Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Irun Ara Ẹran Omi Tó Ń Jẹ́ Otter

Irun Ara Ẹran Omi Tó Ń Jẹ́ Otter

Ọ̀PỌ̀ ÀWỌN ẹranko inú omi sábà máa ń ní ọ̀rá lábẹ́ awọ wọn, èyí sì máa ń mú kí ara wọn móoru kí òtútù máa bàa tètè mú wọn. Àmọ́ ẹran omi tó ń jẹ́ otter yìí tún ní irun tó pọ̀ lára, èyí sì jẹ́ ohun míì tó máa ń jẹ́ kí ara rẹ̀ móoru.

Rò ó wò ná: Irun ara otter inú òkun yìí ṣù mọ́ra dáadáa ju ti àwọn ẹranko yòókù lọ. Tí ẹran omi yìí bá ń lúwẹ̀ẹ́, irun ara rẹ̀ máa ń fẹ́ atẹ́gùn sí i lára. Atẹ́gùn tó ń fẹ́ yìí ni kì í jẹ́ kí omi wọ̀ ọ́ lára, débi tí òtútù á fi mú un.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé ẹ̀kọ́ pọ̀ tá a lè rí kọ́ lára irun ara otter yìí. Nínú ìwádìí wọn, wọ́n lo oríṣiríṣi kóòtù tó ní irun lára tí àwọn irun náà sì ki ju ara wọn lọ. Àwọn olùṣèwádìí náà rí i pé, “bí àwọn irun tó wà lára àwọn kóòtù náà ṣe ki tó tí wọ́n sì gùn tó ni kì í jẹ́ kí omi wọ inú wọn.” Torí náà, irun ara otter inú òkun yìí wúlò gan-an, ó sì ń dáàbò bo ara rẹ̀.

Àwọn olùṣèwádìí gbà pé lọ́jọ́ kan, ìwádìí àwọn á yanjú, àwọn á sì ṣe àwọn aṣọ tí omi kò ní lè wọ inú rẹ̀. Èyí lè mú káwọn kan rò pé á dáa tí àwọn tó ń lúwẹ̀ẹ́ nínú òkun bá lè máa wọ aṣọ tó ní irun lára bíi ti otter inú òkun!

Kí lèrò rẹ? Ṣé irun ara otter inú òkun tó ń mú kí ara rẹ̀ móoru kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?