Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀWỌN ÀṢÀ TÓ LÈ ṢE Ẹ́ LÁǸFÀÀNÍ

1 Má Tan Ara Rẹ

1 Má Tan Ara Rẹ

Ó sábà máa ń wù wá láti ṣe gbogbo àtúnṣe tó yẹ nígbèésí ayé wa lẹ́ẹ̀kan náà. Nígbà míì, èèyàn lè sọ pé, ‘Lọ́sẹ̀ yìí, mi ò ní mu sìgá mọ́, mi ò ní ṣépè mọ́, mi ò ní pẹ́ kí n tó lọ sùn, màá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣeré ìmárale, màá máa jẹun gidi, màá sì máa pe àwọn òbí mi àgbà.’ Tó o bá gbìyànjú láti ṣe gbogbo àtúnṣe yìí lẹ́ẹ̀kan náà, ńṣe lo máa dà bí ẹni tó ń lé eku méjì, o ò wá ní rí ìkankan ṣe!

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.”Òwe 11:2.

Ẹni tó jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà máa ń mọ ohun tí agbára òun gbé. Ó mọ̀ pé ó ní ìwọ̀nba nǹkan tí òun lè fi àkókò, okun àti ohun ìní òun ṣe. Torí náà, dípò tí á fi máa fẹ́ láti ṣe gbogbo àtúnṣe yìí lẹ́ẹ̀kan náà, díẹ̀díẹ̀ ni á máa ṣe é.

Tó o bá gbìyànjú láti ṣe gbogbo àtúnṣe yìí lẹ́ẹ̀kan náà, ńṣe lo máa dà bí ẹni tó ń lé eku méjì, o ò wá ní rí ìkankan ṣe!

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Díẹ̀díẹ̀ ni kó o máa ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ. Àwọn àbá yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́:

  1. Wá ìwé méjì, kọ àwọn ìwà rere tó o fẹ́ máa hù sínú ọ̀kan, kó o sì kọ àwọn àṣà tí ò dáa tó o fẹ́ jáwọ́ nínú rẹ̀ sínú ìkejì. Kọ gbogbo ohun tó o fẹ́ ṣe lórí apá méjèèjì láìṣẹ́ ku ohunkóhun.

  2. Èyí tó o kọ́kọ́ fẹ́ ṣe ni kó o kọ ṣáájú nínú gbogbo rẹ̀.

  3. O lè kọ́kọ́ mú àṣà kan tàbí méjì nínú ìwé méjèèjì, ìyẹn sì ni kó o gbájú mọ́. Tó bá tún yá, mú méjì míì tí wàá tún ṣiṣẹ́ lé lórí.

Ohun tó máa jẹ́ kí àtúnṣe náà yára ni pé kó o fi àwọn àṣà tó dáa rọ́pò èyí tí kò dáa. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé àwòjù tẹlifíṣọ̀n wà lára àṣà tó o fẹ́ jáwọ́ nínú rẹ̀, tó sì tún wù ẹ́ láti máa wáyè fáwọn èèyàn rẹ, o lè pinnu pé: ‘Dípò kí n gba ìdí tẹlifíṣọ̀n lọ ní gbàrà tí mo délé, màá kúkú fóònù àwọn ọ̀rẹ́ tàbí àwọn ẹbí mi.’