JÍ! No. 4 2016 | Àwọn Àṣà Tó Lè Ṣe Ẹ́ Láǹfààní

Bó o fẹ́ bó o kọ̀, àṣà wa máa nípa lórí ìgbésí ayé wa bóyá lọ́nà tó dáa àbí tí kò dáa.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Àwọn Àṣà Tó Lè Ṣe Ẹ́ Láǹfààní

Rí i dájú pé àwọn àṣà rẹ ń ṣe ẹ́ láǹfààní dípò tá á fi kó bá ẹ.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

1 Má Tan Ara Rẹ

Kò ṣeé ṣe láti ní àwọn ìwà tó dáa, kó sì fi èyí tí kò dáa sílẹ̀ lóru mọ́jú. Wo bó o ṣe lè kọ́kọ́ mú èyí tó ṣe pàtàkì jù.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

2 Kíyè Sí Ohun Tó Ń Lọ Láyìíká Rẹ

Àwọn ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa ni kó wà láyìíká rẹ.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

3 Má Ṣe Jẹ́ Kó Sú Ẹ

Kódà tó bá nira fún ẹ láti ní àwọn àṣà tó dáa tàbí fi àwọn àṣà tí kò dáa sílẹ̀, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ!

Ṣé Bíbélì Fàyè Gbà Á Pé Kí Ọkùnrin Fẹ́ Ọkùnrin?

Ṣé ó kórìíra kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin? Àbí ó fàyè gba kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin?

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Àyípadà Bá Ṣẹlẹ̀

Ìyípadà gbọ́dọ̀ wáyé. Wo ohun tí àwọn kan ti ṣe láti fara dà á.

ILẸ̀ ÀTI ÀWỌN ÈÈYÀN

Ìbẹ̀wò sí Orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan

Àwọn èèyàn ìlú Kyrgyzstan kóni mọ́ra wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fúnni. Àwọn àṣà wo ní wọ́n máa ń dá nínú ọ̀pọ̀ ìdílé níbẹ̀?

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ẹwà

Àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n àtàwọn aṣaralóge máa ń jẹ́ kí àwọn èèyàn ní èrò tí kò tọ́ nípa ìrísí wọn.

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Kòkòrò Periodical Cicada Ṣe Ń Gbé Ìgbé Ayé Rẹ̀

Bí kòkòrò yìí ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ̀ máa ń yani lẹ́nu torí pé ẹ̀ẹ̀kan ni wọ́n máa ń fara hàn láàárín ọdún mẹ́tàlá sí ọdún mẹ́tàdínlógún, wọ́n á sì lo ọ̀sẹ̀ mélòó kan péré.

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Bí Ẹ Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Bíbá Ara Yín Jiyàn

Ṣé ìwọ àti ẹnì kejì rẹ máa ń jiyàn ní gbogbo ìgbà? Wo bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ran ìdílé yín lọ́wọ́.

Àwọn Ọ̀dọ́ Sọ Pé Ọlọ́run Wà Lóòótọ́

Àwọn ọ̀dọ́ kan sọ ohun tó jẹ́ kó dá wọn lójú pé Ẹlẹ́dàá kan wà lóòótọ́ nínu fídíò oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́ta yìí.