ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́

Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

Yorùbá
Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
/assets/ct/fa815d8e9f/images/syn_placeholder_sqr.png
w08 8/15 ojú ìwé 1-2
Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

August 15, 2008

Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:

September 29–October 5

Jèhófà Kì Yóò Fi Àwọn Ẹni Ìdúróṣinṣin Rẹ̀ Sílẹ̀

OJÚ ÌWÉ 3

ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 114, 223

October 6-12

Máa Bá A Nìṣó Láti Jẹ́ Adúróṣinṣin Pẹ̀lú Ọkàn Tó Ṣọ̀kan

OJÚ ÌWÉ 7

ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 38, 8

October 13-19

Máa Ṣe Ohun Tó Ń Gbé Iyì Jèhófà Yọ

OJÚ ÌWÉ 12

ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 48, 136

October 20-26

Jèhófà Ń Ṣìkẹ́ Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Àgbàlagbà

OJÚ ÌWÉ 17

ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 58, 216

October 27–November 2

Ǹjẹ́ Ò Ń Sọ “Èdè Mímọ́” Lọ́nà Tó Já Geere?

OJÚ ÌWÉ 21

ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 78, 169

Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá a Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé

Àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ 1 àti 2 OJÚ ÌWÉ 3 sí 11

Àpilẹ̀kọ yìí fi hàn pé Jèhófà kò fàwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pín sí abẹ́ ìjọba méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ti àríwá àti gúúsù. Àpilẹ̀kọ yìí tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ adúróṣinṣin látọkànwá nísinsìnyí ká má bàa ṣubú sínú ìdẹkùn ìfẹ́ ọrọ̀ tàbí híhùwà ọ̀yájú.

Àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ 3 OJÚ ÌWÉ 12 sí 16

Àpilẹ̀kọ yìí sọ bó ṣe yẹ ká máa ṣe torí bá a ṣe mọyì ògo Ọlọ́run. Ó ṣàlàyé ẹ̀kọ́ tá a máa kọ́ nípa bíbuyì kúnni nínú ọ̀nà tí Jésù gbà hùwà sáwọn èèyàn. Wàá tún kọ́ nípa bá a ṣe lè hùwà tó buyì kúnni.

Àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ 4 OJÚ ÌWÉ 17 sí 21

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè máa wo àwọn Kristẹni tó jẹ́ àgbàlagbà gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n. Ṣàkíyèsí bí Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ bó ṣe yẹ ká bọ̀wọ̀ fún wọn nítorí ìmọ̀ àti ìrírí wọn, ká máa kíyè sí bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wọn, ká sì máa tì wọ́n lẹ́yìn kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ ìsìn wọn lọ.

Àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ 5 OJÚ ÌWÉ 21 sí 25

Jèhófà sọ nípasẹ̀ Sefanáyà wòlíì rẹ̀ pé: “Èmi yóò fún àwọn ènìyàn ní ìyípadà sí èdè mímọ́.” (Sef. 3:9) Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó ń jẹ́ “èdè mímọ́.” Wo àwọn ohun tó o lè ṣe kó o bàa lè mọ̀ ọ́n sọ dáadáa. Kó o sì wá rí bó o ṣe lè máa lo èdè tí ò láfiwé yìí láti fi yin Jèhófà.

ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ:

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Gálátíà, Éfésù, Fílípì àti Kólósè

OJÚ ÌWÉ 26

Ǹjẹ́ O Rántí?

OJÚ ÌWÉ 29

Àwọn Míṣọ́nnárì Dà Bí Eéṣú

OJÚ ÌWÉ 30