Yorùbá
JÍ! Nǹkan Ń Gbówó Lórí!—Ọgbọ́n Wo Lo Lè Dá Sí I?
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/g/202511/YR/pt/g_YR_202511_lg.jpg
g25 No. 1

JÍ! No. 1 2025 | Nǹkan Ń Gbówó Lórí!—Ọgbọ́n Wo Lo Lè Dá Sí I?

Ṣé ò ń kọ́kàn sókè torí báwọn nǹkan ṣe ń gbówó lórí? Ṣé oríṣiríṣi iṣẹ́ lò ń rọ́ mọ́ra kó o ṣáà lè rọ́wọ́ mú lọ sẹ́nu? Ṣé iṣẹ́ ẹ ti wá ń gba gbogbo àkókò ẹ débi pé o kì í fi bẹ́ẹ̀ wà pẹ̀lú ìdílé ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwé yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wàá rí àwọn nǹkan tó o lè ṣe tó ò fi ní máa kọ́kàn sókè ju bó ṣe yẹ lọ àtàwọn nǹkan táá jẹ́ kó o máa láyọ̀ bí nǹkan ò tiẹ̀ rọrùn. Nínú àpilẹ̀kọ tó kẹ́yìn, wàá rí àwọn nǹkan rere tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe táá mú kí nǹkan dáa sí i lọ́jọ́ iwájú àti báwọn nǹkan yẹn ṣe lè fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ báyìí.

 

Gbà Pé Ńṣe Ni Nǹkan Á Máa Wọ́n Sí I

Tó gbà pé ńṣe ni nǹkan á máa wọ́n sí i, ìyẹn ò ní jẹ́ kó o máa kọ́kàn sókè ju bó ṣe yẹ lọ.

Máa Fọgbọ́n Náwó

Wo àwọn nǹkan márùn-ún tó o lè ṣe kó o lè máa ṣọ́wó ná.

Ní Ìtẹ́lọ́rùn

Wàá rí bó o ṣe lè máa láyọ̀ bó ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ lówó.

Máa Ṣoore

Tó o bá ń ṣoore fáwọn èèyàn, báwo nìyẹn ṣe lè jẹ́ kó o máa láyọ̀ bí àtijẹ àtimu ò bá tiẹ̀ rọrùn fún ẹ?

Gbà Pé Nǹkan Ṣì Máa Dáa

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa ṣe àwọn nǹkan tó dáa fún wa lọ́jọ́ iwájú. Ìrètí yìí máa ń tù wá nínú gan-an bí nǹkan ò tiẹ̀ rọrùn báyìí.

Kẹ́kọ̀ọ́ Sí I

Bí nǹkan tiẹ̀ ń gbówó lórí, Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa máa kọ́kàn sókè ju bó ṣe yẹ lọ. Bíbélì lè ran ìwọ náà lọ́wọ́.