Ojú Ìwòye Bíbélì
Dídé Lásìkò
Gbogbo èèyàn ló gbà pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa tètè débi tó ń lọ, kódà àwọn tó máa ń pẹ́ lẹ́yìn náà gbà bẹ́ẹ̀. Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó mọ́gbọ́n dání lórí ọ̀rọ̀ yìí.
Báwo ni dídé lásìkò ti ṣe pàtàkì tó?
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ
Ọ̀pọ̀ èèyàn ti rí i pé téèyàn bá tètè dé ibi tó ń lọ, ara rẹ̀ á balẹ̀. Àwọn èèyàn á sì máa sọ̀rọ̀ ẹni náà dáadáa. Lọ́nà wo?
Dídé lásìkò fi han pé o mọ ohun tó ò ń ṣe. Tí o kì í bá pẹ́ lẹ́yìn, èyí fi hàn pé ìwọ lò ń pinnu ohun tó o fẹ́ fi àkókò rẹ ṣe, dípò tí wàá fi jẹ́ kí ipò tó yí ẹ ká dí ẹ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe.
Dídé lásìkò fi han pé o ṣeé gbára lé. Ọ̀pọ̀ èèyàn kì í ka àdéhùn tí wọ́n bá ṣe sí tàbí kí wọ́n má ṣe mú ìlérí wọn ṣẹ. Àmọ́, táwọn èèyàn bá wá rí ẹni tó máa ń dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n máa ń mọyì irú ẹni bẹ́ẹ̀ gan-an. Tẹbí tọ̀rẹ́ ló máa ń bọ̀wọ̀ fún ẹni tó bá ṣeé gbára lé. Àwọn agbanisíṣẹ́ máa ń mọyì òṣìṣẹ́ tó ń dé ibiṣẹ́ lásìkò, tó sì ń parí iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un lásìkò. Wọ́n lè fi kún owó oṣù rẹ̀, tàbí kí wọ́n fọkàn tán an pátápátá.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Àwọn ẹsẹ Bíbélì wà tó ní ín ṣe pẹ̀lú dídé lásìkò. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.” (1 Kọ́ríńtì 14:40) Tí àwọn méjì bá ṣàdéhùn láti pàdé lákòókò kan pàtó, ohun tó dáa jù ni pé kí wọ́n débẹ̀ lásìkò. Ẹsẹ Bíbélì míì tún sọ pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, àní ìgbà fún gbogbo àlámọ̀rí lábẹ́ ọ̀run.” (Oníwàásù 3:1) Ẹsẹ tó tẹ̀ lé e sọ pé “ìgbà gbígbìn àti ìgbà fífa ohun tí a gbìn tu” wà. (Oníwàásù 3:2) Táwọn àgbẹ̀ bá gbin nǹkan lásìkò tó yẹ, irè oko wọn máa jáde dáadáa. Lédè míì, a lè sọ pé èrè tó dáa ló máa yọrí sí fún àgbẹ̀ tó bá ṣe nǹkan lásìkò.
Bíbélì tún jẹ́ ká mọ ìdí pàtàkì míì tó fi yẹ ká máa dé lásìkò: Ó fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún àwọn míì, a ò sì fẹ́ fàkókò wọn ṣòfò. (Fílípì 2:
“Kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.”
—Fílípì 2:4.
Kí lo lè ṣe kó o lè máa dé lásìkò?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa ṣètò ohun tá a bá fẹ́ ṣe ṣáájú. (Òwe 21:5) Tó o bá rí i pé o sábà máa ń pẹ́ lẹ́yìn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ohun tí ò ń ṣe ti pọ̀ jù ló fà á. Ṣé o lè yọ àwọn nǹkan tí kò pọn dandan tó máa ń gba àkókò rẹ? Tó o bá fẹ́ dá àkókò fún ẹnì kan, rí i pé o fi àyè tó pọ̀ tó sílẹ̀, kí o sì ní in lọ́kàn pé wàá débẹ̀ ṣáájú àkókò tẹ́ ẹ ṣàdéhùn. Èyí máa fàyè sílẹ̀ fún ìdílọ́wọ́ tó bá wáyé láìrò tẹ́lẹ̀, irú bíi sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀ tà bí ojú ọjọ́ tí kò dáa.
Bíbélì tún gbà wá níyànjú pé ká jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà. (Òwe 11:2) Èyí gba pé ká mọ ìwọ̀n ohun tá a lè ṣe. Ríi dájú pé o máa rọrùn fún ẹ láti mú àdéhùn tó o bá ṣe ṣẹ, kó o tó ṣàdéhùn. Tó o bá ń gbà láti ṣe ohun tó pọ̀ ju agbára rẹ lọ, ńṣe ni wàá máa dá kún àníyàn àti ìnira rẹ àtàwọn ẹlòmíì!
Bíbélì tún sọ pé ká máa lo àkókò wa dáadáa. (Éfésù 5:
“Àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.”
—Òwe 21:5.