì tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá sọ pé Ọlọ́run ló pèsè ewéko tó ní àwọ̀ yìí àti ọgbà tó ní àwọn ewéko tútù fún àwọn ẹ̀dá èèyàn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:11, 12, 30.

ÀWỌ̀ FUNFUN sábà máa ń ní í ṣe pẹ̀lú ohun tó jẹ mọ́ ìmọ́lẹ̀, ààbò àti ohun tó mọ́ tónítóní. Ó tún jẹ mọ́ inú rere, ọwọ́ mímọ́ àti àìléèérí. Àwọ̀ yìí ni Bíbélì mẹ́nu kàn jù. Nínú ọ̀pọ̀ ìran, Bíbélì sọ nípa àwọn èèyàn àti áńgẹ́lì tó wọ aṣọ funfun. Aṣọ funfun yìí sì dúró fún òdodo  àti àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. (Jòhánù 20:12; Ìṣípayá 3:4; 7:9, 13, 14) Yàtọ̀ sí ìyẹn, Bíbélì tún sọ nípa àwọn tó gun ẹṣin funfun, tí wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun. Aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun yìí ṣàpẹẹrẹ ìjà òdodo. (Ìṣípayá 19:14) Ọlọ́run lo àwọ̀ funfun láti fi tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa lọ́kàn pé òun ṣe tán láti dárí jì wá, ó sọ pé: “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, a ó sọ wọ́n di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì.”—Aísáyà 1:18.

ÀWỌ̀ JẸ́ OHUN TÍ A LÈ FI RÁNTÍ NǸKAN

Bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ kí àwọn tó kọ Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa onírúurú àwọ̀ fi hàn pé Jèhófà mọ ipa tí àwọ̀ máa ń ní lórí àwa èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Ìṣípayá nínú Bíbélì sọ nípa wàhálà tó ń bá àwa èèyàn fínra lónìí, títí kan ogun, ìyàn àti bí àìtó oúnjẹ pẹ̀lú àìsàn ṣe ń pa àwọn èèyàn. Ká lè máa rántí èyí ló ṣe lo ìran kan tó sọ nípa àwọn tí ó gun ẹṣin, kì í ṣe àwọn ẹṣin lásán, àmọ́ àwọn ẹṣin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yìí ní àwọ̀ tó ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan kan.

Ẹṣin funfun ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, èyí tí ó dúró fún ìjà òdodo tí Jésù máa jà. Ẹṣin kejì tó mẹ́nu kàn ni ẹṣin tó ní àwọ̀ iná, ìyẹn dúró fún ogun láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Ẹṣin dúdú tó ń dẹ́rù bani ló tún tẹ̀ lé èyí, ó dúró fún ìyàn. Lẹ́yìn náà, ló wá kan “ẹṣin ràndánràndán kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní orúkọ náà ikú.” (Ìṣípayá 6:1-8) Ìtumọ̀ tí àwọ̀ àwọn ẹṣin yìí ní lọ́kàn wa lè bá ohun tí àwọn ẹṣin náà dúró fún gan-an mu. Èyí ló jẹ́ kó rọrùn fún wa láti rántí àwọ̀ àwọn ẹṣin yìí ká sì fìyẹn máa rántí ohun tí wọ́n kọ́ wa nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé lónìí.

Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì nípa bí wọ́n ṣe fi àwọ̀ ṣàlàyé nǹkan kan tí a lè fojú rí lọ́nà tó máa yéni yékéyéké. Ẹlẹ́dàá wa tó dá ìmọ́lẹ̀, àwọ̀ àti ojú àwa èèyàn fi àwọ̀ ṣàlàyé àwọn nǹkan lọ́nà tó máa yé wa, tí a ò sì ní gbàgbé. Àwọ̀ máa ń jẹ́ ká lè kó ìsọfúnni jọ ká sì lóye rẹ̀. Ó máa ń ní ipa lórí bí nǹkan ṣe ń rí lára wa, ó sì tún jẹ́ ká lè rántí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì. Àwọ̀ jẹ́ ẹ̀bùn ńlá láti ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa ká lè gbádùn ayé wa.