JÍ! No. 6 2016 | Bá A Ṣe Lè Dènà Àrùn

Kéèyàn máa ṣàìsàn lóòrèkóòrè máa ń ṣàkóbá fún ìlera rẹ. Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà dènà rẹ̀?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Bá A Ṣe Lè Dènà Àrùn

Ojoojúmọ́ ni àgọ́ ara wa ń wọ̀yá ìjà pẹ̀lú àwọn kòkòrò àrùn tá ò lè rí.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Àrùn

Ọ̀nà márùn-ún tó o lè gbà kó àrùn, àti bó o ṣe lè dènà wọn.

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Ohun Àrà Kan Nípa Ìṣáwùrú Òkun

Ìṣáwùrú òkun máa ń lẹ̀ mọ́ nǹkan tímọ́tímọ́. Tá a bá mọ bó ṣe ń ṣe é, ó máa jẹ́ ká lè ṣe ohun tó ṣe lẹ nǹkan mọ́ ara ilé, tàbí lẹ iṣan àti eegun pọ̀.

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Bó O Ṣe Lè Fi Ọ̀wọ̀ Hàn

Fífi ọ̀wọ̀ hàn nínú ìgbéyàwó kì í ṣe ohun téèyàn ń ṣé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ohun téèyàn gbọ́dọ̀ máa ṣe nígbà gbogbo ni. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé ò ń bọ̀wọ̀ fún ẹnì kejì rẹ?

ÌTÀN ÀTIJỌ́

Desiderius Erasmus

Wọ́n ní “a lè fi wé àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká lóde òní.” Kí ló mú káwọn èèyàn mọ̀ ọ́n nílé lóko?

Ẹja Clown Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀

Ẹja kékeré yìí ní àwọ̀ mèremère, ó sì ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú òdòdó anemone. Kí ló mú kí àjọgbé wọn ṣàrà ọ̀tọ̀, àti pé báwo ló ṣe ṣeé ṣe?

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Dídé Lásìkò

Dídé lásìkò—tàbí pípẹ́ lẹ́yìn—máa ń sọ irú ẹni tá a jẹ́. Kí ni Bíbélì sọ nípa ànímọ́ tó dáa yìí? Báwo lo ṣe lè jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa tètè dé?

Atọ́ka Àwọn Àkòrí fún Jí! ! 2016

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn àkòrí àpilẹ̀kọ tá a tẹ̀ jáde lọ́dún 2016.

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Máa Wà ní Mímọ́ Tónítóní

Jèhófà ní ibi to máa ń tọ́jú àwọn nǹkan sí. Kọ́ bí o ṣe lè wà ní mímọ́ tónítóní!

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọdún Kérésìmesì?

Ó máa yà ọ́ lẹ́nu tó o bá ka ìtàn àwọn àṣà Kérésìmesì mẹ́fà táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa.