Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÀWỌN Ọ̀DỌ́

Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Àyípadà Bá Ṣẹlẹ̀

Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Àyípadà Bá Ṣẹlẹ̀

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

  • Dádì rẹ ríṣẹ́ sí ibòmíì, ó sì gba pé kẹ́ ẹ kó kúrò níbi tẹ́ ẹ̀ ń gbé báyìí.

  • Ọ̀rẹ́ rẹ fẹ́ kó lọ sí àdúgbò míì tó jìnnà.

  • Ẹ̀gbọ́n rẹ fẹ́ kó kúrò nílé torí pé ó fẹ́ ṣègbéyàwó.

Kí lo lè ṣe kí àwọn àyípadà yìí lè bá lára mu?

Igi tó bá lè fì sọ́tùn-ún fì sósì nígbà tí atẹ́gùn bá ń fẹ́, tí ìjì bá jà, igi náà lè máà wó. Bí àyípadà bá wáyé tí kò sì sí ohun tó o lè ṣe sí i, ohun tó kàn ni pé kó o mú kí àyípadà náà bá ẹ lára mu, bíi ti igi yẹn. Ká tó sọ ohun tó o lè ṣe, ó yẹ ká mọ nǹkan kan nípa àyípadà.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Àyípadà gbọ́dọ̀ wáyé. Bíbélì sọ ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwa èèyàn, ó ní: “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” (Oníwàásù 9:11) Bó pẹ́ bó yá, ohun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ lè ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo àwọn àyípadà náà ló máa ń burú. Àwọn àyípadà kan lè kọ́kọ́ dà bí ohun tó burú, àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó lè ṣe wá láǹfààní. Àwọn kan máa ń gbádùn ohun tí wọ́n ń ṣe déédéé, àmọ́ nǹkan máa ń nira fún wọn tí àyípadà bá wáyé, yálà àyípadà rere tàbí búburú.

Àyípadà máa ń mú kí nǹkan tojú sú àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà. Kí nìdí? Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Alex * sọ pé: “O ò tíì yanjú àyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ara rẹ, tí àwọn ohun míì tí o kò rò tẹ́lẹ̀ tún wá dá kún un.”

Ìdí míì rèé: Bí àyípadà bá dé bá àgbàlagbà, wọ́n máa ń ronú pa dà sẹ́yìn láti mọ bí wọ́n ṣe bójú tó o nígbà tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àmọ́ àwọn ọ̀dọ́ kò ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀.

O lè mú kí ipò náà bá ẹ lára mu. Èyí gba pé kó o fara mọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, kó o sì gbé e kúrò lọ́kàn. Nípa bẹ́ẹ̀ wàá lè fara da ipò tuntun tó o wà báyìí, wàá sì tún ronú nípa àǹfààní tó máa tìdí ẹ̀ yọ. Àwọn ọ̀dọ́ tó bá nírú èrò yìí kì í lo oògùn olóró tàbí mu ọtí àmujù láti fi pa ìrònú rẹ́.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Gba kámú. Ó dájú pé ó máa wù ẹ́ pé kí gbogbo nǹkan máa lọ bó o ṣe fẹ́, àmọ́ ìyẹn ò lè ṣeé ṣe. Torí pé bó pẹ́ bó yá, ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ kò ní jọ wà níbì kan náà mọ́, àwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àwọn àbúrò rẹ á kúrò nílé, ipò nǹkan sì lè mú kí ìdílé yín kó kúrò níbi tẹ́ ẹ̀ ń gbé, wàá sì fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ sílẹ̀. Dípò tí wàá fi jẹ́ kí àwọn nǹkan yìí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ, ó máa dáa kó o fara mọ́ bí nǹkan ṣe rí.—Ìlànà Bíbélì: Oníwàásù 7:10.

Iwájú ni kó o máa lọ. Tó o bá n ronú lórí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ńṣe lo máa dà bí ẹni tó ń wà mọ́tò lọ àmọ́ tó kàn tẹ́jú mọ́ gíláàsì tí wọ́n fi ń wò ẹ̀yìn. Kò burú tó bá ń wẹ̀yìn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ iwájú tó ń lọ ló yẹ kó gbájú mọ́. Nǹkan tó yẹ kéèyàn ṣe náà nìyẹn bí àyípadà bá ṣẹlẹ̀ láìrò tẹ́lẹ̀. Bí ọjọ́ iwájú ṣé máa dáa ni kó o máa rò. (Òwe 4:25) Bí àpẹẹrẹ, o lè bí ara rẹ pé kí ni nǹkan tó dáa tí mo lè ṣe ní oṣù kan tàbí oṣù mẹ́fà sí àkókò yìí?

Ohun tó dáa ni kó o máa rò. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Laura sọ pé: “Ọkàn téèyàn bá fi gbà àyípadà ló ṣe pàtàkì jù, torí náà ohun tó dáa nípa àyípadà náà ni kó o máa rò.” Ṣé o lè sọ àǹfààní kan tí ipò tuntun tó o wà mú wá?—Ìlànà Bíbélì: Oníwàásù 6:9.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Victoria rántí pé nígbà tí òun ṣì wà ní ọ̀dọ́, gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ òun ló kó lọ tán. Ó ní: “Àárò wọ́n sọ mí gan-an, ó ń sẹ́ mí bíi pé kí nǹkan ṣì rí bó ṣe máa ń rí tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí mo ronú pa dà sẹ́yìn, mo ṣàkíyèsí pé àsìkò yẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í jára nù. Mo wá rí i pé àyípadà gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ bá a ṣe ń dàgbà. Ìgbà yẹn náà ni mo wá rí i pé á dáa kí n bẹ̀rẹ̀ sí í yan àwọn tó wà nítòsí mi lọ́rẹ̀ẹ́.”—Ìlànà Bíbélì: Òwe 27:10.

Tó o bá n ronú lórí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ńṣe lo máa dà bí ẹni tó ń wà mọ́tò lọ àmọ́ tó kàn tẹ́jú mọ́ gíláàsì tí wọ́n fi ń wò ẹ̀yìn

Máa ran àwọn míì lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Ohun kan tó lè mára tù ẹ́ kúrò nínú ìṣòro rẹ ni pé kó o máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Anna tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé: “Bí mo ṣe ń dàgbà sí i, mo rí i pé inú mi máa ń dùn tí mo bá ń ran àwọn èèyàn tó ní irú ìṣòro tí mo ní lọ́wọ́ tàbí èyí tó tiẹ̀ le ju tèmi lọ!”

^ ìpínrọ̀ 11 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.