Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀​—Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Gbẹ̀mí Là

Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀​—Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Gbẹ̀mí Là

Ṣàdédé ni nǹkan kan bú gbàù, ilẹ̀ mì tìtì débi pé mo fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣubú. Ariwo ọ̀hún sì fẹ́rẹ̀ẹ́ di mí létí. Ọ́fíìsì wa bẹ̀rẹ̀ sí í jó, èéfín sì bo ibi gbogbo.” ​—Joshua.

Lọ́pọ̀ ìgbà tá a bá ka ìwé ìròyìn, àwọn nǹkan tá a sábà máa ń rí ni ìmìtìtì ilẹ̀ . . . ìjì líle . . . àwọn afẹ̀míṣòfò . . . ìpakúpa nílé ìwé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́ ọ̀tọ̀ ni ká gbọ́ nípa àjálù, ọ̀tọ̀ sì ni kí àjálù ṣẹlẹ̀ sí wa. Kí la lè ṣe láti múra sílẹ̀ kí àjálù tó ṣẹlẹ̀, tó bá ṣẹlẹ̀, kí la lè ṣe ká má bàa kó sínú ewu, kí la sì lè ṣe lẹ́yìn tó ti ṣẹlẹ̀?

KÓ TÓ ṢẸLẸ̀​—MÚRA SÍLẸ̀!

KÒ SÍ ẹni tí àjálù ò lè dé bá. Àmọ́ tó o bá ti múra sílẹ̀ dè é, ó ṣeé ṣe kó o là á já. Báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀?

 • Múra ọkàn rẹ sílẹ̀. Gbà pé àjálù máa ń ṣẹlẹ̀, ó sì lè kan ìwọ tàbí àwọn èèyàn rẹ. Tó o bá rò pé wàá ṣe nǹkan sí i lẹ́yìn tó bá ṣẹlẹ̀, ó lè má bá mọ́.

 • Mọ àwọn àjálù tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ní àgbègbè rẹ. Mọ àwọn ibi tó o lè sá sí. Ṣé ilé rẹ dúró nílẹ̀ dáadáa tí òrùlé rẹ̀ sì lágbára láti dáàbò bò ẹ́ nígbà àjálù? Kó àwọn nǹkan tó lè mú kí iná sọ kúrò nílẹ̀. Fi ẹ̀rọ tó máa ń tani lólobó tí èéfín bá ti ń rú sínú ilé rẹ, kó o sì máa pààrọ̀ bátìrì rẹ̀ látìgbàdégbà, ó kéré tán ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún.

 • Ṣètò àwọn nǹkan tó o lè lò ní pàjáwìrì. Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ó lè má sí iná, omi, fóònù tàbí ohun ìrìnnà. Tó o bá ní mọ́tò, rí i dájú pé epo tó pọ̀ tó wà nínú ẹ̀, kó o sì rí i pé oúnjẹ, omi àtàwọn ohun èlò pàjáwìrì wà nílé.​—Wo àpótí náà “ Ṣé O Ní Gbogbo Ohun Tó O Nílò?

  Ìmúrasílẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an torí pé ó lè gba ẹ̀mí rẹ là

 • Gba nọ́ńbà fóònù àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tó wà nítòsí àtàwọn tó wà lọ́nà jíjìn.

 • Ẹ ṣètò bẹ́ ẹ ṣe máa sá tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, kẹ́ ẹ sì fi dánra wò. Mọ àwọn ọ̀nà tó o lè gbà sá jáde nínú ilé àti ètò pàjáwìrì tí ilé ìwé àwọn ọmọ rẹ ṣe. Ṣètò ibi tí gbogbo yín ti máa pàdé, kí ọ̀kan jẹ́ ládùúgbò yín, kí ìkejì sì wà níbòmíì. Àwọn aláṣẹ dábàá pé kí ìwọ àti ìdílé rẹ fi bẹ́ ẹ ṣe máa dé ibẹ̀ dánra wò.

 • Ṣètò láti ran àwọn míì lọ́wọ́, tó fi mọ́ àwọn àgbàlagbà àtàwọn aláìlera.

TÓ BÁ ṢẸLẸ̀​—TÈTÈ GBÉ ÌGBÉSẸ̀

Joshua tó sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Nígbà tí iná yẹn kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fi nǹkan falẹ̀. Ìgbà yẹn làwọn kan ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ ń pa kọ̀ǹpútà wọn táwọn míì sì ń rọ omi sínú ike omi wọn. Ọkùnrin kan tiẹ̀ tún sọ pé ká ṣì ní sùúrù.” Bí àwọn èèyàn ṣe ń fi nǹkan falẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Joshua ń pariwo pé: “Ẹ jẹ́ ká tètè bọ́ síta o!” Àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ tara kìjí, wọ́n sì tẹ̀ lé e jáde. Bí wọ́n ṣe ń lọ ló ń pariwo pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá ṣubú, ẹ fà á dìde, ẹ fọkàn balẹ̀, gbogbo wa la máa yè é!”

 • Tí iná bá ń jó. Bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kó o sì yára sá jáde. Tí iná bá ń jó, ńṣe ni èéfín máa ń rú boni lójú kì í sì jẹ́ kéèyàn ríran, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ti kú nítorí pé wọ́n fa èéfín símú. Torí náà, má ṣe dúró mú nǹkan kan, ẹ̀mí ló jù. Ìjáfara léwu.

 • Nígbà ìmìtìtì ilẹ̀. Sá sábẹ́ tábìlì kan tó lágbára tàbí kó o sá sí ẹ̀gbẹ́ ògiri inú ilé. Ó lè má pẹ́ tí òmíràn á fi ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra torí náà, tètè sá síta kó o sì fi àgbègbè náà sílẹ̀. Àwọn tó ń gbẹ̀mí là lè má tètè dé, torí náà gbìyànjú kó o gba àwọn míì là.

 • Tí àkúnya omi bá ṣẹlẹ̀. Tí omi bá ya wá lójijì, tètè sá lọ sórí òkè kan, torí pé ìgbì omi náà ṣì máa pọ̀ sí i.

 • Nígbà ìjì líle tàbí ìjì àjàyípo. Tètè sá lọ sí ibi tó lè gba ìjì líle dúró.

 • Nígbà omíyalé. Tètè kúrò nítòsí ilé tí omi ti ya bò. Má ṣe máa fi ẹsẹ̀ wọ́ omi ọ̀gbàrá tó ń ya má sì ṣe wa ọkọ̀ gba inú rẹ̀, torí pé gọ́tà lè wà lábẹ́ omi náà tàbí òpó iná tó ti wó lulẹ̀ tàbí àwọn ìdọ̀tí àti nǹkan míì tó léwu.

 • Ǹjẹ́ o mọ̀? Ọ̀gbàrá tí kò ga ju ẹsẹ̀ bàtà méjì lọ lè gbé mọ́tò lọ. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí ọ̀gbàrá gbé lọ ló jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ń gbìyànjú láti wa mọ́tò gba inú ọ̀gbàrá kọjá.

 • Tí àwọn aláṣẹ bá sọ pé kí ẹ kúrò ní àgbègbè yẹn, kúrò níbẹ̀ kíá! Jẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ mọ ibi tó o wà, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n lè fi ẹ̀mí ara wọn wewu níbi tí wọ́n bá ti ń wá ẹ kiri.

  Tí àwọn aláṣẹ bá sọ pé kí ẹ kúrò ní àgbègbè yẹn, kúrò níbẹ̀ kíá!

 • Ǹjẹ́ o mọ̀? Lákòókò yẹn, ó ṣeé ṣe kí àtẹ̀jíṣẹ́ gbéṣẹ́ ju kó o pe èèyàn lórí fóònù lọ.

 • Tí àwọn aláṣẹ bá sọ pé kí ẹ má ṣe kúrò ní ilé tàbí pé kẹ́ ẹ dúró síbì kan, má ṣe kúrò níbẹ̀. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé kẹ́míkà olóró ló tú sínú afẹ́fẹ́ tàbí bọ́ǹbù runlé-rùnnà ló bú gbàù, dúró sínú ilé rẹ, kó o sì ti gbogbo wíńdò àti ilẹ̀kùn. Ká sọ pé bọ́ǹbù runlé-rùnnà ló bú gbàù, sá lọ sí kọ̀rọ̀ inú lọ́hùn-ún nínú ilé rẹ, kí ìtànṣán tó wà lára bọ́ǹbù náà má bàa pa ẹ́ lára. Gbọ́ ìròyìn lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí lórí rédíò, kó o lè mọ ohun tó ń lọ. Dúró sínú ilé rẹ títí tí àwọn aláṣẹ á fi sọ pé kò séwu mọ́.

LẸ́YÌN ÀJÁLÙ​—YẸRA FÚN EWU!

Wo àwọn àbá yìí kó o lè mọ bí wàá ṣe yẹra fún àìsàn àti àwọn ewu míì:

 • Dúró sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ìyẹn dáa ju kó o wà ní àgọ́ lọ.

 • Rí i pé ibi tó o wà mọ́ tónítóní.

 • Lo àwọn nǹkan tó lè dáàbò bò ẹ́ tó o bá ń kó ìdọ̀tí. Tó bá ṣeé ṣe, wọ ìbọ̀wọ́ àti bàtà tó nípọn, dé akoto kó o sì fi nǹkan bo imú. Ṣọ́ra fún àwọn wáyà iná tàbí àwọn nǹkan tí kò tíì jó tán.

 • Máa bá ìgbòkègbodò rẹ ojoojúmọ́ nìṣó, jẹ́ kó dà bíi pé nǹkan ń lọ bíi ti tẹ́lẹ̀. Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ rí i pé ọkàn rẹ balẹ̀ àti pé ìrètí wà. Kọ́ àwọn ọmọ ní iṣẹ́ ilé ìwé wọn, ẹ jọ ṣeré kẹ́ ẹ sì ṣe ìjọsìn ìdílé. Ẹ má ba ọkàn jẹ́ jù nítorí ìròyìn nípa àwọn àjálù náà, ẹ má sì jẹ́ kí àníyàn nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ mú kí ẹ máa kanra mọ́ ara yín. Jẹ́ kí àwọn míì ràn ẹ́ lọ́wọ́, kí ìwọ náà sì ran àwọn míì lọ́wọ́.

  After the disaster, keep your routine as normal as possible

 • Rántí pé tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, èèyàn lè pàdánù ọ̀pọ̀ nǹkan. Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ohun tí ìjọba àtàwọn àjọ tó ń ṣèrànwọ́ máa ń wá ni bí wọ́n ṣe máa gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa fún wọn ní gbogbo nǹkan tí wọ́n pàdánù. Ohun tó sì ń gbẹ̀mílà lákòókò yẹn ni omi tó mọ́, oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé tó dáa.​—1 Tímótì 6:​7, 8.

 • Gbà pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ, torí náà, gba ìrànwọ́. Èyí sábà máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ bá kọ́kọ́ wáyé. Díẹ̀ lára àwọn àmì téèyàn máa fi mọ̀ ni: àníyàn, ìrẹ̀wẹ̀sì, ìṣesí tó ń yí pa dà lódìlódì, ìrònú tí kò já geere, àìlè ṣiṣẹ́ tàbí àìróorun sùn. Tó bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, bá ọ̀rẹ́ kan tó o finú tán sọ̀rọ̀, kí ara lè tù ẹ́.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Joshua la àjálù tó wáyé níbi iṣẹ́ rẹ̀ já, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ. Àwọn alàgbà ràn án lọ́wọ́, ó sì tún gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn òyìnbó tó mọ̀ nípa ọpọlọ àti ìrònú. Ó sọ pé: “Wọ́n fi dá mi lójú pé bí ara mi ṣe ń yá, ó ṣeé ṣe kí n máa ní ẹ̀dùn ọkàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ ó máa lọ tó bá yá. Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà, mi ò fi bẹ́ẹ̀ ṣèrànrán mọ́. Àmọ́ àyà mi ṣì máa ń já tí mo bá rántí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.”

Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ó máa ń dùn wá gan-an. Àwọn kan tiẹ̀ ti fi àìmọ̀kan dẹ́bi fún Ọlọ́run pé òun ló ń fà á. Àwọn míì máa ń dẹ́bi fún ara wọn bíi ti Joshua tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, ó ní: “Ó ṣì máa ń ṣe mí bíi pé ká ní mo tún tiraka sí i ni bóyá màá lè gba ẹ̀mí àwọn èèyàn tó pọ̀ sí i là. Àmọ́, ọkàn mi balẹ̀ pé láìpẹ́ Ọlọ́run máa mú gbogbo nǹkan tọ́, ohun tó ti bà jẹ́ á sì pa dà dáa. Ní báyìí ná, mo mọyì bí Ọlọ́run ṣe dá ẹ̀mí mi sí, mo sì ń ṣe gbogbo ohun tí agbára mi gbé láti fi hàn pé mo mọyì ẹ̀mí mi.”​—Ìṣípayá 21:​4, 5. *

^ ìpínrọ̀ 33 Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i nípa àwọn ìlérí Ọlọ́run àti ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà, wo ìwé Kíni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? O lè wà á jáde lórí ìkànnì wa www.jw.org/yo.