Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Nǹkan Lò

Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Nǹkan Lò

NÍNÚ ilé, a máa ń fi kẹrosíìnì tàbí gáàsì dáná, a sì máa ń rọ epo sínú mọ́tò kó lè ṣiṣẹ́. Àmọ́, àwọn nǹkan yìí kì í tó lọ́pọ̀ ibi kárí ayé.

Gary tó wá láti South Africa sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni epo ń gbówó lórí, ìṣòro ńlá sì lèyí.” Ní ti Jennifer tó wá láti Philippines, ọ̀rọ̀ iná tí kò láyọ̀lé ti tojú sú u, ó ní: “Ńṣe ni iná mànàmáná máa ń ṣe ségesège.” Fernando tó wá láti El Salvador ní tiẹ̀ sọ pé: “Ipa tí èéfín, epo tàbí gáàsì ń ní lórí àwọn nǹkan abẹ̀mí ń kọ mí lóminú.” Òótọ́ lọ̀rọ̀ Fernando yìí torí pé kárí ayé ni èéfín ti ń ba àyíká jẹ́.

O lè wá bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè borí àwọn ìṣòro yìí?’

À fi máa ṣọ́ iná, epo, gáàsì tàbí kẹrosíìnì lò. Ó máa ṣàǹfààní tá a bá ń ṣọ́ àwọn nǹkan yìí lò tàbí tá à ń lò ó lọ́nà tó bójú mu. Tá a bá ṣọ́ wọn lò, èyí á dín ìnáwó kù. Ó tún máa dáàbò bo àyíká wa, ohun tí kò tó á sì ṣẹ́ kù.

Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà tá a lè gbà máa ṣọ́ àwọn nǹkan lò nínú ilé, tá a bá ń rìnrìn àjò àti nínú ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́.

NÍNÚ ILÉ

Fi ọgbọ́n lo àwọn ẹ̀rọ tó ń mú kí nǹkan gbóná tàbí tutù. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Yúróòpù fi hàn pé tó bá ti mọ́ wa lára láti máa yí ẹ̀rọ tó ń mú kí ilé móoru nígbà òtútù sílẹ̀ díẹ̀, epo tó máa lò láàárín ọdún kan á dín kù gan-an. Derek tó ń gbé orílẹ̀-èdè Canada gbà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Dípò ka tan ẹ̀rọ tó ń mú ilé móoru lásìkò òtútù, ṣe la máa ń wọ aṣọ òtútù, ìyẹn sì ti mú kí iye epo tí ìdílé wa lò lákòókò yẹn dín kù gan-an.”

Bákan náà lọ̀rọ̀ rí tá a bá fẹ́ mú kí ilé tutù nígbà ooru. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gbẹ́ni Rodolfo tó wá láti orílẹ̀-èdè Philippines máa ń tẹ bọ́tìnì kan lára ẹ̀rọ amúlétutù rẹ̀ tó máa jẹ́ kí ẹ̀rọ náà máa dá iṣẹ́ dúró tí kò bá fi bẹ́ẹ̀ sí ooru. Ó sọ pé: “Ohun tí mo ṣe yìí ni kì í jẹ́ kí ẹ̀rọ náà jẹ epo, ó sì dín owó kù.”

Pa wíńdò àti ilẹ̀kùn dé tó o bá ń lo ẹ̀rọ tó ń mú ilé tutù tàbí èyí tó ń mú ilé móoru. * Tó o bá fẹ́ dín ìwọ̀n epo tó o ń lò kù, máa ti wíńdò àti ilẹ̀kun rẹ tó o bá ń lo ẹ̀rọ tó ń mú ilé tutù tàbí èyí tó ń mú ilé móoru. Bí àpẹẹrẹ, tí èèyàn bá ṣílẹ̀kùn sílẹ̀ nígbà òtútù, ẹ̀rọ tó ń mú kí ilé móoru máa jẹ iná tó pọ̀ gan-an.

Yàtọ̀ sí kéèyàn máa ti ilẹ̀kùn àti wíńdò, ọgbọ́n míì tí àwọn kan ń dá ni pé, wọ́n ṣe àwọn wíńdò kan tí wọ́n ṣe lárà ọ̀tọ̀ sí ilé wọn. Àwọn wíńdò yìí kì í jẹ́ kí ooru jáde síta lákòókò òtútù. Èyíti sì ti dín ìnáwó wọn kù gan-an.

Máa lo àwọn gílóòbù tí kì í jẹ iná púpọ̀. Jennifer tá a mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “A kò lo àwọn gílóòbù tó máa ń jẹ iná mọ́, ńṣe la lọ ra èyí tí kì í jẹ iná púpọ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn gílóòbù tá à ń sọ yìí máa ń wọ́nwó díẹ̀, àmọ́ bó ṣe jẹ́ pé wọn kì í jẹ iná púpọ̀, tí wọ́n sì lálòpẹ́ jẹ́ kéèyàn rí i pé òun ló dáa fẹ́ni tó fẹ́ ṣọ́wó ná.

TÁ A BÁ Ń RÌNRÌN ÀJÒ

Tó bá ṣeé ṣe máa wọ mọ́tò èrò. Àpẹẹrẹ kan ni Andrew tó wá láti orílẹ̀-èdè Great Britain. Ó sọ pé: “Tó bá ṣeé ṣe, rélùwéè ni mo máa ń wọ̀ lọ síbi iṣẹ́ tàbí kí n wa kẹ̀kẹ́.” Ìwé kan tó ń jẹ́ Energy: What Everyone Needs to Know sọ pé, “téèyàn bá wa mọ́tò ara rẹ̀, ìlọ́po mẹ́ta epo tí mọ́tò èrò tàbí rélùwéè máa lò ni onítọ̀hún máa lò.”

Ṣètò ìrìn àjò rẹ. Tó o bá múra ìrìn àjò rẹ sílẹ̀ ṣáájú, á ṣeé ṣe fún ẹ láti pa àwọn ìrìn kan pọ̀ kó o lè ṣọ́ epo lò kó o sì dín ìrìn àjò tí wàá rìn kù, á tún jẹ́ kó o ṣọ́wó ná, oò sì ní fi àkókò ṣòfò.

Àpẹẹrẹ ẹnì kan tó ṣe bẹ́ẹ̀ ni Jethro, tó wá láti orílẹ̀-èdè Philippines. Ohun tó ṣe ni pé ó ti pinnu iye owó táá máa fi ra epo sí mọ́tò rẹ̀ lóṣooṣù. Ó ní: “Ìyẹn ti jẹ́ kí n lè máa ṣètò ìrìn àjò mi lọ́nà tó gbéṣẹ́.”

ÌGBÒKÈGBODÒ OJOOJÚMỌ́

Má ṣe máa fi ìgbà gbogbo lo omi gbígbóná. Ìwádìí tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà fi hàn pé, “ohun tó ju ìdá mẹ́rin iná tí àwọn èèyàn ń lò nínú ilé wọn ló jẹ́ pé omi gbígbóná ni wọ́n ń lò ó fún.”

Omi gbígbóná máa ń jẹ iná tó pọ̀, torí náà, tá a bá fẹ́ ṣọ́ iná lò, àfi ká dín omi gbígbóná tí à ń lò kù. Èyí sì bọ́gbọ́n mu, ìdí nìyẹn tí Victor láti orílẹ̀-èdè South Africa fi sọ pé: “Ńṣe la máa ń ṣọ́ omi gbígbóná lò pàápàá tá a bá fẹ́ wẹ̀.” Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tó ń jẹ́ Steven Kenway tún fi kún un, ó ní: “Kéèyàn máa ṣọ́ omi gbígbóná lò dáa gan-an, torí pé ó máa ń dín ìnáwó kù.”

Máa pa àwọn ẹ̀rọ tí o kò lò. Èyí kan àwọn gílóòbù àti àwọn ẹ̀rọ abáná ṣiṣẹ́ bíi tẹlifíṣọ̀n àti kọ̀ǹpútà. Àwọn ẹ̀rọ míì ṣì máa ń jẹ iná lọ lábẹ́lẹ̀ lẹ́yìn tó o bá pa wọ́n, ìdí nìyẹn tí àwọn onímọ̀ kan fi sọ pé lẹ́yìn tí o bá pa ẹ̀rọ kan, rí i pé o yọ wáyà rẹ̀ kúrò lára sọ́kẹ́ẹ̀tì iná. Fernando tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ó ti mọ́ mi lára láti máa pa iná tí mo bá ń jáde, mo sì máa ń yọ àwọn wáyà ẹ̀rọ kúrò lára sọ́kẹ́ẹ̀tì tí mi ò bá lò wọ́n.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí nǹkan kan tá a lè ṣe sọ́rọ̀ epo, gáàsì, kẹrosíìnì àti iná tó ń gbówó lórí, bẹ́ẹ̀ sì la ò rí nǹkan ṣe sí bí èéfín ṣe ń ba àyíká jẹ́, síbẹ̀ a lè máa ṣọ́ àwọn nǹkan yìí lò. Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti pinnu láti máa ṣe nìyẹn. Èyí gba ìsapá lóòótọ́, àmọ́ tá a bá ń ṣọ́ epo, gáàsì, kẹrosíìnì àti iná lò, á ṣe wá láǹfààní. Valeria tó wá láti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, sọ pé: “Ṣíṣọ́ nǹkan lò ti dín ìnáwó mi kù, ó sì jẹ́ kí n lè máa dáàbò bo àyíká mi.”

^ ìpínrọ̀ 10 Àmọ́ ṣá o, láwọn ibì kan, irú ẹ̀rọ tí wọ́n ń lò nínú ilé wọn lè gba kí wọ́n ṣílẹ̀kùn àti wíńdò sílẹ̀ kí afẹ́fẹ́ gbẹ̀mígbẹ̀mí má bàa dé wọn mọ́lé. Torí náà, rí i pé o tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà lára ẹ̀rọ tó o rà sílé rẹ.