Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Ìkarawun ìṣáwùrú

Ìkarawun ìṣáwùrú

ÌKARAWUN tó wà lára àwọn ìṣáwùrú máa ń jẹ́ kí wọ́n lè gbé níbi tí kò rọrùn, pàápàá lábẹ́ òkun nísàlẹ̀ lọ́hùn-ún. Bí ìkarawun yìí ṣe ń dáàbò bo ìṣáwùrú yìí mú kí àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèwádìí nípa ìkarawun náà láti mọ bí wọ́n ṣe lè ṣe àwọn mọ́tò tó máa dáàbò bo ẹni tó wà nínú rẹ̀ àti ilé tó lè dáàbò bo àwọn tó ń gbé inú rẹ̀.

Rò ó wò ná: Nígbà tí àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ń ṣèwádìí nípa ìkarawun, oríṣi méjì ni wọ́n gbé yẹ̀ wò. Ọ̀kan ni èyí tó ní igun méjì tó wá rí pẹrẹsẹ níwájú. Èkejì ni èyí tó rí rógódó látòkè délẹ̀ bíi ti ìgbín.

Ní ti onígun méjì yẹn, àwọn onímọ̀ ṣàkíyèsí pé ó ní ìlà lára tó wá láti apá òkè dé apá tí ó tẹ́ pẹrẹsẹ níwájú. Tí omi bá ń ru gùdù, apá òkè tó kéré tó sì ṣe kodọrọ yìí ló máa ń gbà á sára kí omi má bàa wọ́ ìṣáwùrú náà lọ. Lẹ́nu kan ṣá, ìkarawun yìí ló ń dáàbò bo ìṣáwùrú náà lọ́wọ́ ewu.

Àwọn olùṣèwádìí tún fi ìkarawun ìṣáwùrú yìí wé òmíràn, wọ́n kíyè sí i pé ìlà wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ tó wà lára ìkarawun yìí ń ṣiṣẹ́ gan-an láti pèsè ààbò ìlọ́po méjì fún ìṣáwùrú náà ju èyí tí ìkarawun tí wọ́n fi wéra lè pèsè lọ.

Ìwé ìròyìn Scientific American sọ pé: “Lọ́jọ́ iwájú, tí wọ́n bá fi irú ìkarawun yìí ṣe ara mọ́tò, irú mọ́tò bẹ́ẹ̀ máa dára, á sì lágbára láti dáàbò bo àwọn tó wà nínú rẹ̀.”

Kí lèrò rẹ: Ṣé ìkarawun ìṣáwùrú yìí ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?