Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

City of Astana

ILẸ̀ ÀTI ÀWỌN ÈÈYÀN

Ẹ Já Ká Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan

Ẹ Já Ká Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan

DARANDARAN ni ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú yìí. Títí dí òní àwọn èèyàn ilẹ̀ yìí máa ń kó ẹran wọn jẹ̀ kiri bí ojú ọjọ́ bá ṣe gbà. Nígbà ooru, wọ́n máa ń daran lọ sí orí àwọn òkè tó tutù. Tó bá sì di ìgbà òtútù, wọ́n máa da àwọn ẹran wọn wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀.

Inú ìlú ńlá ni àwọn kan ń gbé. Síbẹ̀, èèyàn á rí i lára wọn pé wọn kò gbàgbé ìgbésí ayé darandaran tí àwọn baba ńlá wọn gbé. Èyí hàn nínú àṣà wọn, oúnjẹ wọn àti iṣẹ́ ọwọ́ tí wọ́n ń ṣe. Àwọn èèyàn ilẹ̀ Kazakhstan máa ń gbádùn ewì tó dùn, orin àti àwọn orin tí wọ́n fi ohun èlò orin ìbílẹ̀ wọn kọ.

Ilé tí wọ́n máa ń gbé rí roboto, kì í sì tóbi púpọ̀, àwọn èèyàn sọ pé àwọn tó ń gbé irú ilé yìí máa ń mọyì ìṣẹ̀dá Ọlọ́run. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà láàárín wọn fẹ́ràn ilé náà, àwọn tó ń gbé inú ìlú ńlá láàárín wọn sì sábà máa ń lo irú ilé bẹ́ẹ̀ fún ayẹyẹ pàtàkì. Àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ pàápàá fẹ́ràn láti máa dé sínú ilé yìí. Inú ilé wọn máa ń kún fún àwọn aṣọ aláràbarà tí àwọn obìnrin wọn hun tí wọ́n sì fi tẹ́ kápẹ́ẹ̀tì sílẹ̀ tàbí sára ògiri wọn.

Nínú ilé wọn

Àwọn tó ń gbé lábúlé nínú wọn fẹ́ràn ẹṣin púpọ̀. Ó kéré tán, wọ́n ní orúkọ mọ́kànlélógún [21] tí wọ́n fi ń pe ẹṣin, tó ní oríṣiríṣi ìtumọ̀ tó jinlẹ̀. Wọ́n sì ní ọ̀rọ̀ tó ju ọgbọ̀n [30] lọ tí wọ́n fi ń ṣàlàyé àwọ̀ tí ẹṣin ní. Ẹ̀bùn ńlá tó jọjú gbáà ni tí wọ́n bá fún ẹnì kan lẹ́ṣin. Àti kékeré ni àwọn ọmọkùnrin wọn ti máa ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń gun ẹṣin.

Oúnjẹ ìbílẹ̀ wọn kì í ta lẹ́nu, ó sì máa ń ní ẹran nínú dáadáa. Koumiss ni wọ́n máa ń mu, wàrà ẹṣin ni wọ́n fi ṣe é, wọ́n sì gbà pé ó ń ṣara lóore gan-an. Wọ́n tún máa ń mu shubat tó kan díẹ̀ lẹ́nu, wàrà ràkúnmí ni wọ́n fi ṣe ìyẹn.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Almaty kí àwọn alèjò káàbọ̀ láti rìn yíká ọgbà náà.

Àmọ̀tẹ́kùn orí yìnyín máa ń wà ní orí àwọn òkè Kazakhstan nígbà ẹ̀ẹ̀rùn