ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́

Òun Náà Ni!

Yorùbá
Òun Náà Ni!
/assets/ct/28ada02fb0/images/syn_placeholder_sqr.png
w12 1/15 ojú ìwé 3
Òun Náà Ni!

Òun Náà Ni!

Bí ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ṣe rí báyìí ti yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀, kó lè túbọ̀ fà ẹ́ mọ́ra kó sì lè mú kó o túbọ̀ gbádùn kíkẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Jèhófà.—Sm. 1:2; 119:97.

Ó ti pé ọdún mẹ́rin báyìí tá a ti bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ọ̀kan jẹ́ ẹ̀dà tá à ń fi sóde, ìkejì sì wà fún gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ wọn.

Arákùnrin kan tó ti ń sin Jèhófà látọjọ́ pípẹ́ sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tó ka ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àkọ́kọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́, ó ní: “Nígbà tí mo kà á, mo rí i pé ó ti lọ wà jù, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì wọ̀ mí lọ́kàn. Bí ìwé ìròyìn náà ṣe ṣàlàyé kínníkínní nípa àwọn òtítọ́ iyebíye tó wà nínú Bíbélì wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni. Ẹ ṣeun lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ìpèsè àgbàyanu yìí.” Arákùnrin mìíràn kọ̀wé pé: “Ńṣe ni mo máa ń fojú sọ́nà fún lílo àkókò tó pọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí, mo sì tún máa ń lo Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.” A lérò pé ojú tí ìwọ náà fi wò ó nìyẹn.

Gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe mọ̀, látọdún 1879 la ti ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, ẹ̀mí Jèhófà àti ìbùkún rẹ̀ nìkan ló sì lè mú kí irú iṣẹ́ ńlá bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe. (Sek. 4:6) A ti yí èèpo ẹ̀yìn ìwé ìròyìn náà pa dà ní ìgbà mélòó kan láàárín ọdún mẹ́tàléláàádóje [133] tá a ti ń tẹ̀ ẹ́ jáde. Lọ́dún 2012, a ó máa fọwọ́ ya àwòrán ibi tí ẹnì kan ti ń jẹ́rìí sára èèpo ẹ̀yìn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ kọ̀ọ̀kan tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Àwòrán aláwọ̀ mèremère yìí á máa rán wa létí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ pé ká máa jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Jèhófà. (Ìṣe 28:23) Ní ojú ìwé kejì, ẹ máa rí fọ́tò tá a ya àwòrán rẹ̀ sí ẹ̀yìn ìwé ìròyìn náà, ẹ ó sì rí àlàyé ṣókí tó sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àwòrán náà àti ibi tó ti ṣẹlẹ̀. Látìgbà yìí lọ, èyí a máa rán gbogbo wa létí pé àwọn èèyàn Jèhófà ń wàásù ìhìn rere “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.”—Mát. 24:14.

Àwọn ohun mìíràn wo ló tún yí pa dà nínú ìwé ìròyìn náà? A ti gbé àpótí àtúnyẹ̀wò wá sí ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ kọ̀ọ̀kan tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Èyí á jẹ́ kó o rí àwọn kókó pàtàkì tó yẹ kó o fi sọ́kàn tó o bá ń ka àpilẹ̀kọ náà tàbí tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ á máa lo àwọn ìbéèrè wọ̀nyí láti ṣe àtúnyẹ̀wò àpilẹ̀kọ náà lẹ́yìn tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ bá ti parí. Ẹ óò kíyè sí i pé àlàfo etí ìwé ìròyìn náà ti fẹ̀ sí i, àwọn nọ́ńbà ojú ìwé àti ti ìpínrọ̀ sì túbọ̀ hàn ketekete.

Gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣàlàyé rẹ̀ nínú ẹ̀dà tó wà lọ́wọ́ yín yìí, a ti fi apá tuntun kan kún àwọn àpilẹ̀kọ tí ìwé ìròyìn yìí yóò máa gbé jáde, èyí tí a pè ní “Látinú Àpamọ́ Wa.” A ó máa fi àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì nínú ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní. Nínú àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú,” a ó máa gbé ìrírí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará jáde lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àpilẹ̀kọ náà á máa ṣe àlàyé tó ṣe kedere nípa ìdùnnú, ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ táwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní nígbà tí wọ́n lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i.

A nírètí pé wàá túbọ̀ máa gbádùn àkókò tó o fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bó o ṣe ń lo ìwé ìròyìn yìí.

Àwa Òǹṣèwé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

1879

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

1895

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

1931

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

1950

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

1974

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

2008