OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Ẹwà
Èrò tá a ní nípa ẹwà àti ìrísí wa ló máa pinnu bóyá a máa láyọ̀ tàbí a ò ní láyọ̀.
Kí nìdí tí ohun tó lẹ́wà fi máa ń wù wá?
Bí ọpọlọ àwa èèyàn ṣe máa ń dá ohun tó lẹ́wà mọ̀ ṣì jẹ́ àdììtú. Bíbélì náà kò sọ bó ṣe ń ṣẹlẹ̀, àmọ́ ó sọ ohun tó ń mú kí nǹkan tó lẹ́wà máa wù wá, ìyẹn ni pé: Ọlọ́run dá àwọn ànímọ́ rẹ̀ mọ́ àwa èèyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; Oníwàásù 3:11) Ọlọ́run tún dá ara wa lọ́nà àgbàyanu. Ìrísí wa yàtọ̀ síra, a sì lè ṣe onírúurú nǹkan. Ìdí nìyẹn tí olórin kan láyé ìgbàanì fi sọ pé: “Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.”—Sáàmù 139:14.
Lóde òní, àwọn iléeṣẹ́ aṣaralóge àti iléeṣẹ́ ìròyìn tí mú kí àwọn èèyàn ní èrò tí kò tọ̀nà nípa ẹwà àti ìrísí wọn. Ìwé kan tó ń jẹ́ Body Image, sọ pé àwọn èèyàn gbà pé ẹwà ṣe pàtàkì ju ìwà lọ. Téèyàn bá ṣáà ti lẹ́wà, àbùṣe bùṣe. Irú èrò kúkúrú yìí lè mú kí àwọn èèyàn fọwọ́ rọ́ ohun tó ṣe pàtàkì sẹ́yìn, ìyẹn bí a ṣe lè jẹ́ kí ìwà wa dáa si.—1 Sámúẹ́lì 16:7.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ti ki àṣejù bọ ọ̀rọ̀ ìrísí wọn
Bí àwọn kan ṣe ka ẹwà àti ìrísí wọn sí pàtàkì, bẹ́ẹ̀ náà láwọn obìnrin kan máa ń ṣí ibi ìkọ̀kọ̀ ara wọn sílẹ̀ láti fa ojú àwọn ọkùnrin mọ́ra. Ìwádìí tí àjọ American Psychological Association (APA) ṣe lọ́dún 2007 fi hàn pé ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n, Íńtánẹ́ẹ̀tì àtàwọn tó ń polówó ọjà ló máa ń lo àwọn obìnrin tó ṣí ara sílẹ̀ láti fa ojú àwọn èèyàn mọ́ra. Bíbélì là á mọ́lẹ̀ pé a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí èyí kó èèràn ràn wá, fún àǹfààní ara wa!—Kólósè 3:5, 6.
‘Kí ọ̀ṣọ́ yín má sì jẹ́ ti òde ara, ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù, èyí tí ó níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run.’—1 Pétérù 3:3, 4.
Kí nìdí tó fi mọ́gbọ́n dání pé ká má ṣe àṣejù?
Àwọn kan máa ń sọ pé, “Tó o bá lẹ́wà, fi ṣakọ!” Ìròyìn àjọ APA sọ pé, láwọn ibi tírú èrò yìí ti wọ́pọ̀, àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn ọmọbìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà gbà pé tí àwọn èèyàn bá ń yẹ́ ẹwà wọn sí, tí wọ́n sì kà wọ́n sí àrímáleèlọ, ìgbà yẹn ni wọ́n tó gbà pé àwọn dáa léèyàn. Irú èrò bẹ́ẹ̀ léwu púpọ̀. Kódà, èyí ti ṣàkóbá fún ìlera ọ̀pọ̀ èèyàn, ó ti mú kí àwọn kan soríkọ́, àwọn míì kórìíra ìrísí wọn, àwọn kan kì í jẹun dáadáa, àwọn míì kò si ka ara wọn kún ẹni tó lẹ́nu láwùjọ.
“Mú pákáǹleke kúrò ní ọkàn-àyà rẹ, kí o sì taari ìyọnu àjálù kúrò ní ẹran ara rẹ; nítorí pé asán ni ìgbà èwe àti ìgbà ọ̀ṣìngín nínú ìgbésí ayé.”—Oníwàásù 11:10.
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní èrò tó tọ́?
Bíbélì sọ pé “ìyèkooro èrò inú,” tàbí àròjinlẹ̀ gba pé kéèyàn mẹ̀tọ́mọ̀wà. (1 Tímótì 2:9) Bí àpẹẹrẹ: Ẹni tó bá mẹ̀tọ́mọ̀wà kì í fi ẹwà rẹ̀ ṣe fọ́rífọ́rí, ńṣe ló máa ń mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Wọ́n kì í fojú pa àwọn míì rẹ́, ìyẹn sì máa ń mú káwọn èèyàn gba ti wọn, kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé wọ́n á rí ojúure Ọlọ́run. (Míkà 6:8) Láfikún sí i, wọ́n máa ń ní ọ̀rẹ́ tòótọ́, wọ́n sì tún máa ń rí ọkọ tàbí aya tó máa bá wọn kalẹ̀, tí kì í ṣe ẹwà ojú lásán ló ń wá.
Abájọ tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú pé ká jẹ́ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà,” ìyẹn ni pé ká sapá láti ní ìwà rere. (1 Pétérù 3:3, 4) Ẹwà ojú máa ń ṣá, àmọ́ ìwà rere wa kì í kú. Kódà, a lè mú kó dára sí i! Òwe 16:31 sọ pé: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.” Torí náà, yálà a ti dàgbà tàbí a ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, tá a bá fi àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, a máa ní ẹwà tí kì í ṣá, a sì má ní iyì àti ìtẹ́lọ́rùn.
“Òòfà ẹwà lè jẹ́ èké, ẹwà ojú sì lè jẹ́ asán; ṣùgbọ́n obìnrin tí ó bẹ̀rù Jèhófà ni ẹni tí ó gba ìyìn fún ara rẹ̀.”—Òwe 31:30.