Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ọ̀nà Wo Ni Jèhófà Ń Gbà Fìfẹ́ Hàn sí Wa?

Àwọn Ọ̀nà Wo Ni Jèhófà Ń Gbà Fìfẹ́ Hàn sí Wa?

“Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba ti fi fún wa”!1 JÒH. 3:1.

ORIN: 91, 13

1. Kí ni àpọ́sítélì Jòhánù rọ̀ wá pé ká gbé yẹ̀ wò, kí sì nìdí?

Ó YẸ ká mọrírì ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ nínú 1 Jòhánù 3:1 ká sì ronú jinlẹ̀ lé e lórí. Nígbà tí Jòhánù sọ pé, “ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba ti fi fún wa,” ńṣe ló ń rọ àwọn Kristẹni tòótọ́ pé kí wọ́n ronú lórí irú ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wọn àti bí ìfẹ́ náà ṣe pọ̀ tó. Ó sì tún fẹ́ kí wọ́n ronú lórí bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn. Tá a bá ń ronú lórí àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà fìfẹ́ hàn sí wa, ìfẹ́ tá a ní fún un á pọ̀ sí i, àá sì tún ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú rẹ̀.

2. Kí nìdí tó fi ṣòro fún àwọn kan láti gbà pé Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn?

2 Àwọn kan wà tí wọn ò gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn. Wọ́n gbà pé ẹni ẹ̀rù tó yẹ ká máa ṣègbọràn sí ni. Tàbí kí àwọn ẹ̀kọ́ èké kan tí wọ́n ti kọ́ mú kí wọ́n gbà pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ wa, a ò sì lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́ àwọn míì gbà pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ò láàlà, wọ́n gbà pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn láìka ohun tí àwọn bá ṣe sí. Nígbà tó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó yé ẹ pé ìfẹ́ ni ànímọ́ Jèhófà tó ta yọ jù lọ, ìfẹ́ tó ní sí wa ló sì sún un láti fi Ọmọ rẹ̀ rúbọ torí wa. (Jòh. 3:16; 1 Jòh. 4:8) Síbẹ̀, bí wọ́n ṣe tọ́ ẹ àti ibi tó o gbé dàgbà lè nípa lórí ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run.

3. Kí ló mú ká mọrírì ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa?

 3 Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà nífẹ̀ẹ́ wa? A lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí tá a bá ronú lórí àjọṣe pàtàkì tó wà láàárín àwa àti Jèhófà Ọlọ́run. A mọ̀ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá gbogbo èèyàn. (Ka Sáàmù 100:3-5.) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Ádámù ní “ọmọkùnrin Ọlọ́run,” tí Jésù náà sì kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa sọ pé “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run” tí wọ́n bá ń gbàdúrà. (Lúùkù 3:38; Mát. 6:9) Torí pé Jèhófà ló dá wa, òun ni Baba wa, àjọṣe baba sí ọmọ la sì ní pẹ̀lú rẹ̀. Látàrí èyí, bí bàbá onífẹ̀ẹ́ kan ṣe ń nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa.

4. (a) Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín Jèhófà àti àwọn bàbá tó bí wa? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e?

4 Aláìpé ni àwọn bàbá tó bí wa. Bó ti wù kí wọ́n gbìyànjú tó, wọn ò lè nífẹ̀ẹ́ wa bíi ti Jèhófà. Kódà, àwọn kan ti ní ọgbẹ́ ọkàn torí ìwà òǹrorò tí wọ́n hù sí wọn nínú ìdílé tí wọ́n gbé dàgbà. Ìyẹn máa ń fa ìrora ó sì máa ń kó ìbànújẹ́ báni. Àmọ́, ó dá wa lójú pé Jèhófà kì í ṣe irú bàbá bẹ́ẹ̀. (Sm. 27:10) Tá a bá mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an ó sì ń tọ́jú wa, ó dájú pé ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. (Ják. 4:8) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ọ̀nà mẹ́rin tí Jèhófà ń gbà fìfẹ́ hàn sí wa. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò ọ̀nà mẹ́rin tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

JÈHÓFÀ Ń FÌFẸ́ PÈSÈ ÀWỌN OHUN TÁ A NÍLÒ

5. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Áténì nípa Ọlọ́run?

5 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà ní Áténì, ní ìlú Gíríìsì, ó kíyè sí i pé ìlú náà kún fún ère àwọn òrìṣà àti àwọn ọlọ́run àjúbàfún tí wọ́n gbà pé ó fún àwọn ní ẹ̀mí àti àwọn ohun kòṣeémáàní. Èyí mú kí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run tí ó dá ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀ . . . ni ó fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo. . . . Nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa ní ìwàláàyè, tí a ń rìn, tí a sì wà.” (Ìṣe 17:24, 25, 28) Láìsí àní-àní, ìfẹ́ ló mú kí Jèhófà pèsè “ohun gbogbo” tó jẹ́ kòṣeémáàní láti gbé ìwàláàyè wa ró. Ronú lórí ohun tí gbólóhùn yẹn ní nínú.

6. Báwo ni ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá ayé ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

6 Ronú nípa ayé tí Jèhófà Ẹlẹ́dàá ti “fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.” (Sm. 115:15, 16) Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ná ọ̀pọ̀ owó lórí ìwádìí nípa òfúúrufú bóyá wọ́n lè rí pílánẹ́ẹ̀tì tó dà bíi tiwa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ṣàwárí ọgọ́rọ̀ọ̀rún pílánẹ́ẹ̀tì, wọn ò rí ọ̀kan ṣoṣo nínú wọn tó ní gbogbo ohun tó lè gbé ìwàláàyè ró bíi ti ayé wa yìí. Ilẹ̀ ayé wa yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá. Tiẹ̀ rò ó wò ná, nínú àìlóǹkà pílánẹ́ẹ̀tì tó wà lágbàáyé, kì í ṣe pé Jèhófà dá ayé ká lè gbé inú rẹ̀ nìkan ni, àmọ́ ó dá a kó lè jẹ́ ibi tó tuni lára, tó lẹ́wà tí kò sì léwu láti gbé! (Aísá. 45:18) Gbogbo èyí ń fi bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó hàn.Ka Jóòbù 38:4, 7; Sáàmù 8:3-5.

7. Báwo ni ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá wa ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa?

7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹlẹ́wà ni Jèhófà fún wa, ó mọ̀ pé ká tó lè láyọ̀ ká sì ní ìtẹ́lọ́rùn, a nílò ju àwọn ohun tara lọ. Bí ọmọ kan bá mọ̀ pé àwọn òbí òun nífẹ̀ẹ́ òun wọ́n sì ń tọ́jú òun, ọkàn rẹ̀ á balẹ̀. Jèhófà dá wa ní àwòrán ara rẹ̀, èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa ó sì ń tọ́jú wa. (Jẹ́n. 1:27) Láfikún síyẹn, Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mát. 5:3) Baba  onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, torí náà ó “ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa” nípa tara àti nípa tẹ̀mí.1 Tím. 6:17; Sm. 145:16.

JÈHÓFÀ Ń FÌFẸ́ KỌ́ WA LẸ́KỌ̀Ọ́ ÒTÍTỌ́

8. Kí nìdí tá a fi lè retí pé kí “Ọlọ́run òtítọ́” fìfẹ́ hàn sí wa?

8 Àwọn bàbá fẹ́ràn àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì máa ń fẹ́ dáàbò bò wọ́n kí àwọn ẹlòmíì má bàa ṣì wọ́n lọ́nà tàbí kí wọ́n tàn wọ́n jẹ. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ òbí ò lè tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà torí pé àwọn gan-an ò fara mọ́ ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìjákulẹ̀ àti ìdàrúdàpọ̀ lèyí sì máa ń yọrí sí. (Òwe 14:12) Àmọ́, Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run òtítọ́.” (Sm. 31:5) Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ó sì wù ú kí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ máa tàn kó lè máa tọ́ wọn sọ́nà bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn, pàápàá jù lọ nínú ìjọsìn wọn. (Ka Sáàmù 43:3.) Òtítọ́ wo ni Jèhófà ń fi hàn wá, báwo nìyẹn sì ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa?

Àwọn bàbá tó jẹ́ Kristẹni máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà nípa kíkọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Baba wọn ọ̀run (Wo ìpínrọ̀ 8 sí 10)

9, 10. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa látinú ohun tó sọ fún wa (a) nípa ara rẹ̀? (b) nípa wa?

9 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jèhófà sọ òtítọ́ nípa ara rẹ̀ fún wa. Ó sọ orúkọ ara rẹ̀ fún wa, orúkọ yìí ló sì fara hàn jù lọ nínú gbogbo orúkọ tó wà nínú Bíbélì. Lọ́nà yìí, Jèhófà ń jẹ́ ka mọ òun, ó sì ń jẹ́ ká lè ní àjọṣe pẹ̀lú òun. (Ják. 4:8) Jèhófà tún jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ tí òun ní àti irú Ọlọ́run tí òun jẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àgbáyé wa ń fi agbára àti ọgbọ́n rẹ̀ hàn, Ìwé Mímọ́ tún jẹ́ ká mọ̀ pé ó jẹ́ onídàájọ́ òdodo, ìfẹ́ rẹ̀ kò sì láfiwé. (Róòmù 1:20) Ó dà bíi bàbá kan tí kì í ṣe pé ó kàn lágbára tó sì gbọ́n nìkan ni, àmọ́ ó nífẹ̀ẹ́ ó sì máa ń fòye báni lò, èyí wá mú kó rọrùn fún àwọn ọmọ rẹ̀ láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.

10 Jèhófà tún ṣe ohun kan fún àǹfààní gbogbo wa. Ó sọ ohun tó ní lọ́kàn nípa wa fún wa, ìyẹn ni ipa tá à ń kó nínú ìṣètò rẹ̀. Èyí sì máa ń pa kún àlàáfíà àti ètò tó wà nínú ìdílé rẹ̀ láyé àti lọ́run. Bíbélì kọ́ wa pé Ọlọ́run ò dá àwa èèyàn láti máa dá ṣèpinnu tàbí ká wà láì gbára lé Ọlọ́run, tá ò bá fara mọ́ òtítọ́ yìí, ohun búburú ló máa tìdí ẹ̀ yọ. (Jer. 10:23) Ó ṣe pàtàkì ká gbà pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn tá a bá fẹ́ máa láyọ̀. Ó dìgbà tá a bá gbà pé Ọlọ́run láṣẹ lórí wa, ká tó lè ní àlààfíà ká sì wà ní ìṣọ̀kan. Torí náà, àfi ká máa dúpẹ́ pé Jèhófà jẹ́ ká mọ àwọn ohun pàtàkì yìí!

11. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún wa tó jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wa jẹ ẹ́ lógún àti pé ó nífẹ̀ẹ́ wa?

11 Ọjọ́ iwájú àwọn ọmọ máa ń jẹ bàbá wọn lógún, ó sì máa ń wù ú pé kí wọ́n ní ohun tó dáa àti ohun tó nítumọ̀ tí wọ́n á fi ìgbésí ayé wọn ṣe. Ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, tàbí kí wọ́n máa fi ìgbésí ayé wọn lépa àwọn ohun tí kò ní láárí. (Sm. 90:10) Torí pé ọmọ Ọlọ́run ni wá, a mọ̀ pé òótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ó sì ṣèlérí ọjọ́ ọ̀la tó lárinrin fún wa. Èyí ló mú kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀.

JÈHÓFÀ Ń FÚN ÀWỌN ỌMỌ RẸ̀ NÍ ÌMỌ̀RÀN ÀTI ÌBÁWÍ

12. Báwo ni ìbáwí tí Jèhófà fún Kéènì àti ìmọ̀ràn tó fún Bárúkù ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ ẹ́ lógún?

12 Jèhófà sọ fún Kéènì pé: “Èé ṣe tí ìbínú rẹ fi gbóná, èé sì ti ṣe tí ojú rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì? Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí? . . . Ìwọ yóò ha sì kápá [ẹ̀ṣẹ̀] bí?” (Jẹ́n. 4:6, 7) Ọlọ́run fún Kéènì ní ìmọ̀ràn tó bọ́ sákòókò àti ìtọ́sọ́nà tó wúlò. Lọ́nà yìí, Jèhófà kìlọ̀ fún Kéènì nígbà tó rí i pé ó ti fẹ́ ṣe ohun tí ò dáa. Àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé Kéènì ò fetí sí ìkìlọ̀ Jèhófà ó sì jìyà ohun tó ṣe yẹn. (Jẹ́n.  4:11-13) Nígbà tí nǹkan tojú sú akọ̀wé Jeremáyà tó ń jẹ́ Bárúkù tí inú rẹ̀ sì bà jẹ́, Jèhófà gbà á nímọ̀ràn kó bàa lè rí ohun tó jẹ́ ìṣòro rẹ̀. Bárúkù ò ṣàìgbọràn bíi ti Kéènì, ó gba ìmọ̀ràn, Jèhófà sì dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.Jer. 45:2-5.

13. Kí nìdí tí Jèhófà fi yọ̀ǹda pé kí àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́ kojú àdánwò?

13 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí; ní ti tòótọ́, ó máa ń na olúkúlùkù ẹni tí ó gbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ lọ́rẹ́.” (Héb. 12:6) Kì í ṣe tí wọ́n bá nani lọ́rẹ́ nìkan la lè sọ pé wọ́n báni wí. Oríṣiríṣi ọ̀nà la lè gbà báni wí. Nínú Bíbélì, a rí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n dojú kọ àdánwò tó le koko, èyí tó ṣeé ṣe kó la ìbáwí lọ, àmọ́ wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìbáwí náà. Ronú nípa Jósẹ́fù, Mósè àti Dáfídì. Ìtàn ìgbésí ayé wọn wà lára àwọn ìtàn tó gùn jù lọ nínú Bíbélì tí àlàyé rẹ̀ sì ṣe kedere. Tá a bá ń kà nípa bí Jèhófà ṣe dúró tì wọ́n nígbà ìṣòro àti bó ṣe lò wọ́n láti ṣe àwọn ohun ribiribi, àá túbọ̀ rí bí Jèhófà ṣe ń tọ́jú wa tó sì ń fìfẹ́ hàn sí wa.Ka Òwe 3:11, 12.

14. Báwo la ṣe lè rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa nínú ìbáwí tó bá fun wa?

14 A tún lè rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa nínú ìbáwí tó bá fún wa. Tí Jèhófà bá bá àwọn tó hùwà àìtọ́ wí, tí wọ́n bá fetí sílẹ̀ tí wọ́n sì ronú pìwà dà, ó máa “dárí jì lọ́nà títóbi.” (Aísá. 55:7) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Dáfídì sọ ohun tó wọni lọ́kàn nípa bí Jèhófà ṣe ń dárí jini nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí ń dárí gbogbo ìṣìnà rẹ jì, ẹni tí ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn, ẹni tí ń gba ìwàláàyè rẹ padà kúrò nínú kòtò, ẹni tí ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú dé ọ ládé. Bí yíyọ oòrùn ti  jìnnà réré sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ìrélànàkọjá wa jìnnà réré sí wa.” (Sm. 103:3, 4, 12) Ǹjẹ́ kí àwa náà máa gba ìmọ̀ràn Jèhófà, kódà tó bá bá wa wí ká tètè ṣègbọràn, ká sì máa rántí pé ìfẹ́ tí kò láfiwé tó ní sí wa ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀.Sm. 30:5.

JÈHÓFÀ Ń DÁÀBÒ BÒ WÁ Ó SÌ Ń FI ÌṢỌ́ ṢỌ́ WA

15. Kí ló fi hàn pé àwọn èèyàn Jèhófà ṣeyebíye lójú rẹ̀?

15 Ó dájú pé ọ̀kan lára ohun tí bàbá onífẹ̀ẹ́ kan máa ń kà sí pàtàkì ni bó ṣe máa dáàbò bo ìdílé rẹ̀ kó sì pa wọ́n mọ́ lọ́wọ́ ewu tàbí ohun tó lè ṣèpalára fún wọn. Ohun tí Jèhófà, Baba wa ọ̀run náà máa ń ṣe nìyẹn. Onísáàmù náà sọ nípa Jèhófà pé: “Ó ń ṣọ́ ọkàn àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀; ó ń dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.” (Sm. 97:10) Jẹ́ ká wò ó báyìí ná: O ka ojú rẹ sí ohun tó ṣeyebíye, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bí Jèhófà náà ṣe ka àwọn èèyàn rẹ̀ sí iyebíye nìyẹn. (Ka Sekaráyà 2:8.) Ẹ sì wo bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ṣeyebíye tó lójú rẹ̀!

16, 17. Ṣàlàyé àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ tó sì pa wọ́n mọ́, kódà ní àkókò tá à ń gbé yìí.

16 Jèhófà máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì. (Sm. 91:11) Áńgẹ́lì kan ṣoṣo gba ìlú Jerúsálẹ́mù sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà tí wọ́n wá gbógun tì í, ó sì pa ọmọ ogun ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] lálẹ́ ọjọ́ kan. (2 Ọba 19:35) Áńgẹ́lì dá àpọ́sítélì Pétérù, Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. (Ìṣe 5:18-20; 12:6-11) Ọwọ́ Jèhófà ò sì kúrú ní àkókò tá à ń gbé yìí náà. Aṣojú oríléeṣẹ́ wa kan tó ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kan nílẹ̀ Áfíríkà ròyìn pé ìjà òṣèlú àti ìjà ẹ̀sìn ti ba orílẹ̀-èdè náà jẹ́. Ìjà, jíjí ẹrù ẹlẹ́rù kó, ìfipábánilòpọ̀ àti ìpànìyàn sì ti dá rúkèrúdò àti ọ̀pọ̀ rúgúdù sílẹ̀ níbẹ̀. Síbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa pàdánù gbogbo ohun ìní àti iṣẹ́ wọn, kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó kú. Tẹ́ ẹ bá bi ẹnikẹ́ni nínú wọn pé báwo ni nǹkan ṣe ń lọ sí, á bú sẹ́rìn-ín, á sì sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Jèhófà, kò sí láburú kankan!” Ó dájú pé wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn.

17 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sítéfánù jẹ́ ká rí i pé nígbà míì Jèhófà lè yọ̀ǹda pé kí àwọn ọ̀tá gba ẹ̀mí ẹnì kan tó jẹ́ olóòótọ́. Síbẹ̀, Ọlọ́run máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lápapọ̀ nípa fífún wọn ní àwọn ìkìlọ̀ tó bágbà mu nípa àwọn ètekéte Sátánì. (Éfé. 6:10-12) Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì tí ètò Ọlọ́run ń mú jáde, à ń mọ ewu tó wà nínú eré ìnàjú tó ń gbé ìṣekúṣe àti ìwà ipá lárugẹ, lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́nà tí kò tọ́, agbára ẹ̀tàn tí ọrọ̀ ní àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó wá ṣe kedere pé Bàbá onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, kò sì fẹ́ kí ohunkóhun wu wọ́n léwu.

ÀǸFÀÀNÍ TÍTAYỌ

18. Báwo ni ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí ẹ ṣe rí lára rẹ?

18 Lẹ́yìn tá a ti ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà títayọ tí Jèhófà ń gbà fìfẹ́ hàn sí wa, ṣe ni ìmọ̀lára tiwa náà wá dà bíi ti Mósè. Nígbà tí Mósè ronú nípa ọ̀pọ̀ ọdún tó ti fi sin Jèhófà, ó sọ pé: “Fi inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀, kí a lè fi ìdùnnú ké jáde, kí a sì lè máa yọ̀ ní gbogbo ọjọ́ wa.” (Sm. 90:14) Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa tá a sì ń jọlá ìfẹ́ yìí jẹ́ ọ̀kan lára àǹfààní àti ìbùkún tó ta yọ jù lọ tá a lè ní lónìí. Bíi ti àpọ́sítélì Jòhánù, àwa náà lè sọ pé: “Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba ti fi fún wa”!1 Jòh. 3:1.