Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìtàn Àtijọ́

Aristotle

Aristotle

NÍ OHUN tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́tà ọdún [2,300 ] sẹ́yìn, Aristotle kó ipa pàtàkì láti mú kí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí tẹ̀ síwájú. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló nífẹ̀ẹ́ sí àwárí tó ṣe, wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí ọ̀pọ̀ èdè, ọ̀pọ̀ èèyàn sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ James MacLachlan kọ̀wé pé: “Èrò tí Aristotle ní nípa ìṣẹ̀dá láwọn èèyàn ilẹ̀ Yúróòpù tẹ̀ lé fún nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún.” Díẹ̀ lára èrò Aristotle tiẹ̀ nípa lórí ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì, Protestant àti Ìsìláàmù.

Ọ̀pọ̀ Nǹkan Ni Ìwádìí Rẹ̀ Dá Lé

Aristotle kọ̀wé nípa onírúurú nǹkan bí iṣẹ́ ọ̀nà, ìràwọ̀, àwọn nǹkan abẹ̀mí, ìwà, èdè, òfin, ọgbọ́n, òòfà, físíìsì, ìgbádùn, ewì, ìṣèlú, ìrònú ẹ̀dá, ọ̀rọ̀ sísọ, tó fi mọ ọkàn, tó gbà pé ó máa ń kú. Àmọ́ ohun tó jẹ́ kó gbajúmọ̀ jù lọ ni ẹ̀kọ́ nípa ohun abẹ̀mí àti ọgbọ́n orí.

Àwọn ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Gíríìkì ayé àtijọ́ máa ń ṣàkíyèsí nǹkan tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ òótọ́, wọ́n sì gbà pé táwọn bá ronú jinlẹ̀ nípa rẹ̀ àwọn á dé ìparí èrò tó bọ́gbọ́n mu. Ọ̀nà yìí ni wọ́n ń gbà ṣàlàyé bí ayé àtọ̀run ṣe rí.

Ọgbọ́n tí wọ́n ń dá yìí ló jẹ́ kí wọ́n lè ní àwọn èrò tó tọ́ nípa àwọn nǹkan kan, ọ̀kan lára rẹ̀ ni pé ohun kan wà tó ń darí ayé àti ọ̀run. Ó kàn jẹ́ pé ìwọ̀nba ni ibi tí wọ́n rí nǹkan dé, èyí sì kó ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ṣìnà, tó fi mọ́ Aristotle. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n rò pé ńṣe ni àwọn pílánẹ́ẹ̀tì àtàwọn ìràwọ̀ ń yípo ayé. Nígbà yẹn, èyí ni wọ́n kà sí òtítọ́ tó bọ́gbọ́n mu. Ìwé The Closing of the Western Mind sọ pé: “Àròjinlẹ̀ àti ohun tí wọ́n fojú rí mú kí ọ̀pọ̀ gbà pé ńṣe ni ayé dúró sójú kan, tí oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ sì ń yípo rẹ̀.”

Ká ní kì í ṣe pé wọ́n mú èrò tí kò tọ́ yìí wọnú ẹ̀sìn ni, ìwọ̀nba ni wàhálà tí ọ̀rọ̀ náà dá sílẹ̀ ì bá mọ.

Àwọn Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì Fara Mọ́ Èrò Aristotle

Nígbà yẹn lọ́hùn, àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni nílẹ̀ Yúróòpù gba àwọn kan lára ẹ̀kọ́ Aristotle sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí kò lábùlà. Thomas Aquinas (nǹkan bí ọdún 1224-1274) tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aṣáájú ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì fi àwọn ẹ̀kọ́ Aristotle kún ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì. Èyí mú kí èrò Aristotle pé ńṣe ni ayé dúró sojú kan di ara ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Protestant náà gba ẹ̀kọ́ yìí wọlé. Lára wọn ni Calvin àti Luther, tí wọ́n sọ pé ẹ̀kọ́ náà bá Bíbélì mu.—Wo àpótí náà “ Ó Bá Ohun Tí Bíbélì Sọ Mu.”

Wọ́n gba àwọn kan lára ẹ̀kọ́ Aristotle sí ẹ̀kọ́ òtítọ́

Òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Charles Freeman sọ pé: “Nínú àwọn ẹ̀kọ́ kan, ó jọ pé èèyàn kò lè rí ìyàtọ̀ láàárín [àwọn ẹ̀kọ́ Aristotle] àti ti ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì.” Èyí ló mú káwọn kan sọ pé ọ̀gbẹ́ni Aquinas ti fẹ́rẹ̀ẹ́ fi ẹ̀kọ́ Aristotle rọ́pò ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì. Ọ̀gbẹ́ni Freeman sọ pé, “Aquinas ló wá di ọmọlẹ́yìn Aristotle.” Láwọn ọ̀nà kan, a lè sọ pé ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni fẹ́rẹ̀ẹ́ má yàtọ̀ sí ohun tí Aristotle fi kọ́ni. Fún ìdí yìí, nígbà tí ọmọ Ítálì kan tó ń jẹ́ Galileo tó jẹ́ onímọ̀ nípa sánmà àti ìṣirò mú ẹ̀rí wá pé ayé ló ń yípo oòrùn, ńṣe ni wọ́n fipá mú un wá jẹ́jọ́, wọ́n sì ní kó yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa dà. * Ṣùgbọ́n, Aristotle fúnra rẹ̀ mọ̀ pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì máa ń tẹ̀ síwájú àti pé ó lè yí pa dà tí wọ́n bá ṣàwárí ohun tuntun. Àmọ́ èrò àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yàtọ̀ sí tiẹ̀!

^ ìpínrọ̀ 11 Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i nípa ọ̀rọ̀ Galileo àti ṣọ́ọ̀ṣì, wo àpilẹ̀kọ yìí Galileo’s Clash With the Church,” nínú Jí! April 22, 2003, lédè Gẹ̀ẹ́sì.