Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Èyí Mà Rọrùn Gan-an O!”

“Èyí Mà Rọrùn Gan-an O!”

SOO-JEONG, tó jẹ́ agbaninímọ̀ràn fáwọn ọmọléèwé lórílẹ̀-èdè South Korea, máa ń lo àwọn fídíò tó wà ní ìkànnì jw.org láti kọ́ àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀. Ó sọ pé: “Ohun tí àwọn ọmọ kíláàsì mi ṣe nígbà tí wọ́n wo fídíò Ta Ni Ọ̀rẹ́ Tòótọ́? wú mi lórí gan-an! Lẹ́yìn tí wọ́n wo fídíò náà, wọ́n sọ pé ‘mi ò tíì ronú nípa yíyan ọ̀rẹ́ lọ́nà tí fídíò yìí gbà ṣàlàyé rẹ̀. Èyí mà rọrùn gan-an o.’ Àwọn kan sọ pé àwọn á máa lọ sí ìkànnì yìí nígbàkigbà táwọn bá nílò ìmọ̀ràn.” Soo-jeong fi kún un pé: “Mo ti sọ fún àwọn olùkọ́ ẹlẹgbẹ́ mi pé kí wọ́n máa lo fídíò yìí, inú wọn sì dùn pé àwọn ní irú nǹkan báyìí táwọn lè fi kọ́ àwọn ọmọléèwé lẹ́kọ̀ọ́.”

Fídíò míì tó tún ti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè South Korea ni fídíò eré ojú pátákó kan tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Bó O Ṣe Lè Borí Ẹni Tó Ń Halẹ̀ Mọ́ Ẹ Láìbá A Jà. Olùkọ́ kan tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àjọ kan tó ń jẹ́ Juvenile Violence Prevention Foundation fi fídíò yìí han àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Ó sọ pé: “Fídíò náà wọ ọ̀pọ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́kàn torí àwọn àwòrán tó fani mọ́ra tó wà nínú rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, fídíò náà wúlò gan-an torí pé ó sọ ohun tó o lè ṣe tí wọ́n bá halẹ̀ mọ́ ẹ àti bí o kò ṣe ní kó sọ́wọ́ àwọn tó máa halẹ̀ mọ́ ẹ.” Àjọ náà gba àṣẹ lọ́wọ́ wa láti máa fi fídíò náà kọ́ àwọn ọmọ iléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ti girama lẹ́kọ̀ọ́. A sì fọwọ́ sí i. Àwọn ọlọ́pàá náà máa ń lo àwọn fídíò tó wà ní ìkànnì jw.org.

Tí o kò bá tíì wo ìkànnì jw.org, a rọ̀ ẹ́ pé kó o lọ wo ohun tó wà níbẹ̀. Ó rọrùn gan-an láti lò. Ọ̀fẹ́ lo sì máa wa ohun tó o bá fẹ́ jáde níbẹ̀, títí kan ohùn tá a gba sílẹ̀, fídíò,Bíbélì àtàwọn ìwé lóríṣiríṣi.