Ojútùú Tó Kárí Ayé Sí Ìṣòro Tó Kárí Ayé
Ojútùú Tó Kárí Ayé Sí Ìṣòro Tó Kárí Ayé
KÒ SÍ ibi tí ìjìyà kò sí, ọ̀pọ̀ tó sì jẹ́ aláàánú máa ń ran àwọn tó ń jìyà lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé ìwòsàn máa ń lo àkókò tó pọ̀ níbi iṣẹ́ kí wọ́n lè ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn tó ń ṣàìsàn tàbí àwọn tó fara pa. Àwọn panápaná, àwọn ọlọ́pàá, àwọn amòfin àtàwọn tá a lè pè nígbà tí nǹkan pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀ máa ń gbìyànjú láti dín ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn kù tàbí kí wọ́n rí i pé ìyà kò jẹ wọ́n. Irú àwọn ìsapá bẹ́ẹ̀ máa ń ṣiṣẹ́ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan, àmọ́, ó kọjá agbára èèyàn èyíkéyìí tàbí àjọ èyíkéyìí láti mú ìjìyà kúrò níbi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé. Ní ti Ọlọ́run, ó lè mú ìjìyà kúrò, ó sì máa pèsè ojútùú tó máa kárí ayé.
Ìdánilójú èyí wà nínú ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì pé: “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn Ìṣípayá 21:4) Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bí àwọn èèyàn tó máa jàǹfààní nínú ìlérí yẹn ṣe máa pọ̀ tó. Ẹsẹ Bíbélì yẹn ṣàkópọ̀ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run pé ó máa fòpin sí gbogbo ìjìyà. Ó máa ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó bá mú ogun, ebi, àìlera, àìsí ìdájọ́ òdodo títí kan gbogbo àwọn èèyàn burúkú kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè ṣe èyí.
ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe
Ọlọ́run máa lo ẹnì kejì tó lágbára jù lọ ní ayé àti ọ̀run láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ìyẹn Jésù Kristi tó ti jíǹde. Ìgbà ń bọ̀ tí Jésù máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba lórí gbogbo ilẹ̀ ayé láìsí ẹni tó máa ta kò ó. Àwọn ọba, ààrẹ orílẹ̀-èdè tàbí àwọn olóṣèlú kò tún ní ṣàkóso lórí aráyé mọ́ láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọba kan àti ìjọba kan, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run ló máa ṣàkóso aráyé.
Ìjọba yẹn máa fi òpin sí gbogbo ìṣàkóso èèyàn. Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dáníẹ́lì 2:44) Àwọn èèyàn tó wà ní gbogbo ayé máa wà níṣọ̀kan lábẹ́ ìjọba òdodo kan, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run.
Nígbà tí Jésù wà ní ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn, ó sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba yẹn ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Ó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àdúrà àwòṣe, ó fún wọn nítọ̀ọ́ni láti gbàdúrà lọ́nà yìí: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Kíyè sí pé Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba yẹn ló máa jẹ́ kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, ìfẹ́ Ọlọ́run sì ni láti mú òpin dé bá ìjìyà níbi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé.
Ìjọba òdodo Ọlọ́run máa mú ìbùkún wá fáwọn èèyàn irú èyí tí ìjọba èèyàn kò lè mú wá láéláé. Má gbàgbé pé Jèhófà fún wa ní Ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà kí àwa èèyàn lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run tó máa ṣe aráyé lóore bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso, àwọn èèyàn máa di ẹ̀dá pípé. Kí ló máa jẹ́ àbájáde rẹ̀? Jèhófà “yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.”—Aísáyà 25:8.
Àwọn kan lè béèrè pé: ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run kò ṣe wá nǹkan ṣe sí i láti ọjọ́ yìí? Kí ló ń dúró dè?’ Ó ṣeé ṣe kí Jèhófà ti fòpin sí ìjìyà tipẹ́tipẹ́ tàbí kó má tiẹ̀ jẹ́ kí ìjìyà èyíkéyìí wáyé. Àmọ́, ó fàyè gbà á fún àǹfààní ayérayé àwa ọmọ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, kì í sì í ṣe fún àǹfààní ara rẹ̀. Àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn máa gbà pé kí ọmọ náà jẹ àwọn ìyà kan tí wọ́n bá mọ̀ pé ìyẹn ló máa ṣe é ní àǹfààní tó máa tọ́jọ́. Bákan náà, àwọn ìdí pàtàkì wà tó mú kí Jèhófà fàyè gba ìjìyà ẹ̀dá èèyàn fún ìgbà díẹ̀, ó sì ṣàlàyé àwọn ohun tó fà á nínú Bíbélì. Lára wọn ni òmìnira láti yan ohun tó wù wá, ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀ tó kan ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti máa ṣàkóso. Bíbélì tún ṣàlàyé pé, Ọlọ́run fàyè gba ẹ̀dá ẹ̀mí búburú kan láti ṣàkóso ayé fún ìgbà díẹ̀. a
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a kò lè ṣàlàyé gbogbo ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà nínú àpilẹ̀kọ yìí, síbẹ̀ àwọn nǹkan méjì kan wà tó máa fún wa ní ìrètí àti ìṣírí. Àkọ́kọ́ ni pé: Kékeré ni ìyà èyíkéyìí tó lè ti jẹ wá máa jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀ ìbùkún tí Jèhófà máa fi jíǹkí wa. Ọlọ́run fi dá wa lójú pé: “Àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.” (Aísáyà 65:17) Ọlọ́run máa mú ìbànújẹ́ àti ìjìyà tó jẹ́ àbájáde ibi tó ti fàyè gbà fún ìgbà díẹ̀ kúrò pátápátá.
Nǹkan kejì rèé: Ọlọ́run ti dá ọjọ́ kan tí kò ní yẹ̀ tó máa mú òpin dé bá ìjìyà. Má gbàgbé pé wòlíì Hábákúkù béèrè lọ́wọ́ Jèhófà bí àkókò tó fi máa fàyè gba ìwà ipá àti rúkèrúdò ṣe máa pẹ́ tó. Jèhófà dá a lóhùn pé: “Ìran náà ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀. . . Kì yóò pẹ́.” (Hábákúkù 2:3) A máa rí i nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e pé “àkókò tí a yàn kalẹ̀” náà ti sún mọ́lé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà, wo orí 11 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Tó Sọ Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Aláyọ̀
KÒ NÍ SÍ OGUN MỌ́:
“Ẹ wá wo àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà, bí ó ti gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayanilẹ́nu kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 46:8, 9.
ÀWỌN ÒKÚ MÁA PA DÀ WÀ LÁÀYÈ:
“Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15.
OÚNJẸ MÁA WÀ FÚN GBOGBO ÈÈYÀN:
“Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:16.
KÒ NÍ SÍ ÀÌSÀN MỌ́:
“Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.
KÒ NÍ SÍ ÀWỌN ÈÈYÀN BÚBURÚ MỌ́:
“Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.”—Òwe 2:22.
ÌDÁJỌ́ ÒDODO MÁA LÉKÈ:
“Wò ó! Ọba kan [Kristi Jésù] yóò jẹ fún òdodo; àti ní ti àwọn ọmọ aládé, wọn yóò ṣàkóso bí ọmọ aládé fún ìdájọ́ òdodo.”—Aísáyà 32:1.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ìjọba Ọlọ́run máa mú ìyà èyíkéyìí tó lè ti jẹ wá kúrò