Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹyẹ Arctic Tern

Ẹyẹ Arctic Tern

NÍGBÀ kan, èrò àwọn èèyàn ni pé tí ẹyẹ arctic tern bá fò lọ fò bọ̀ láti Arctic sí Antarctica, ó máa ń gbà tó ẹgbẹ̀rún márùnlélọ́gbọ̀n ó lé ọgọ́rùn-ún méjì [35,200] kìlómítà. Àmọ́, ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé ó máa ń fò jìnnà gan-an jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Ẹyẹ arctic tern kì í fò lọ tààrà, Bó ṣe wà nínú àwòrán yìí

Ohun kékeré kan wà tí wọ́n máa ń fi sára àwọn ẹyẹ láti mọ bí wọ́n ṣe ń rìn jìnnà tó. Ìyẹn ló jẹ́ káwọn tó ń ṣèwádìí mọ̀ pé ní àlọ àti àbọ̀, àwọn ẹyẹ arctic tern kan máa ń fò jìnnà tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rùn-ún [90,000] kìlómítà. Kò sí ẹyẹ tàbí ẹranko míì tó ń rìn jìnnà tó bẹ́ẹ̀ láyé yìí. Ẹyẹ kan tiẹ̀ fò jìnnà tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ó dín mẹ́rin [96,000] kìlómítà! Kí nìdí tí wọ́n fi tún ìwádìí yìí ṣe?

Ibi yòówù kí àwọn ẹyẹ arctic tern ti gbéra, wọn kì í fò lọ tààrà. Bó ṣe wà nínú àwòrán yìí, ìrìn àjò orí Òkun Àtìláńtíìkì kò ṣe tààrà, ńṣe ló rí kọ́lọkòlọ. Kí nìdí tí ìrìn àjò àwọn ẹyẹ yìí kò fi ṣe tààràtà? Ìdí ni pé afẹ́fẹ́ tó wà lórí Òkun Àtìláńtíìkì ni wọ́n gbára lé bí wọ́n ṣe ń fò.

Láàárín nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ọdún tí àwọn ẹyẹ arctic tern máa ń lò láyé, àròpọ̀ ìrìn àjò wọn máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ́nù méjì ààbọ̀ kìlómítà. Ńṣe nìyẹn sì dà bí ìgbà tí èèyàn bá rìnrìn-àjò ẹ̀ẹ̀mẹta tàbí ẹ̀ẹ̀mẹrin lọ sínú òṣùpá! Ẹnì kan tó ṣèwádìí sọ pé: “Ohun àrà gbáà ló jẹ́ pé ẹyẹ kóńkóló yìí lè pitú tó báyìí.” Ìwé kan tó ń jẹ́ Life on Earth: A Natural History sọ pé: “Torí pé ọ̀pọ̀ àkókò ni ẹyẹ arctic tern fi ń fò, àkókò tí wọ́n fi ń rí ìmọ́lẹ̀ pọ̀ ju ti ẹ̀dá èyíkéyìí míì lọ.”