Yorùbá
Ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/102020044/univ/art/102020044_univ_sqr_xl.jpg
g20 No. 2 ojú ìwé 2

Ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀

Ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀

Oríṣiríṣi nǹkan ló lè fìyà jẹni láyé, a ò sì ríbi yẹ̀ ẹ́ sí. Ó lè jẹ́ ogun, àìsàn, jàǹbá tàbí àwọn àjálù bí àkúnya omi àti ìjì líle.

Àwọn èèyàn fẹ́ mọ ìdí tá a fi ń jìyà.

  • Àwọn kan sọ pé wọ́n kádàrá ìyà mọ́ wa ni, kò sì sóhun tẹ́nì kankan lè ṣe nípa ẹ̀.

  • Àwọn míì gbà gbọ́ pé tẹ́nì kan bá ń jìyà, á jẹ́ nítorí pé ẹni náà ti ṣe ohun tí kò dáa láyé yìí tàbí nígbà tó kọ́kọ́ wáyé.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ mọ ìdí tí ìyà fi ń jẹ aráyé, àmọ́ wọn ò rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn.