Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kókó Iwájú Ìwé

Bá A Ṣe Lè Dènà Àrùn

Bá A Ṣe Lè Dènà Àrùn

Ojoojúmọ́ ni àgọ́ ara wa ń wọ̀yá ìjà pẹ̀lú àwọn kòkòrò àrùn tá ò lè rí. Lára wọn ni kòkòrò bakitéríà, fáírọ́ọ̀sì àti kòkòrò parasite tí wọ́n dà bíi májèlé tó lè ṣàkóbá fún ìlera wa. * A kì í mọ̀ tí àwọn nǹkan yìí bá ń ṣẹlẹ̀ nínú ara wa, torí pé kí àwọn májèlé yìí tó dá àìsàn sí wa lára ni àwọn ohun tó ń gbógun ti àrùn á ti mú wọn kúrò. Àmọ́ nígbà míì, àwọn májèlé yìí lè lágbára ju ara wa lọ kí wọ́n sì dá àìsàn sí wa lára. Àwọn oògùn tá a bá lò ló máa ń jẹ́ kí ara tún pa dà bọ̀ sípò.

Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, àwọn èèyàn ò mọ nǹkan kan nípa ewu tí àwọn kòkòrò àrùn tíntìntín lè fà. Nígbà tó yá, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó gbáyé láwọn ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún wá jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn kòkòrò yìí máa ń fa àrùn, wọ́n sì jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè dáàbò bo ara wa. Látìgbà náà wá, àwọn olùwádìí nínú ìmọ̀ ìṣègùn ti sapá gidigidi láti dín àwọn àrùn tó ń gbèèràn kù; bí ìgbóná àti àrùn rọpárọsẹ̀. Àìpẹ́ yìí ni àwọn àrùn bí ibà pọ́njú àti ibà dengue, tún bẹ̀rẹ̀ sí í jà. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká gbé àwọn kókó yìí yẹ̀ wò:

  • Bí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ṣe ń rìnrìn àjò kárí ayé lọ́dọọdún, láìmọ̀, wọ́n lè fara gbé àwọn ohun tó lè fa àìsàn bá ẹlòmíì láti orílẹ̀-èdè kan sí orílẹ̀-èdè míì. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Clinical Infectious Diseases sọ pé: “Ìrìn àjò ayára bí àṣá táwọn èèyàn ń rìn kárí ayé wà lára ohun tó jẹ́ kí àwọn kòkòrò tó ń fa àrùn gbèèràn.”

  • Àwọn kòkòrò bakitéríà kan kò gbóògùn apakòkòrò mọ́. Kódà, Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé: “Ibi tí ayé dé báyìí, ó jọ pé apá oògùn apakòkòrò kò lè ká àwọn àìsàn mọ́, ó di kí ẹ̀fọ́rí lásán máa lu àwọn èèyàn pa.”

  • Ìjà abẹ́lé àti ipò òṣì kì í jẹ́ kí ìjọba lè kápá àrùn kó má bàa gbèèràn.

  • Ọ̀pọ̀ èèyàn kò mọ bí wọ́n ṣe lè dènà àrùn.

Láìka bí nǹkan ṣe rí yìí, ọgbọ́n wà tó o lè dá sí i kí ìwọ àti ìdílé rẹ lè dènà àrùn. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e á jẹ́ kó o rí i pé ibi yòówù kó o máa gbé, àwọn nǹkan kéékèèké kan wà tó o lè ṣe láti dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àrùn.

^ ìpínrọ̀ 3 Kì í ṣe gbogbo kòkòrò àrùn tíntìntín ló máa ń dá àìsàn síni lára. Àmọ́ àwọn tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí lágbára láti ṣàkóbá fún ìlera wa.