Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà—Olùpèsè àti Aláàbò Wa

Jèhófà—Olùpèsè àti Aláàbò Wa

“Nítorí pé òun darí ìfẹ́ni rẹ̀ sí mi, èmi pẹ̀lú yóò pèsè àsálà fún un. Èmi yóò dáàbò bò ó nítorí pé ó ti wá mọ orúkọ mi.”—SM. 91:14.

1, 2. Báwo ni ipò tẹ̀mí wa àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe yàtọ̀ síra?

JÈHÓFÀ ló dá ètò ìdílé sílẹ̀. (Éfé. 3:14, 15) Síbẹ̀, tá a bá tiẹ̀ wá látinú ìdílé kan náà, ìwà wa àti ipò tó yí wa ká máa ń yàtọ̀ síra. Ó lè jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ lo gbé dàgbà. Ó sì ṣeé ṣe kí òbí àwọn míì ti kú nítorí àìsàn, jàǹbá tàbí àwọn àjálù míì. Àwọn míì sì wà tí wọn ò tiẹ̀ mọ àwọn òbí wọn rárá.

2 Ipò tẹ̀mí gbogbo àwa tá a jùmọ̀ ń sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan tún yàtọ̀ síra. Bí àwọn kan ṣe máa ń sọ, ó lè jẹ́ pé ‘inú òtítọ́ ni wọ́n bí ẹ sí,’ tí àwọn òbí rẹ sì kọ́ ẹ láwọn ìlànà Ọlọ́run. (Diu. 6:6, 7) O sì lè wà lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà míì wàásù fún tí wọ́n sì kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.—Róòmù 10:13-15; 1 Tím. 2:3, 4.

3. Kí ni gbogbo wa ń jìyà rẹ̀, àǹfààní wo la sì jọ ní?

3 Yàtọ̀ sí àwọn nǹkan tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu kàn yìí, ohun kan wà tí gbogbo wa ń jìyà rẹ̀, àǹfààní kan sì wà tí kò yọ ẹnikẹ́ni nínú wa sílẹ̀. A jọ ń jìyà àbájáde àìgbọràn Ádámù a sì ti jogún àìpé, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 5:12) Síbẹ̀, nítorí pé à ń fòótọ́ sin Ọlọ́run, ó bá a mu tá a bá pe Jèhófà ní “Baba wa.” Nígbà tí ìwé Aísáyà 64:8 ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tó jẹ́ àyànfẹ́ Ọlọ́run nígbà àtijọ́, ó sọ pé: “Jèhófà, ìwọ ni Baba wa.” Síwájú sí i, nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ àdúrà àwòkọ́ṣe tó gbà, ó sọ pé: “Baba wa tí ń bẹ ní  ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.”—Mát. 6:9.

4, 5. Tá a bá ń ronú lórí bí ìmọrírì tá a ní fún Baba wa, Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó, kí ló máa dára ká gbé yẹ̀ wò?

4 Torí pé ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Baba wa ọ̀run ń mú ká ké pe orúkọ rẹ̀, ó máa ń tọ́jú wa ó sì máa ń dáàbò bò wá lápapọ̀. Onísáàmù náà fa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yọ níbi tó ti sọ pé: “Nítorí pé [olùjọsìn tòótọ́] darí ìfẹ́ni rẹ̀ sí mi, èmi pẹ̀lú yóò pèsè àsálà fún un. Èmi yóò dáàbò bò ó nítorí pé ó ti wá mọ orúkọ mi.” (Sm. 91:14) Ó dájú pé ìfẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ní sí àwa èèyàn rẹ̀ lápapọ̀ máa ń mú kó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ó sì máa ń dáàbò bò wá kí wọ́n má bàa pa wá rẹ́.

5 Ká bàa lè túbọ̀ mọrírì Baba wa ọ̀run, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó pàtàkì mẹ́ta kan yẹ̀ wò: (1) Olùpèsè ni Baba wa. (2) Jèhófà ni Aláàbò wa. (3) Ọlọ́run ni Ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́. Bá a ṣe ń gbé àwọn kókó yìí yẹ̀ wò, ó máa dára ká ṣàṣàrò lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run ká sì fòye mọ bá a ṣe lè máa bọlá fún un gẹ́gẹ́ bíi Baba wa. Ó tún máa ṣe wá láǹfààní tá a bá ronú lórí bí Jèhófà ṣe máa bù kún àwọn tó bá sún mọ́ ọn.—Ják. 4:8.

JÈHÓFÀ OLÙPÈSÈ TÍTÓBILỌ́LÁ

6. Kí ni ọ̀kan lára ọ̀nà tí Jèhófà gbà fi hàn pé òun ni Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere”?

6 Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè, nítorí a máa sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá.” (Ják. 1:17) Ẹ̀bùn àgbàyanu látọ̀dọ̀ Jèhófà ló jẹ́ pé a tiẹ̀ wà láàyè. (Sm. 36:9) Tá a bá ń fi ìgbésí ayé wa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ó máa bù kún wa lọ́pọ̀ yanturu nísinsìnyí, a ó sì ní ìrètí àtiwà láàyé títí láé nínú ayé tuntun. (Òwe 10:22; 2 Pét. 3:13) Àmọ́, báwo lèyí ṣe lè ṣeé ṣe níwọ̀n bá a ti ń jìyà àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù?

7. Kí ni Ọlọ́run ṣe ká lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀?

7 Dájúdájú, àìmọye ọ̀nà ni Jèhófà gbà jẹ́ Olùpèsè Títóbilọ́lá. Bí àpẹẹrẹ, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ máa ń mú kó dá wa nídè. Òótọ́ ni pé gbogbo wa la ti dẹ́ṣẹ̀ tá a sì ti jogún àìpé látọ̀dọ̀ Ádámù, baba wa àkọ́kọ́. (Róòmù 3:23) Síbẹ̀, nítorí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa, ó lo ìdánúṣe láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa ká lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀. Ìfẹ́ náà jẹ́ lọ́nà yìí, kì í ṣe pé àwa ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, bí kò ṣe pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”—1 Jòh. 4:9, 10.

8, 9. Báwo ni Jèhófà ṣe fi han Ábúráhámù àti Ísákì pé òun jẹ́ Olùpèsè Atóbilọ́lá? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

8 Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé tó dà bí àsọtẹ́lẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló jẹ́ ká mọ ohun tó ná Jèhófà láti fìfẹ́ pèsè ohun táá mú kí aráyé onígbọràn jogún ìyè àìnípẹ̀kun. Ìwé Hébérù 11:17-19 ṣàlàyé pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù, nígbà tí a dán an wò, kí a kúkú sọ pé ó ti fi Ísákì rúbọ tán, ọkùnrin tí ó sì ti fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gba àwọn ìlérí gbìdánwò láti fi ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo rúbọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti wí fún un pé: ‘Ohun tí a ó pè ní irú-ọmọ rẹ yóò jẹ́ nípasẹ̀ Ísákì.’ Ṣùgbọ́n ó ṣírò pé Ọlọ́run lè gbé e dìde, àní kúrò nínú òkú; láti ibẹ̀, ó sì tún rí i gbà lọ́nà àpèjúwe.” Kò ṣòro láti rí bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe bá Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ mu. Jèhófà fi Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi rúbọ nítorí aráyé.—Ka Jòhánù 3:16, 36.

9 Ẹ wo bí inú Ísákì á ṣe dùn tó nígbà tí Ọlọ́run gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú ìrúbọ tí ì bá kú! Láìsí àní-àní, inú rẹ̀ dùn pé Ọlọ́run pèsè ohun mìíràn tí wọ́n fi rúbọ dípò òun, ìyẹn ni àgbò kan tí ìwo rẹ̀ kọ́ igi. (Jẹ́n. 22:10-13) Abájọ tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní “Jèhófá-jirè,” tó túmọ̀ sí “Jèhófà Yóò Pèsè.”—Jẹ́n. 22:14, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.

 OHUN TÍ ỌLỌ́RUN ṢE KÁ LÈ PADÀ BÁ A RẸ́

10, 11. Àwọn wo ló múpò iwájú nínú “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́”? Ọ̀nà wo ni wọ́n gbà ṣe bẹ́ẹ̀?

10 Bá a ṣe ń ronú lórí ọ̀nà tí Jèhófà gbà fi hàn pé òun jẹ́ Olùpèsè Atóbilọ́lá yìí, bẹ́ẹ̀ là ń mọyì ipa pàtàkì tí Jésù Kristi kó, a sì kún fún ọpẹ́ bíi ti Pọ́ọ̀lù, ẹni tó kọ̀wé pé: “Nítorí èyí ni ohun tí àwa ti ṣèdájọ́, pé ọkùnrin kan kú fún gbogbo ènìyàn; nítorí bẹ́ẹ̀, gbogbo wọ́n ti kú; ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.”—2 Kọ́r. 5:14, 15.

11 Nítorí pé àwọn Kristẹni ìgbàanì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì mọyì àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ tí wọ́n ní láti máa sìn ín, wọ́n fayọ̀ tẹ́wọ́ gba “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́” náà. Iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n ṣe ló mú kí àwọn olóòótọ́ ọkàn lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run, òun ló mú kí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, tó sì mú kí wọ́n di ọmọ tẹ̀mí fún Ọlọ́run lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Lóde òní, irú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí kan náà làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tá a fẹ̀mí yàn ń ṣe. Ohun tí wọ́n ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ Ọlọ́run àti ti Kristi ló ń mú kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ wá sọ́dọ̀ Jèhófà tí wọ́n sì ń di onígbàgbọ́.—Ka 2 Kọ́ríńtì 5:18-20; Jòh. 6:44; Ìṣe 13:48.

12, 13. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì ọ̀pọ̀ nǹkan tí Jèhófà ń fún wa?

12 Gbogbo àwọn Kristẹni tó ní ìrètí àtimáa gbé lórí ilẹ̀ ayé mọrírì bí Jèhófà ṣe jẹ́ Olùpèsè Atóbilọ́lá, èyí sì ń mú kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Tá a bá wà lóde ẹ̀rí, a máa ń lo Bíbélì tó jẹ́ òmíràn lára àwọn ohun títayọ tí Ọlọ́run fún wa. (2 Tím. 3:16, 17) Bá a ṣe ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí yìí lóde ẹ̀rí, à ń mú kí àwọn èèyàn ní àǹfààní láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun. Ohun míì tún wà tí Jèhófà fi ń ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù yìí, ohun náà ni ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Sek. 4:6; Lúùkù 11:13) Ohun tí ẹ̀mí mímọ́ yìí ń mú ká ṣàṣeyọrí rẹ̀ wúni lórí gan-an bá a ṣe ń rí i nínú Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ ò rí i pé ọlá ńlá la ní pé à ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí sí ìyìn Ọlọ́run tó jẹ́ Olùpèsè àti Baba wa!

13 Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run ti fún wa yìí, ó dára kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Ǹjẹ́ mò ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi kí Jèhófà lè rí i pé mo mọrírì àwọn ohun tó fún wa? Àwọn ọ̀nà wo ni mo lè gbà sunwọ̀n sí i kí n lè túbọ̀ jáfáfá bí mo ṣe ń wàásù ìhìn rere?’ A lè fi hàn pé a mọyì àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run fún wa nípa fífi àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba rẹ̀ sí ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa rí sí i pé ọwọ́ wa tẹ àwọn nǹkan tá a ṣaláìní. (Mát. 6:25-33) Nítorí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa, ó dájú pé àwa náà máa sa gbogbo ipá wa ká lè máa ṣe ohun tó fẹ́ ká sì mú ọkàn rẹ̀ yọ̀.—Òwe 27:11.

14. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ Olùpèsè àsálà fáwọn èèyàn rẹ̀?

14 Onísáàmù náà, Dáfídì sọ pé: “Ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ àti òtòṣì ni mí. Jèhófà tìkára rẹ̀ ń gba tèmi rò. Ìwọ ni ìrànwọ́ mi àti Olùpèsè àsálà fún mi.” (Sm. 40:17) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà ti jẹ́ Olùpèsè àsálà fún àwọn èèyàn rẹ̀ lápapọ̀, pàápàá jù lọ nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá ń ṣe inúnibíni sí wọn lọ́nà rírorò tí wọ́n sì ń dọdẹ wọn ṣáá. A mà dúpẹ́ o pé Ọlọ́run ń ràn wá lọ́wọ́ nírú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀ tó sì tún ń fún wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan tá á jẹ́ ká lè máa gbádùn àjọṣe tó dára pẹ̀lú rẹ̀ déédéé!

JÈHÓFÀ Ń DÁÀBÒ BÒ WÁ

15. Ṣàpèjúwe bí bàbá onífẹ̀ẹ́ kan ṣe máa ń dáàbò bo ọmọ rẹ̀.

15 Yàtọ̀ sí pé bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ máa ń fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ohun tí wọ́n nílò, ó tún máa ń dáàbò bò wọ́n. Ó dájú pé bí  wọ́n bá wà nínú ewu, ó máa sapá láti yọ wọ́n. Arákùnrin kan rántí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtó kan tó wáyé nígbà tó ṣì wà lọ́mọdé. Ó ṣẹlẹ̀ pé òun àti bàbá rẹ̀ ń ti òde ẹ̀rí bọ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n ní láti gba ibi odò kan kọjá. Òjò ńlá kan tó rọ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ yẹn ti mú kí odò náà kún àkúnya. Wọn ò sì lè sọdá odò náà àyàfi tí wọ́n bá ń bẹ́ láti orí òkúta ńlá kan sí òmíì. Ọ̀dọ́mọdé yìí ń lọ níwájú, baba rẹ̀ sì ń tẹ̀ lé e. Ṣàdédé ni ẹsẹ̀ rẹ̀ yẹ̀ kúrò lórí ọ̀kan lára àwọn òkúta náà, ó ṣubú sínú omi tó kún àkúnya náà, ó sì rì sómi lẹ́ẹ̀mejì. Kíá ni bàbá rẹ̀ di èjìká rẹ̀ mú ṣinṣin, kò má bàa kú sínú omi náà. Ẹ wo bí inú ọmọ náà á ṣe dùn tó! Baba wa ọ̀run náà máa ń gbà wá lọ́wọ́ ohun tó dà bí ọ̀gbàrá tí ń ya mùúmùú nínú ayé búburú yìí àti lọ́wọ́ Sátánì tó ń darí rẹ̀. Ó dájú pé kò sí ẹni tá a lè retí pé kó dáàbò bò wá bíi Jèhófà, Òun ni Aláàbò tó dára jù lọ láyé àti lọ́run.—Mát. 6:13; 1 Jòh. 5:19.

16, 17. Báwo ni Jèhófà ṣe ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ tó sì tún dáàbò bò wọ́n nígbà tí wọ́n bá àwọn ọmọ Ámálékì jà?

16 A lè rí àpẹẹrẹ tó dára nípa bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ dáàbò boni nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò lóko ẹrú nílẹ̀ Íjíbítì tó sì dáàbò bò wọ́n lọ́nà ìyanu nígbà tí wọ́n ń la Òkun Pupa kọjá lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Lẹ́yìn tí orílẹ̀-èdè náà ti rìn gba ibi Òkè Sínáì kọjá, wọ́n gúnlẹ̀ sí Réfídímù.

17 Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15, ó ṣeé ṣe kí Sátánì ti máa wá gbogbo ọ̀nà táá fi gbógun ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó rọrùn láti kọ lù yìí. Ó lo àwọn ọmọ Ámálékì tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Núm. 24:20) Tún ronú lórí ohun tí Jèhófà gbé ṣe nípasẹ̀ Jóṣúà, Mósè, Áárónì àti Húrì, àwọn ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin. Nígbà tí Jóṣúà ń bá àwọn ọmọ Ámálékì jà, Mósè, Áárónì àti Húrì  wà lórí òkè kan nítòsí ibẹ̀. Nígbà tí Mósè bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á máa ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn. Nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ wúwo, Áárónì àti Húrì kún un lọ́wọ́. Bí ọ̀ràn ṣe rí nìyẹn tó fi jẹ́ pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àti ààbò Jèhófà, “Jóṣúà fi ojú idà rẹ́yìn Ámálékì àti àwọn ènìyàn rẹ̀.” (Ẹ́kís. 17:8-13) Mósè mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pè é ní “Jèhófà-nisì,” èyí tó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Òpó Àmì Àfiyèsí Mi.”—Ka Ẹ́kísódù 17:14, 15, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.

ỌLỌ́RUN Ń GBÀ WÁ LỌ́WỌ́ SÁTÁNÌ

18, 19. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àkókò wa?

18 Jèhófà máa ń dáàbò bo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i. Bíi ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Réfídímù, ojú Ọlọ́run là ń wò pé kó ràn wá lọ́wọ́ tí àwọn ọ̀tá bá dojú kọ wá. Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáàbò bò wá lápapọ̀, ó sì máa ń gbà wá lọ́wọ́ Èṣù. Ronú nípa ọ̀pọ̀ ìgbà tí Ọlọ́run ti dáàbò bo àwọn ará wa tí wọ́n ò dá sí ogun tàbí ọ̀ràn ìṣèlú. Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún 1930 sí nǹkan bí ọdún 1945, Jèhófà dáàbò bo àwọn ará wa lásìkò ìjọba Násì lórílẹ̀-èdè Jámánì àti láwọn orílẹ̀-èdè míì. Tá a bá ń ka ìtàn ìgbésí ayé àwọn ará wa nínú àwọn ìwé ìròyìn àti Ìwé Ọdọọdún wa, tá a sì ń ronú lórí bí Ọlọ́run ṣe dáàbò bò wọ́n nígbà inúnibíni, ó maá mú ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó jẹ́ Ibi Ààbò wa.—Sm. 91:2.

Jèhófà lè lo àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ adúróṣinṣin nígbà ìṣòro (Wo ìpínrọ̀ 18 sí 20)

19 Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ń mú kó fún wa ní àwọn ìránnilétí tó ń dáàbò bò wá, ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ ètò rẹ̀ àtàwọn ìtẹ̀jáde. Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn ìránnilétí bẹ́ẹ̀ ti ṣe wá láǹfààní lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Bí ìwà ìṣekúṣe àti wíwo àwòrán oníhòòhò ṣe túbọ̀ ń wọ aráyé lẹ́wù, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń rán wa létí ewu tó wà nínú irú àwọn ìwàkiwà bẹ́ẹ̀, ó sì ń fún wa ní ìrànlọ́wọ́ tó wúlò. Bí àpẹẹrẹ, baba wa ọ̀run ń gbà wá nímọ̀ràn pé ká yẹra fún ẹgbẹ́ búburú téèyàn lè kó tó bá ń ṣi ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ́tì lò. *1 Kọ́r. 15:33.

20. Ààbò àti ìtọ́sọ́nà wo là ń rí gbà nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni?

20 Báwo la ṣe lè fi hàn pé òótọ́ là ń ‘kọ́ wa láti ọ̀dọ̀ Jèhófà?’ Bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa fetí sí àṣẹ Ọlọ́run. (Aísá. 54:13) A máa ń rí ìtọ́sọ́nà àti ààbò tá a nílò gbà nínú àwọn ìjọ wa tó jẹ́ ibi ààbò, torí pé ibẹ̀ ni àwọn ọkùnrin adúróṣinṣin tí wọ́n ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà ti ń fún wa ní ìrànlọ́wọ́ àti ìmọ̀ràn tá a nílò látinú Ìwé Mímọ́. (Gál. 6:1) “Àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” yìí ni Jèhófà máa ń lò lọ́pọ̀ ìgbà láti bójú tó wa lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. (Éfé. 4:7, 8) Kí wá ló yẹ ká ṣe? Ńṣe ló yẹ ká máa tẹrí ba látọkànwá, ká sì máa ṣègbọràn. A ó sì rí ìbùkún Ọlọ́run gbà.—Héb. 13:17.

21. (a) Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

21 Ẹ jẹ́ ká pinnu pé a óò jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí wa, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Baba wa ọ̀run. Ó tún yẹ ká máa ṣàṣàrò lórí bí Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run ṣe gbé ìgbé ayé rẹ̀, torí pé àpẹẹrẹ aláìlẹ́gbẹ́ tó fi lélẹ̀ là ń tẹ̀ lé. Jésù rí èrè ńlá gbà torí pé ó ṣègbọràn títí dójú ikú. (Fílí. 2:5-11) Bíi tirẹ̀, àwa náà máa rí ìbùkún gbà torí pé a fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kè lé Jèhófà. (Òwe 3:5, 6) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fìgbà gbogbo yíjú sí Jèhófà tó jẹ́ Olùpèsè àti Aláàbò wa tí kò lẹ́gbẹ́. Ohun ayọ̀ àti àǹfààní ńláǹlà ló jẹ́ pé à ń sìn ín! Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run á máa pọ̀ sí i bá a ṣe ń ronú lórí ọ̀nà kẹta tí Baba wa ń gbà bójú tó wa, ìyẹn bó ṣe jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́. Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jíròrò bí Jèhófà ṣe jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́.

^ ìpínrọ̀ 19 A lè rí irú àwọn ìránnilétí bẹ́ẹ̀ nínú àwọn àpilẹ̀kọ bíi, “Fi Ọgbọ́n Lo Íńtánẹ́ẹ̀tì” nínú Ilé Ìṣọ́, August 15, 2011, ojú ìwé 3 sí 5 àti “Ṣọ́ra fún Àwọn Ìdẹkùn Èṣù!” àti “Ẹ Dúró Gbọn-in Kẹ́ Ẹ sì Sá fún Àwọn Ohun Tí Sátánì Fi Ń Múni!” nínú Ilé Ìṣọ́, August 15, 2012, ojú ìwé 20 sí 29.