OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ
Nípa Àwọn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà
Ìròyìn tó wá láti àwọn ilẹ̀ tó wà ní apá Ìwọ̀ Oòrùn Ayé fi hàn pé ó tọ́ ká máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò.
Ọ̀NÀ MÍÌ TÁ A LÈ FI DÍN ÌDÀÀMÚ KÙ
Ìwádìí tí wọ́n ṣe ní ìpínlẹ̀ Vancouver, lórílẹ̀-èdè Kánádà fi hàn pé táwọn èèyàn bá dín bí wọ́n ṣe ń ka àtẹ̀jíṣẹ́ kù sí nǹkan bí ìgbà mẹ́ta lóòjọ́, dípò tí wọ́n á fi máa wò ó lemọ́lemọ́, ó máa dín ìdààmú wọn kù. Kostadin Kushlev, tó ṣáájú ìwádìí náà sọ pé ìbí tí òun parí èrò sí ni pé: “Ó máa ń ṣorò fún àwọn èèyàn láti lo ìkóra-ẹni-níjàánu tó bá dọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń ka àtẹ̀jíṣẹ́, àmọ́ tí wọ́n bá lè máa kó ara wọn níjàánu, ó máa dín ìdààmú wọn kù.”
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ: “Àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé báyìí, torí náà ǹjẹ́ kò yẹ ká wá ọ̀nà láti dín ìdààmú kù?
NǸKAN TI SUNWỌ̀N SÍ I NÍNÚ ÒKUN
Ìròyìn kan tí àjọ Wildlife Conservation Society (WCS) gbé jáde fi hàn pé ẹja àtàwọn onírúurú ohun abẹ̀mí ti wá ń pọ̀ sí i ní okùn tó wà ní Belize àtàwọn àgbègbè míì ní erékùṣù Caribbean. Ohun tó jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe ni pé ìjọba ṣòfin pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ wa ohun àmúṣọrọ̀ láwọn àgbègbè yìí. Ó fi kún un pé: “Ó lè tó nǹkan bí ọdún mẹ́fà kí àwọn ohun abẹ̀mí tó wà láwọn àgbègbè yìí tó pọ̀ sí i. Àmọ́, ó máa gba ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó lè pọ̀ dáadáa.” Janet Gibson, tó jẹ́ adarí ètò ní àjọ WCS sọ nípa ìlú Belize pé: “Ó ti wá ṣe kedere pé bí ìjọba kò ṣe gbà kí wọ́n máa wa ohun àmúṣọrọ̀ làwọn àgbègbè yìí máa jẹ́ kí ẹja àtàwọn onírúurú ẹ̀dá abẹ̀mí inú okùn pọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè yìí.”
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ: Ǹjẹ́ bí ayé ṣe máa ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tun kò fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wà?
ÌWÀ IPÁ GBÒDE KAN NÍ BRAZIL
Ilé iṣé ìròyìn kan tí wọ́n ń pè ní Agência Brasil sọ pé ìwà ipá ti ń pọ̀ sí i ní Brazil. Lọ́dún 2012, àwọn èèyàn tí wọ́n pa lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [56,000]. Èyí ni ìpànìyàn tó tíì pọ̀ jù lọ láàárín ọdún kan tó wà lákọọ́lẹ̀ Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìlera lórílẹ̀-èdè Brazil. Luís Sapori tó mọ̀ nípa ààbò àwọn aráàlú gbà pé ohun tó fa ìṣòro yìí ni bí ìwà ọmọlúwàbí ṣe ń pòórá. Ó sọ pé táwọn èèyàn ò bá ti bọ̀wọ̀ fún òfin ìlú mọ́, “wọn á bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ipá láti mú ìfẹ́ inú wọn ṣẹ.”
ǸJẸ́ O MỌ̀? Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò kan tí ìfẹ́ àwọn èèyàn á “di tútù,” tí ìwà àìlófin á sì gbòde kan.