Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ṣé Ọwọ́ Rẹ Máa Ń Dí Jù?

Ṣé Ọwọ́ Rẹ Máa Ń Dí Jù?

Ṣé ọwọ́ rẹ máa ń dí jù? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìwọ nìkan. Ìwé ìròyìn The Economist tiẹ̀ sọ pé: “Ó jọ pé ibi gbogbo ni ọwọ́ àwọn èèyàn ti máa ń dí báyìí.”

NÍ ỌDÚN 2015, wọ́n fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn òṣìṣẹ́ kan ní orílẹ̀-èdè mẹ́jọ, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sọ pé kì í rọrùn fún àwọn láti ṣe ojúṣe àwọn níbi iṣẹ́ àti nínú ilé. Díẹ̀ lára ohun tó fà á ni pé ojúṣe wọn níbi iṣẹ́ àti ní ilé ń pọ̀ sí i, ọjà túbọ̀ ń wọ́n sí i, iṣẹ́ sì ń gba àkókò púpọ̀ sí i. Bí àpẹẹrẹ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn òṣìṣẹ́ kan sọ pé ó tó wákàtí mẹ́tàdínláàádọ́ta [47] tí àwọn fi ń ṣiṣẹ́ lọ́sẹ̀. Àwọn míì sì wà tó jẹ́ pé ọgọ́ta wákàtí tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ lọ́sẹ̀!

Nínú ìwádìí míì tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínlógójì [36], ó ju ìdámẹ́rin àwọn tí wọ́n fọ́rọ̀ wá lẹ́nu wò tó sọ pé tí àwọn ò bá sí lẹ́nu iṣẹ́ pàápàá, gìrìgìrì ni gbogbo nǹkan tí àwọn bá ń ṣe ṣì máa ń bọ́ sí! Kódà, àkóbá kékeré kọ́ ló máa ṣe fún àwọn ọmọ táwọn òbí bá ń gbé iṣẹ́ tó pọ̀ jù fún wọn.

Tó bá ti mọ́ wa lára láti máa ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó, ó máa ń mú kí nǹkan tojú súni, torí pé ńṣe ni àkókò á máa lé wa léré ṣáá. Ǹjẹ́ nǹkan kan wà tí èèyàn lè ṣe kó má bàa ki àṣejù bọ ọ̀rọ̀ iṣẹ́? Ipa wo ni ohun tá a gbà gbọ́, ìpinnu wa àti àwọn ohun tá à ń lépa ń ní lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun mẹ́rin tó mú kí àwọn kan máa ṣe iṣẹ́ àṣejù.

WỌ́N FẸ́ MÁA PÈSÈ GBOGBO NǸKAN TÍ ÌDÍLÉ WỌN NÍLÒ

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Gary sọ pé: “Gbogbo ọjọ́ ni mo fi ń ṣiṣẹ́, torí pé gbogbo nǹkan tó dára ni mo fẹ́ máa ṣe fún àwọn ọmọ mi. Mi ò fẹ́ kí ìyà tó jẹ mí jẹ àwọn ọmọ mi.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó dáa ló wà lọ́kàn irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ ó yẹ kí wọ́n fara balẹ̀ ronú lórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. Àwọn ìwádìí kan fi hàn pé àwọn àgbàlagbà àtàwọn ọmọdé tó bá ka owó àti ohun ìní sí pàtàkì jù kì í fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀, wọn kì í ní ìtẹ́lọ́rùn, ara wọn kì í sì í yá gágá bíi ti àwọn tí kò ka owó àti ohun ìní sí pàtàkì jù.

Àwọn ọmọ tí wọ́n ń kọ́ pé nǹkan ìní tara ló ṣe pàtàkì jù kì í sábà láyọ̀

Torí pé àwọn òbí kan fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn yọrí ọlá lẹ́yìnwá ọ̀la, wọ́n máa ń fi iṣẹ́ pá ara wọn àtàwọn ọmọ wọn lórí. Ìwé kan tó ń jẹ́ Putting Family First sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ ní ire ọmọ wọn lọ́kàn, wàhálà ńlá gbáà ló máa dá sílẹ̀ fún gbogbo ìdílé náà.”

WỌ́N FẸ́ NÍ OHUN TÓ PỌ̀

Ìwé kan tó ń jẹ́ The Economist sọ pé: “Àwọn tó ń polówó ọjà fẹ́ ká gbà pé ńṣe là ń fi nǹkan gidi du ara wa tá ò bá ra àwọn nǹkan tó lòde. Ojoojúmọ́ ni àwọn nǹkan tuntun ń jáde lóríṣiríṣi, bíi fíìmù, oúnjẹ, àtàwọn nǹkan míì, ńṣe ni èyí sì ń lé àwọn èèyàn léré. Níbi tí wọ́n ti ń ronú nípa èyí tí wọ́n máa rà, òmíràn tún ti jáde.”

Ní ọdún 1930, gbajúgbajà onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé kan sọ pé bí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé ṣe túbọ̀ ń jáde máa jẹ́ káwọn èèyàn ráyè gbọ́ ti ara wọn. Ó ṣeni láàánú pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Elizabeth Kolbert tó jẹ́ òǹkọ̀wé fún ìwé ìròyìn New Yorker sọ pé: “Dípò kí àwọn èèyàn tètè kúrò ní ibi iṣẹ́, ńṣe ni wọ́n á tún máa ṣe àfikún iṣẹ́ kí wọ́n lè rówó ra àwọn nǹkan tuntun,” èyí kì í jẹ́ kí wọ́n ráyè gbọ́ ti ara wọn.

WỌ́N FẸ́ TẸ́ ÀWỌN MÍÌ LỌ́RÙN

Àwọn òṣìṣẹ́ kan máa ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó torí kí wọ́n lè gbayì lójú ọ̀gá wọn. Àwọn òṣìṣẹ́ kan tún máa ń fipá mú àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn láti ṣe àfikún iṣẹ́, bí ẹni kàn bá sì sọ pé òun ò ṣe, ńṣe ni wọ́n á kan irú ẹni bẹ́ẹ̀ lábùkù. Ọrọ̀ ajé tó ti dẹnu kọlẹ̀ tún máa ń mú kí àwọn kan máa fojoojúmọ́ ayé ṣiṣẹ́, kí wọ́n má bàa dá wọn dúró ní ibi iṣẹ́.

Àwọn òbí kan máa ń fẹ́ ṣe bíi ti àwọn ìdílé míì tó ń sáré lójú méjèèjì káwọn ọmọ wọn lè yọrí ọla. Àmọ́ tí wọn ò bá rí i ṣe, wọ́n máa ń rò pé ńṣe ni àwọn ń fi nǹkan rere “du” àwọn ọmọ àwọn.

WỌ́N FẸ́ GBAYÌ LÁWÙJỌ

Tim tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Mo fẹ́ràn iṣẹ́ mi gan-an, ńṣe ni mo sì máa ń rúnpá-rúnsẹ̀ sí i lójoojúmọ́ ayé mi. Mo fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé mo tó gbangba sùn lọ́yẹ́.”

Ọ̀pọ̀ èèyàn náà ni ọ̀rọ̀ wọn jọ ti Tim, wọ́n gbà pé táwọn bá ń rúnpá-rúnsẹ̀ sí iṣẹ́, èyí á jẹ́ káwọn èèyàn máa fojú iyì wo àwọn. Elizabeth Kolbert tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Kí àwọn èèyàn máa sọ pé ọwọ́ àwọn dí ti wá di ohun àmúyangàn. Bí ọwọ́ rẹ bá ṣe dí tó ni wàá ṣe gbayì tó láwùjọ.”

MÁ ṢE JU ARA RẸ LỌ

Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa siṣẹ́ kára. (Òwe 13:4) Àmọ́, ó tún sọ pé ká má ṣe ju ara wa lọ. Oníwàásù 4:6 sọ pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.”

Tá ò bá ṣe ju ara wa lọ, ọpọlọ wa á jí pépé ara wa á sì yá gágá. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe lóòótọ́ pé kí èèyàn má ṣe àṣejù nídìí iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àbá mẹ́rin tó lè ràn wá lọ́wọ́:

MỌ ÀWỌN OHUN TÓ YẸ KÓ O KÀ SÍ PÀTÀKÌ

Kò sí ohun tó burú nínú kí èèyàn lówó lọ́wọ́. Àmọ́, báwo la ò ṣe ní ki àṣejù bọ̀ ọ́? Kí ló ń mú kí ayé yẹni? Ṣé owó tó ń wọlé fúnni àti ohun ìní la fi ń mọ ẹni tí ayé yẹ? Kókó ibẹ̀ ni pé àpọ̀jù gbogbo nǹkan ni kò dáa, kódà àpọ̀jù ìsinmi tàbí eré ìnàjú pàápàá lè mú kí nǹkan tojú súni.

Tim tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Nígbà tí èmi àti ìyàwó mi fara balẹ̀ wo ìgbé ayé wa, a rí i pé a ti ń ṣe ju ara wa lọ. A wá ṣàkọsílẹ̀ bí ìgbé ayé wa ṣe rí ní báyìí àti bá a ṣe fẹ́ kó rí. A sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tójú wa ti rí nítorí àwọn ohun tá a ti ṣe sẹ́yìn àti bí a ṣe lè ṣàtúnṣe.”

MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÌPOLÓWÓ ỌJÀ KÓ BÁ Ẹ

Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká ṣọ́ra fún “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú.” (1 Jòhánù 2:​15-17) Ìpolówó ọjà lè mú kó máa wu èèyàn láti ní oríṣiríṣi nǹkan, á wá di pé èèyàn ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó tàbí kó máa ná owó tó pọ̀ jù sórí eré ìnàjú. Ká sòótọ́, a ò lè sá fún gbogbo ìpolówó ọjà. Àmọ́ gbogbo ẹ̀ náà kọ́ ló yẹ ká máa kà sí pàtàkì. Ó tún yẹ ká fara balẹ̀ ronú nípa ohun tá a nílò gangan.

Kò tún yẹ ká gbàgbé pé àwọn tá a jọ ń kẹ́gbẹ́ lè kó bá wa. Tó bá jẹ́ pé torí-tọrùn làwọn ọ̀rẹ́ rẹ fi ń lépa ọrọ̀ tàbí pé ohun ìní ni wọ́n kà sí pàtàkì jù, á dáa kó o wá àwọn ọ̀rẹ́ míì tó ń lépa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì níti gidi. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.”​—Òwe 13:20.

MÁ ṢE IṢẸ́ ÀṢEJÙ

Jẹ́ kí ọ̀gá rẹ mọ ìwọ̀n iṣẹ́ tí agbára rẹ gbé àti pé àwọn nǹkan kan wà tó ṣe pàtàkì gan-an sí ẹ. Fi sọ́kàn pé kì í ṣe ohun tó burú tí èèyàn bá gba àyè ní ibi iṣẹ́ láti sinmi. Ìwé kan tó ń jẹ́ Work to Live sọ pé: “Àwọn tó máa ń ṣiṣẹ́ lákòókò iṣẹ́ tí wọ́n sì tún máa ń wá àyè láti sinmi tàbí kí wọ́n lọ gbafẹ́ ti wá mọ̀ pé àìsí níbiṣẹ́ àwọn kò sọ pé kí iṣẹ́ má ṣe.”

Owó ń wọlé dáadáa fún Gary tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, àmọ́ ó pinnu láti dín àkókò tó fi ń ṣiṣẹ́ kù. Ó sọ pé: “Èmi àti ìdílé mi jọ sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè mú ìgbé ayé wa rọrùn, lẹ́yìn náà, a wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Mo tún sọ fún ọgá mi pé àwọn ọjọ́ kan wà tí mi ò ní máa fi ṣiṣẹ́ lọ́sẹ̀, ó sì gbà bẹ́ẹ̀.”

WÁ ÀYÈ LÁTI WÀ PA PỌ̀ PẸ̀LÚ ÌDÍLÉ RẸ

Ó yẹ kí àwọn tọkọtaya máa wá àyè láti wà pa pọ̀, ó sì yẹ káwọn òbí máa wá àyè gbọ́ tàwọn ọmọ wọn. Torí náà, má ṣe fara wé àwọn ìdílé tí wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó kí wọ́n bàa lè yọrí ọlá nínú gbogbo nǹkan. Gary sọ pé: “Máa dìídì wá àyè lati sinmi, kó o sì pa àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.”

Má ṣe jẹ́ kí tẹlifíṣọ̀n, fóònù tàbí àwọn nǹkan míì gbà ẹ́ lọ́kàn nígbà tó o bá wà pẹ̀lú ìdílé rẹ. Ó kéré tán, ẹ máa jẹun pọ̀ lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́, kẹ́ ẹ sì jọ máa fi àkókò yẹn sọ̀rọ̀. Tí àwọn òbí bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, ara àwọn ọmọ á yá gágá, wọ́n á sì máa ṣe dáadáa ní ilé ìwé.

Ẹ máa lo àkókò oúnjẹ láti jọ sọ̀rọ̀

Ní báyìí, wá bi ara rẹ pé: ‘Báwo ni mo ṣe fẹ́ kí ayé mi rí? Báwo ni mo ṣe fẹ́ kí nǹkan rí fún ìdílé mi?’ Tó o bá fẹ́ láyọ̀, tó o sì fẹ́ gbé ayé ire, máa fi àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù sí ipò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé rẹ, èyí á fi hàn pé àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ló ń darí rẹ.