Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JÍ! No. 2 2021 | Ewu Wo Ló Wà Nínú Ẹ̀rọ Ìgbàlóde?

Ewu wo ló wà nínú ẹ̀rọ ìgbàlódé? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ẹ̀rọ ìgbàlódé wúlò gan-an, òótọ́ sì ni. Àmọ́, ẹ̀rọ ìgbàlódé lè máa dọ́gbọ́n pani lára, téèyàn ò sì ní tètè mọ̀.

Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ìwọ Àtàwọn Ọ̀rẹ́ Ẹ?

Ẹ̀rọ ìgbàlódé lè jẹ́ kó o máa bá àwọn ọ̀rẹ́ ẹ sọ̀rọ̀, kẹ́ ẹ sì túbọ̀ máa ṣe nǹkan pa pọ̀.

Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ọmọ Ẹ?

Àwọn ọmọdé mọ ẹrọ ìgbàlódé lò dáadáa, àmọ́ ó yẹ kí wọ́n mọ bá a ṣe ń lò ó láìséwu.

Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ọkọ àti Aya?

Tí tọkọtaya bá ń lo ẹ̀ro ìgbàlóde lọ́nà tó dáa, ó lè mú kí ìfẹ́ àárín wọn túbọ̀ lágbára.

Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlóde Lè Ṣe fún Ìrònú Ẹ?

Kò ní jẹ́ kó o pọkàn pọ̀ tó o bá ń kàwé, kò ní jẹ́ kó o pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ kan láìyà sídìí nǹkan míì, á sì jẹ́ kí nǹkan tètè máa sú ẹ tó o bá dá wà. Àwọn nǹkan mẹ́ta táá jẹ́ kó o túbọ̀ máa ronu dáadáa.

Kẹ́kọ̀ọ́ Sí I Lórí Ìkànnì JW.ORG

Ẹ̀kọ́ wo ló wù ẹ́ láti kọ́?

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

Wo àwọn ọ̀nà tí ẹ̀rọ ìgbàlódé lè gbà dọ́gbọ́n ṣàkóbá fún ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ, ìdílé ẹ àti ìrònú ẹ.