Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Lè Jẹ́ Oníwà Mímọ́

A Lè Jẹ́ Oníwà Mímọ́

“Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, . . . kí ẹ sì wẹ ọkàn-àyà yín mọ́ gaara.” —JÁK. 4:8.

1. Kí lèrò àwọn èèyàn nípa ìwà mímọ́ lóde òní?

ÌWÀ mímọ́ kì í ṣe ohun tó wọ́pọ̀, pàápàá lóde òní. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn èèyàn kò rí ohun tó burú nínú kí ọkùnrin máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin àti kí obìnrin ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin tàbí kéèyàn ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni. Kódà wọ́n ń fi ìpolówó ọjà àti eré orí ìtàgé gbé irú àṣà bẹ́ẹ̀ lárugẹ. (Sm. 12:8) Ìṣekúṣe ti wá di ohun tó gbòde kan débi pé a lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí èèyàn jẹ́ oníwà mímọ́ nínú ayé yìí?’ Ó dájú pé Jèhófà lè ran àwọn Kristẹni tòótọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè jẹ́ oníwà mímọ́.—Ka 1 Tẹsalóníkà 4:3-5.

2, 3. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká sapá láti borí èrò ìṣekúṣe? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé tí a bá fẹ́ jẹ́ oníwà mímọ́, a gbọ́dọ̀ kọ ìfẹ́ ìṣekúṣe sílẹ̀ lákọ̀tán. Bí ìdẹ tó wà lẹ́nu ìwọ̀ ṣe máa ń fa ẹja mọ́ra, bẹ́ẹ̀ náà ni èròkerò àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ṣe lè fa Kristẹni kan lọ, tí kò bá tètè gbé e kúrò lọ́kàn. Wọ́n lè ṣàkóbá fún ara àìpé wa, kí wọ́n sì sún wa ṣèṣekúṣe. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, adùn tẹ́nì kán rò pé ó wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ lè kó sí i lórí débi pé kò ní lè kápá irú èròkerò bẹ́ẹ̀ mọ́. Ní irú àkókò yìí, kódà ìránṣẹ́ Jèhófà kan  lè ṣe ohun tó ń rò lọ́kàn tí àyè bá ṣí sílẹ̀. Kò sí àní-àní pé “ìfẹ́-ọkàn náà . . . a bí ẹ̀ṣẹ̀.”—Ka Jákọ́bù 1:14, 15.

3 Ó yẹ ká ronú jinlẹ̀ lórí bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó wà fún ìgbà díẹ̀ ṣe lè di ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Àmọ́, ó tù wá nínú láti mọ̀ pé tí a kò bá jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ jọba lọ́kàn wa, a kò ní lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe ká sì jìyà àwọn àbájáde rẹ̀! (Gál. 5:16) Ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun mẹ́ta tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí èrò ìṣekúṣe, ìyẹn ni: àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà, ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti ìrànwọ́ látọ̀dọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn.

“Ẹ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN”

4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká sún mọ́ Jèhófà?

4 Bíbélì fún àwọn tó fẹ́ “sún mọ́ Ọlọ́run” ní ìtọ́ni pé: “Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, . . . kí ẹ sì wẹ ọkàn-àyà yín mọ́ gaara.” (Ják. 4:8) Tá a bá ka àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà sí ohun tó ṣeyebíye, àá sapá láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní gbogbo apá ìgbésí ayé wa, títí kan àwọn ohun tá à ń rò lọ́kàn. Tá a bá fẹ́ “mọ́ ní ọkàn-àyà,” ó yẹ ká máa ronú lórí ohun tí ó mọ́, ohun tó tọ́ àti ohun tí ó yẹ fún ìyìn. (Sm. 24: 3, 4; 51:6; Fílí. 4:8) Òótọ́ ni pé Jèhófà máa ń gbójú fo àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tí àìpé wa máa ń fà, torí ó mọ̀ pé èròkerò lè wá sí wa lọ́kàn. Síbẹ̀, a mọ̀ pé inú Ọlọ́run ò ní dùn tá a bá fàyè gba èrò tí kò tọ́ lọ́kàn wa, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti má ṣe fàyè gbà á. (Jẹ́n. 6:5, 6) Tá a bá ń ronú lórí kókó yìí, èyí á jẹ́ kí ìpinnu wa láti mú kí èrò ọkàn wa jẹ́ mímọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ sí i.

5, 6. Báwo ni àdúrà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí èrò ìṣekúṣe?

5 Ọ̀nà pàtàkì kan tó máa fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá ni pé, ká bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ ká lè borí èrò tí kò tọ́. Tá a bá sún mọ́ Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà, òun náà á sún mọ́ wa. Jèhófà máa ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ní fàlàlà ká lè túbọ̀ dúró lórí ìpinnu wa láti sá fún èrò ìṣekúṣe, ká sì jẹ́ oníwà mímọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ kí àṣàrò ọkàn wa jẹ́ kí Ọlọ́run mọ̀ pé a máa sa gbogbo ipá wa láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Sm. 19:14) Ǹjẹ́ à ń fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kó yẹ̀ wá wò, bóyá “ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára,” ìyẹn èròkerò tàbí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, wà lọ́kàn wa tó lè yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀? (Sm. 139:23, 24) Ǹjẹ́ à ń bẹ Jèhófà lóòrèkóòrè pé kó ràn wá lọ́wọ́, ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí i nígbà tá a bá dojú kọ àdánwò?—Mát. 6:13.

6 Ó ṣeé ṣe kí ìwà tá à ń hù tẹ́lẹ̀ tàbí bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà ti mú ká máa hu àwọn ìwà tí Jèhófà kà léèwọ̀. Síbẹ̀, Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe àwọn àtúnṣe táá jẹ́ ká lè máa sìn ín lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Èyí dá Dáfídì Ọba lójú, kódà lẹ́yìn tó bá Bátí-ṣébà ṣe panṣágà, ó bẹ Jèhófà pé: “Dá ọkàn-àyà mímọ́ gaara sínú mi, . . . Kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, ọ̀kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.” (Sm. 51:10, 12) Torí pé aláìpé ni wá, ó lè wù wá gan-an ká lọ́wọ́ nínú ìwà tó lè yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀, àmọ́ Jèhófà lè mú kó máa wù wá látọkàn wá láti máa ṣègbọràn sí i. Kódà tí èròkerò bá gbilẹ̀ lọ́kàn wa, tó sì ń darí ìrònú wa láti hu ìwà àìmọ́, Jèhófà lè tọ́ wa sọ́nà ká lè máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, kó sì hàn bẹ́ẹ̀ nínú bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa. Ó lè dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ewu èyíkéyìí tó lè fẹ́ borí wa.—Sm. 119:133.

Tí èròkerò bá ti ń wá sí wa lọ́kàn, kódà kó jẹ́ fúngbà díẹ̀, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀ lọ́kàn wa, a gbọ́dọ̀ fà á tu lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 6)

“Ẹ DI OLÙṢE Ọ̀RỌ̀ NÁÀ”

7. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè dáàbò bò wá ká lè yẹra fún èrò tí kò mọ̀?

7 Tá a bá bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́, ó lè dáhùn àdúrà wa nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọgbọ́n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run a “kọ́kọ́ mọ́ níwà.” (Ják. 3:17) Tá a bá fẹ́ yẹra fún èròkerò, a gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ ká sì máa ṣàṣàrò lórí àwọn  ohun tá a kà. (Sm. 19:7, 11; 119:9, 11) Bákan náà, Ìwé Mímọ́ fún wa ní àwọn àpẹẹrẹ àti ìmọ̀ràn tó ṣe pàtó tó lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè yẹra fún èrò tí kò mọ́.

8, 9. (a) Kí ló sún ọ̀dọ́kùnrin kan débi tó fi bá aṣẹ́wó kan ní ìbálòpọ̀? (b) Inú àwọn ipò wo lóde òní ló ti ṣe pàtàkì pé ká fi ìkìlọ̀ tó wà nínú Òwe orí keje sílò?

8 Ìwé Òwe 5:8 kà pé: “Jẹ́ kí ọ̀nà rẹ jìnnà réré sí ẹ̀gbẹ́ [obìnrin oníṣekúṣe]; má sì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀.” Òwe orí keje sọ ewu tó wà nínú ká máa fojú kéré ìkìlọ̀ yìí, ó sọ nípa ọ̀dọ́kùnrin kan tó gbafẹ́ jáde lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, àmọ́ tó lọ gba ọ̀nà ilé obìnrin aṣẹ́wó kan kọjá. Bó ti ń lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, obìnrin náà sún mọ́ ọn, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé aṣọ péńpé tó fi ara sílẹ̀ ni obìnrin náà wọ̀. Ó dì mọ́ ọ̀dọ́kùnrin náà, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Àwọn ọ̀rọ̀ dídún tí obìnrin náà sọ kó sí ọ̀dọ́kùnrin náà lórí débi tí kò fi lè já ara rẹ̀ gbà lọ́wọ́ obìnrin náà. Ó mà ṣe o, wọ́n bá ara wọn ṣèṣekúṣe. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ó ṣeé ṣe kí ọ̀dọ́kùnrin náà máà ní in lọ́kàn láti lọ ṣe ìṣekúṣe nígbà tó ń jáde nílé. Àìní ìrírí àti àìlo ìfòyemọ̀ ló kó bá a. Síbẹ̀, ó ní láti jìyà àbájáde ìwà búburú tó hù. Ká ní ó sá fún obìnrin oníṣekúṣe yìí ni, ì bá má ti kó sí wàhálà yìí!—Òwe 7:6-27.

9 Àwa náà lè hùwà láìlo ìfòyemọ̀, tí a  bá lọ fi ara wa sínú àwọn ipò tó lè mú kó máa wù wá láti ṣe ìṣekúṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan lè gbé ohunkóhun tó wù wọ́n jáde sórí afẹ́fẹ́ ní òru. Tó bá wá jẹ́ pé ìgbà yẹn là ń wá àwọn ètò tí wọ́n ń ṣe lóríṣiríṣi lórí tẹlifíṣọ̀n ńkọ́? Àbí kó jẹ́ pé, ńṣe la kàn ń ṣí ìlujá tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí àwọn ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti àwọn ìkànnì míì tí wọ́n fi ń peni wá wo àwọn àwòrán, orin tàbí fídíò tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ, àbí tó ń fi ìbálòpọ̀ lọni. Tá a bá ṣe èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan yìí, ó ṣeé ṣe ká rí ohun tó lè mú kó máa wù wá láti ṣe ìṣekúṣe, kó sì wá nira fún wa láti jẹ́ oníwà mímọ́.

10. Ewu wo ló wà nínú kéèyàn máa tage? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

10 Ọ̀nà míì tí Bíbélì gbà ràn wá lọ́wọ́ ni pé, ó fún wa ní ìmọ̀ràn nípa bó ṣe yẹ kí ọkùnrin àti obìnrin máa ṣe sí ara wọn. (Ka 1 Tímótì 5:2.) Ìmọ̀ràn yìí fi hàn pé kò tọ̀nà kéèyàn máa tage. Àwọn kan rò pé kò sí ohun tó burú nínú kéèyàn kàn fojú sọ̀rọ̀, kó fara sọ̀rọ̀ tàbí kéèyàn dínjú sẹ́nì kan lọ́nà tó lè mú kí ọkàn onítọ̀hún fà sí ìṣekúṣe, tí kò bá ṣáà ti fara kan onítọ̀hún. Àmọ́, tẹ́nì kan bá ń tage tàbí tó fàyè gbà á, o lè mú kí onítọ̀hún bẹ̀rẹ̀ sí í ro èròkerò, ó sì lè yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀ tó burú jáì. Ó ti ṣẹlẹ̀ rí, ó sì tún lè ṣẹlẹ̀.

11. Àpẹẹrẹ rere wo ní Jósẹ́fù fi lélẹ̀?

11 Ní ti Jósẹ́fù, ó fi ọgbọ́n hùwà. Nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì ọ̀gá rẹ̀ gbìyànjú láti fa ojú rẹ̀ mọ́ra, Jósẹ́fù kọ̀ jálẹ̀. Àmọ́, ìyàwó Pọ́tífárì kò jáwọ́, ojoojúmọ́ ló fi ń rọ Jósẹ́fù pé kó wà pẹ̀lú òun. (Jẹ́n. 39:7, 8, 10) Ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan sọ pé ohun tí ìyàwó Pọ́tífárì ń dọ́gbọ́n ń sọ ni pé: “‘Jẹ́ kí èmi àtìẹ jọ wa pa pọ̀ láwa nìkan fúngbà díẹ̀,’ ó sì ń retí pé èyí á mú kí [Jósẹ́fù] kọ́kọ́ nawọ́ ìfẹ́ sí òun.” Síbẹ̀, Jósẹ́fù ti pinnu pé òun ò ní ṣe ohun táá jẹ́ kó fa ojú òun mọ́ra tàbí gbà á láyè láti bá òun ṣe ohunkóhun. Jósẹ́fù kọ̀ jálẹ̀ láti bá a tage, kò sì jẹ́ kó bá òun náà tage, èyí ni kò sì jẹ́ kí èròkerò ráyè jọba lọ́kàn rẹ̀. Nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì fẹ́ fi dandan mú kí Jósẹ́fù ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú òun, Jósẹ́fù gbé ìgbésẹ̀ tó mọ́gbọ́n dání. ‘Ó fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí i lọ́wọ́, ó fẹsẹ̀ fẹ, ó sì bọ́ síta.’—Jẹ́n. 39:12.

12. Báwo la ṣe mọ̀ pé ohun tí à ń wò lè ṣàkóbá fún ọkàn wa?

12 Bákan náà, Bíbélì sọ ewu tó wà nínú jíjẹ́ kí ọkàn wa ro èròkerò nítorí àwọn ohun tí à ń wò. Ojú tí kò gbé ibì kan lè gbé ìfẹ́ fún ìṣekúṣe síni lọ́kàn tàbí kó jẹ́ kí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ lágbára lọ́kàn ẹni. Jésù kìlọ̀ fún wa pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mát. 5:28) Rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì Ọba. Bíbélì sọ pé: “Láti orí òrùlé náà ni [Dáfídì] sì ti tajú kán rí obìnrin kan tí ń wẹ.” (2 Sám. 11:2) Kò tètè gbójú kúrò níbẹ̀ kó sì máa ro nǹkan míì. Èyí mú kí ọkàn rẹ̀ máa fà sí ìyàwó oníyàwó, ó sì bá a ṣe panṣágà.

13. Kí nìdí tó fi yẹ ká ‘bá ojú wa dá májẹ̀mú,’ kí sì lèyí ní nínú?

13 Tá a bá fẹ́ borí fífọkàn yàwòrán ìṣekúṣe, a ní láti ‘bá ojú wa dá májẹ̀mú’ bíi ti Jóòbù tó jẹ́ adúróṣinṣin. (Jóòbù 31:1, 7, 9) A gbọ́dọ̀ pinnu tọkàntọkàn láti máa darí ojú wa, ká má sì máa ní èrò ìṣekúṣe lọ́kàn tá a bá ń wo àwọn èèyàn. Ó túmọ̀ sí pé ká gbé ojú wa kúrò nínú àwòrán èyíkéyìí tó lè mú ọkàn wa fà sí ìṣekúṣe bóyá lórí kọ̀ǹpútà ni o, nínú pátákó ìpolówó, èèpo ẹ̀yìn ìwé tàbí níbikíbi yòówù kó jẹ́.

14. Àǹfààní wo ni ìmọ̀ràn tó ní ká jẹ́ oníwà mímọ́ máa ṣe fún wa?

14 Ǹjẹ́ o ti rí apá tó kàn ọ́ nínú ìjíròrò  yìí, táá jẹ́ kó o lè borí èrò ìṣekúṣe tó lè wá síni lọ́kàn? Torí náà, gbé ìgbésẹ̀ ní kíá. Tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pátápátá, èyí á ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀, wàá sì jẹ́ oníwà mímọ́.—Ka Jákọ́bù 1:21-25.

‘PE ÀWỌN ALÀGBÀ’

15. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká wá ìrànlọ́wọ́ tó bá ṣòro fún wa láti borí èrò ìṣekúṣe?

15 Tá a bá ń sapá láti borí èrò ìṣekúṣe, àwọn tá a jọ jẹ́ ará ni orísun ìrànlọ́wọ́ míì tá a lè yíjú sí. Ká sòótọ́, kò rọrùn pé ká sọ àwọn ìṣòro ara ẹni fún àwọn ẹlòmíì. Àmọ́, tá a bá lo ìgboyà tá a sì rẹ ara wa sílẹ̀, tí a wá ní kí Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ yẹ̀ wá wo, kó sì sọ irú èèyàn tá a jẹ́ gan-an fún wa, èyí ò ní jẹ́ ká máa rò pé ó tọ́ láti gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ èyíkéyìí láyè. (Òwe 18:1; Héb. 3:12, 13) Tá a bá sọ ibi tá a kù sí fún Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ tó sì tóótun nípa tẹ̀mí, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn àbààwọ́n kan tèèyàn kì í sábà kíyè sí. Èyí sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tó ṣe pàtàkì táá jẹ́ ká lè dúró nínú ìfẹ́ Jèhófà.

16, 17. (a) Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ṣòro fún láti borí èrò tí kò tọ́? Ṣàpèjúwe. (b) Kí nìdí tó fi dá a pé kí àwọn tó ti wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe tètè wá ìrànlọ́wọ́?

16 Àwọn alàgbà kúnjú ìwọ̀n láti ràn wá lọ́wọ́. (Ka Jákọ́bù 5:13-15.) Ọ̀dọ́kùnrin kan ní orílẹ̀-èdè Brazil sapá láti borí èròkerò fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé inú Jèhófà kò dùn sí àwọn ohun tí mò ń fọkàn mi rò, àmọ́ ìtìjú kò jẹ́ kí n lè sọ bí nǹkan ṣe ń rí lára mi fún àwọn ẹlòmíì.” Ọpẹ́lọpẹ́ alàgbà kan tó kíyè sí i pé nǹkan kan ń ṣe ọ̀dọ́kùnrin yìí, ó lọ bá a, ó sì gbà á níyànjú pé kó wá ìrànlọ́wọ́. Ọ̀dọ́kùnrin náà sọ pé: “Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ bí àwọn alàgbà ṣe fìfẹ́ hàn sí mi, ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí mi àti bí wọ́n ṣe lóye mi kọjá ohun tí mo rò pé wọ́n lè ṣe fún mi. Wọ́n fara balẹ̀ tẹ́tí sí àwọn ìṣòro mi. Wọ́n lo Bíbélì láti fi dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi, wọ́n sì gbàdúrà pẹ̀lú mi. Èyí wá jẹ́ kó rọrùn láti gba ìmọ̀ràn inú Bíbélì tí wọ́n fún mi.” Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, bí ọ̀dọ́kùnrin náà ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó sọ pé: “Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yé mi báyìí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn máa wá ìrànlọ́wọ́, dípò tèèyàn á fi máa dá nìkan ru ẹrù ìnira rẹ̀ kiri.”

17 Ó ṣe pàtàkì pé ká wá ìrànlọ́wọ́ pàápàá tó bá jẹ́ pé wíwo àwọn ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ló gbé èròkerò sí wa lọ́kàn. Tá ò bá tètè wá ìrànlọ́wọ́, ńṣe ni ewu tí èrò tí kò mọ́ máa ń fà máa túbọ̀ lágbára sí i, ‘nígbà tí ó bá sì lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀’ tó máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn míì, táá sì kẹ́gàn bá orúkọ Jèhófà. Bí ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣé pinnu láti wà nínú ìjọ Kristẹni kí wọ́n sì máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ti jẹ́ kí wọ́n lè gba ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n fún wọn lọ́nà ìfẹ́.—Ják. 1:15; Sm. 141:5; Héb. 12:5, 6.

PINNU LÁTI JẸ́ ONÍWÀ MÍMỌ́

18. Kí lo ti pinnu láti ṣe?

18 Bí ìwà rere ṣe ń jó rẹ̀yìn nínú ayé Sátánì yìí, inú Jèhófà máa ń dùn tó bá rí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòtọ́ tí wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti ní èrò tó tọ́, tí wọ́n sì ń pa ìlànà ìwà rere Jèhófà mọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa pinnu láti sún mọ́ Jèhófà ká sì gba ìmọ̀ràn tó ń fún wa nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìjọ Kristẹni. Tá a bá jẹ́ oníwà mímọ́, èyí á jẹ́ ká ní ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn nísinsìnyí. (Sm. 119:5, 6) Lọ́jọ́ iwájú, nígbà tí Ọlọ́run bá mú Sátánì kúrò, a máa ní àǹfààní láti máa gbé títí láé nínú ayé kan tó bọ́ lọ́wọ́ ìwà ìbàjẹ́ Sátánì.