Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ | FAN YU

Onímọ̀ Nípa Ètò Orí Kọ̀ǹpútà Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́

Onímọ̀ Nípa Ètò Orí Kọ̀ǹpútà Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́

Ọ̀JỌ̀GBỌ́N FAN YU bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ìṣirò ní China Institute of Atomic Energy, tó wà nítòsí ìlú Beijing lórílẹ̀-èdè Ṣáínà. Ní gbogbo àkókò yẹn kò gbà pé Ọlọ́run wà, ó sì gbà pé ńṣe ni gbogbo ohun alààyè kàn ṣàdédé wà, bí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ṣe sọ. Àmọ́, ní báyìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yu ti wá gbà gbọ́ pé àwọn ohun abẹ̀mí ò kàn ṣàdèédé wà àti pé Ọlọ́run ló dá àwọn ohun alààyè. Ó ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fún àwọn akọ̀ròyìn Jí!

Jọ̀wọ́ sọ fún wa nípa bí wọ́n ṣe tọ́ ẹ dàgbà.

Ọdún 1959 ni wọ́n bí mi ni ìlú Fuzhou, lágbègbè Jiangxi lórílẹ̀-èdè Ṣáínà. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ, orílẹ̀-èdè náà wà nínú rúkèrúdò tó lékenkà tá a wá mọ̀ sí Ìyípadà Àṣà Ìbílẹ̀ báyìí. Ẹnjiníà ni bàbá mi, torí náà wọ́n ní kó ṣe ọ̀nà ojú irin kan gba aginjù kọjá. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni wọ́n máa ń wá wò wá. Nígbà yẹn, ọ̀dọ̀ ìyá mi ni mò ń gbé. Tíṣà ni wọ́n ní ilé ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ kan, ilé ìwé yẹn la sì ń gbé. Ní ọdún 1970, a kó lọ sí abúlé kan tó ń jẹ́ Liufang tó wà ní ìgbèríko Linchuan, nǹkan ò rọrùn níbẹ̀ rárá torí pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí oúnjẹ.

Ẹ̀sìn wo ni ìdílé yín ń ṣe?

Bàbá mi ò lẹ́sìn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò fẹ́ràn ìṣèlú. Ẹlẹ́sìn Búdà ni ìyá mi. Ohun tí wọ́n kọ́ mi ní ilé ìwé ni pé ńṣe ni àwọn ohun alààyè ṣàdédé wà. Mo sì gbà bẹ́ẹ̀, torí pé àwọn olùkọ́ mi ló kọ́ mi.

Kí nìdí tó o fi fẹ́ràn ìṣirò?

Mo fẹ́ràn ìṣirò torí pé ìṣirò máa ń jẹ́ kéèyàn ronú jinlẹ̀, kó sì mọ̀ bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ lóòótọ́. Ọdún 1976 ni Mao Tse-tung tó jẹ́ olórí àwọn tó ń fa wàhálà lórí ọ̀ràn ìyípadà náà kú, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí mo wọ yunifásítì. Ẹ̀kọ́ ìṣirò ni mo yàn láàyò. Lẹ́yìn tí mo gboyè ẹlẹ́ẹ̀kejì ní Yunifásítì, mo ríṣẹ́ síbì kan tí wọ́n ti ní kí n fi ìmọ̀ ìṣirò ṣèwádìí nípa ẹ̀rọ agbára átọ́míìkì.

Irú ìwé wo lo kọ́kọ́ gbà pé Bíbélì jẹ́?

Lọ́dún 1987, mo lọ sí Texas A&M University lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ sí i kí n lè gboyè ọ̀mọ̀wé. Mo gbọ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló gba Ọlọ́run gbọ́ ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n sì máa ń ka Bíbélì. Mo tún gbọ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì pọ̀ gan-an, torí náà mo rò pé ó yẹ kí n kà á.

Àwọn ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì bọ́gbọ́n mu gan-an. Àmọ́, mo ka àwọn ibì kan tí kò yè mi rárá, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí mi ò fi kà á mọ́.

Kí ló wá jẹ́ kó o nífẹ̀ẹ́ Bíbélì nígbà tó yá?

Ó kọ́kọ́ rú mi lójú pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó dá ohun gbogbo, torí náà mo pinnu pé màá ṣèwádìí sí i nípa rẹ̀

Lọ́dún 1990, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé mi, ó sì fi ohun tí Bíbélì sọ hàn mí, pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa fún àwa èèyàn. Obìnrin náà wá ṣètò pé kí tọkọtaya kan wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn náà, Liping ìyàwó mi náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ti fìgbà kan kọ́ àwọn ọmọ iléèwé girama ní ẹ̀kọ́ físíìsì lórílẹ̀-èdè Ṣáínà, òun náà sì gbà pé kò sí Ọlọ́run. A kẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan. Ó kọ́kọ́ rú mi lójú pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó dá ohun gbogbo, torí náà mo pinnu pé màá ṣèwádìí sí i nípa rẹ̀.

Báwo ló ṣe wá ṣèwádìí nípa rẹ̀?

Bí mo ṣe jẹ́ onímọ̀ ìṣirò ti jẹ́ kí n mọ bí wọ́n ṣe ń ṣírò ìgbà tó ṣeé ṣe káwọn nǹkan ṣẹlẹ̀. Ohun kan ni pé láìsí èròjà purotéènì, kò ṣeé ṣe fún èèyàn láti máa wà láàyè nìṣó. Èyí mú kí n ṣe ìṣirò kan láti mọ̀ bóyá ó ṣeé ṣe fún èèyàn láti pilẹ̀ èròjà purotéènì láìsí ọwọ́ ohunkóhun míì níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, èròjà purotéènì wà lára ohun tó ṣòro jù lọ láti ṣàlàyé nínú àwọn ohun abẹ̀mí àti pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èròjà purotéènì yìí ló wà nínú sẹ́ẹ̀lì ara àwọn ohun abẹ̀mí tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ wọnú ara wọn lọ́nà àrà. Gẹ́gẹ́ bí àwọn olùṣèwádìí míì ṣe sọ, mo wá rí i ní tòótọ́ pé kò ṣeé ṣe fún èèyàn láti pilẹ̀ èròjà purotéènì láìsí ọwọ́ ohunkóhun míì níbẹ̀! Síbẹ̀, mi ò tíì rí àlàyé kankan nínú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó lè sọ ohun tó ń pilẹ̀ àwọn èròjà purotéènì tó jẹ́ ohun àrà yìí, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ohun abẹ̀mí tí èròjà náà wà nínú rẹ̀. Èyí jẹ́ kí n gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà.

Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá?

Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo túbọ̀ ń rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì ti ní ìmúṣẹ. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa fi ìlànà Bíbélì sílò. Ó máa ń yà mí lẹ́nu pé, ‘Báwo ni àwọn tó kọ Bíbélì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ṣe lè kọ àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó ṣì wúlò fún àwọn èèyàn títí dòní?’ Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo wá gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì.

Kí ló mú kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Ẹlẹ́dàá wà lóòótọ́?

Bí mo ṣe ń rí àwọn ohun àgbàyanu tó wà láyé, ńṣe ló túbọ̀ ń dá mi lójú pé Ẹlẹ́dàá wà lóòótọ́. Ní báyìí, ètò orí kọ̀ǹpútà ni mò ń ṣe, ìyẹn Software Design, ó sì máa ń yà mí lẹ́nu bí ọpọlọ èèyàn ṣe lágbára gan-an ju kọ̀ǹpútà lọ. Bí àpẹẹrẹ, ohun ìyanu gbáà ni bí ọpọlọ wa ṣe ń dá ọ̀rọ̀ mọ̀. Ọ̀pọ̀ nínú wa ló máa ń tètè lóye ọ̀rọ̀, kódà kó jẹ́ ààbọ̀ ọ̀rọ̀, a máa ń mọ̀ tẹ́nì kan bá rẹ́rìn-ín, tó bá wúkọ́, tó bá kálòlò, tó bá fi ohùn ọ̀tọ̀ sọ̀rọ̀, tí ohùn rẹ̀ bá ń dùn bíi pé ó ń sọ̀rọ̀ nínú yàrá tó wà lófìfo, tó bá ń sọ̀rọ̀ níbi tí ariwo wà tàbí tí ohùn rẹ̀ kò bá já geere lórí fóònù. Lójú tiwa, a lè má fi bẹ́ẹ̀ ka èyí sí ohun bàbàrà, àmọ́ lójú àwọn tó ń ṣe ètò orí kọ̀ǹpútà, ohun àrà gbáà ló jẹ́. Síbẹ̀, kò sí bí ètò kọ̀ǹpútà tó lè dá ohùn èèyàn mọ̀ ṣe lágbára tó, bíńtín ni lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọpọlọ èèyàn.

Lára nǹkan tó mú kí ọpọlọ èèyàn lágbára gan-an ju kọ̀ǹpútà lọ ni pé ọpọlọ wa lè jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe rí lára, ó lè jẹ́ ká dá ìró ohùn mọ̀, títí kan bí ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣe ń sọ̀rọ̀. Ní báyìí, àwọn onímọ̀ nípa ètò orí kọ̀ǹpútà ń ṣe ìwádìí nípa bí wọ́n ṣe lè ṣe àwọn ètò orí kọ̀ǹpútà kan tí á máa dá ohùn àti ọ̀rọ̀ mọ̀ bíi ti ọpọlọ. Mo gbà pé bí wọ́n ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ìṣẹ̀dá Ọlọ́run.