Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ọkọ àti Aya?

Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ọkọ àti Aya?

Táwọn tọkọtaya bá lo ẹ̀rọ ìgbàlódé lọ́nà tó dáa, ó lè mú kí ìfẹ́ àárín wọn túbọ̀ lágbára. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń jẹ́ kí tọkọtaya bá ara wọn sọ̀rọ̀ lóòrèkóòrè, bí wọ́n ò tiẹ̀ sí nítòsí ara wọn.

Àmọ́, àwọn tọkọtaya kan máa ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé lọ́nà tí kò dáa, ìyẹn sì ti mú kí wọ́n . . .

  • má ṣe ráyè fún ara wọn mọ́.

  • máa gbé iṣẹ́ wálé láìjẹ́ pé ó pọn dandan.

  • máa fura sí ara wọn, kí wọ́n má sì fọkàn tán ara wọn mọ́.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

ÀKÓKÒ TẸ́ Ẹ FI WÀ PA PỌ̀

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Michael sọ pé: “Nígbà míì témi àtìyàwó mi bá wà pa pọ̀, kì í ráyè tèmi rárá, torí fóònù ló kàn máa ń tẹ̀ ní tiẹ̀, á sì máa sọ pé, ‘Mi ò tíì ráyè wo fóònù yìí látàárọ̀.’ ” Lórí ọ̀rọ̀ yìí, baálé ilé kan tó ń jẹ́ Jonathan sọ pé: “Ọkọ àtìyàwó lè máa gbé pọ̀ lóòótọ́, àmọ́ ó lè dà bíi pé ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń gbé.”

RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ọ̀rọ̀ àti ìpè tó ń wọlé sórí fóònù ẹ kì í jẹ́ kó o ráyè gbọ́ ti ọkọ tàbí ìyàwó ẹ?​—ÉFÉSÙ 5:33.

IṢẸ́

Iṣẹ́ àwọn kan máa ń gba pé kí wọ́n máa gba ìpè àti lẹ́tà lórí fóònù wọn lóòrèkóòrè, kódà lẹ́yìn tí wọ́n ti kúrò níbiṣẹ́. Àmọ́, ó ṣì ṣòro fáwọn kan tí iṣẹ́ wọn ò le tó bẹ́ẹ̀ láti jẹ́ kọ́rọ̀ iṣẹ́ wọn mọ síbi iṣẹ́. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Lee sọ pé: “Nígbà tí mo bá wà pẹ̀lú ìyàwó mi, ó ti mọ́ mi lára kí n máa wo gbogbo ọ̀rọ̀ àti lẹ́tà tó ń wọlé sórí fóònù mi láti ibiṣẹ́.” Ìyàwó ilé kan tó ń jẹ́ Joy sọ pé: “Àtilé ni mo ti ń ṣiṣẹ́, torí náà, ó máa ń ṣòro fún mi láti ṣíwọ́ lásìkò. Téèyàn ò bá ṣọ́ra, kò ní ráyè fún ẹnì kejì ẹ̀.”

RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣé o máa ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa tí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀?​—LÚÙKÙ 8:18.

JẸ́ OLÓÒÓTỌ́

Ìwádìí kan fi hàn pé àwọn kan máa ń fura sí ohun tí ẹnì kejì wọn ń ṣe lórí ìkànnì àjọlò, ìyẹn sì máa ń dá ìjà sílẹ̀ láàárín wọn lọ́pọ̀ ìgbà. Àwọn kan jẹ́wọ́ pé àwọn kì í jẹ́ kẹ́nì kejì àwọn róhun táwọn ń gbé sórí ìkànnì.

Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ewu púpọ̀ ló wà lórí ìkànnì àjọlò, ó sì lè mú káwọn tọkọtaya tètè ṣe ìṣekúṣe. Abájọ táwọn agbẹjọ́rò tó ń rí sọ́rọ̀ ìkọ̀sílẹ̀ fi sọ pé wàhálà tí ìkannì àjọlò ń dá sílẹ̀ láàárín àwọn tọkọtaya kì í ṣe kékeré, ìyẹn ló sì fà á tí ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya fi ń kọ ara wọn sílẹ̀ lóde òní.

RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣó o máa ń fàwọn ọ̀rọ̀ tó o fi ń ránṣẹ́ sẹ́ni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹ pa mọ́, kí ẹnì kejì ẹ má bàa rí i?​—ÒWE 4:23.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

FI OHUN TÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ SÍPÒ ÀKỌ́KỌ́

Tẹ́nì kan bá wà tí kì í fi bẹ́ẹ̀ jẹun, ara onítọ̀hún ò ní le dáadáa. Bọ́rọ̀ tọkọtaya ṣe rí náà nìyẹn, tí wọn ò bá wáyè láti máa gbọ́ ti ara wọn, wọ́n máa níṣòro.​—Éfésù 5:​28, 29.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”​—FÍLÍPÌ 1:10.

Kí ẹ̀yin ọkọ àti aya jọ jíròrò àwọn tó yẹ kẹ́ ẹ ṣe nínú àwọn àbá yìí tàbí kẹ́ ẹ kọ èyí tẹ́yin fúnra yín ronú kàn, tí kò ní jẹ́ kí ẹ̀rọ ìgbàlódé ba àárín yín jẹ́.

  • A fẹ́ jọ máa jẹun pọ̀, ó kéré tán ẹ̀ẹ̀kan lójúmọ́

  • A fẹ́ ya àwọn àsìkò kan sọ́tọ̀ tá a máa fi wà pa pọ̀, tá ò sì ní lo fóònù tàbí kọ̀ǹpútà wa

  • A fẹ́ ṣètò àwọn ọjọ́ kan táwa méjèèjì á jọ máa jáde láti gbádùn ara wa

  • A ò ní máa fi fóònù wa sí tòsí tá a bá ti fẹ́ sùn lálẹ́

  • A fẹ́ máa pa fóònù tàbí kọ̀ǹpútà wa fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lójúmọ́, ká lè bára wa sọ̀rọ̀ láìsí ìdíwọ́

  • A fẹ́ yan àkókò kan lójúmọ́ tá ò ni máa tan Íńtánẹ́ẹ̀tì wa