Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | Ẹ̀BÙN WO LÓ JU GBOGBO Ẹ̀BÙN LỌ?

“Ẹ̀bùn Tó Dáa Jù Tí Mo Rí Gbà Nìyí”

“Ẹ̀bùn Tó Dáa Jù Tí Mo Rí Gbà Nìyí”

Ọ̀rọ̀ tí ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13] sọ nìyẹn nígbà tí wọ́n fún un ní ọmọ ajá kan. Obìnrin oníṣòwò kan tó rí ṣe dáadáa sọ pé kọ̀ǹpútà tí bàbá òun fún òun nígbà tóun wá níléèwé gíga lẹ̀bùn tó tún ayé òun ṣe. Ọkọ kan tí kò tíì pẹ́ tó ṣègbéyàwó sọ pé káàdì tí ìyàwó òun fọwọ́ ara rẹ̀ ṣe ní àyájọ́ ọdún kan ìgbéyàwó àwọn ni ẹ̀bùn tó dáa jù tí òun tíì rí gbà.

Ọdọọdún làwọn èèyàn ń lo àkókò àti okun wọn láti fi wá ẹ̀bùn tó “dáa jù” tí wọ́n lè fún ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí wọn nígbà àjọyọ̀ pàtàkì. Ọ̀pọ̀ ló sì máa ń fẹ́ láti gbọ́ irú àwọn ọ̀rọ̀ tá a sọ lókè yìí. Ìwọ ńkọ́? Ṣé wàá fẹ́ gba ẹ̀bùn tàbí kó o fúnni lẹ́bùn tẹ́ni tó o fún á mọyì tọkàntọkàn?

Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń tuni lára lóòótọ́, àmọ́ kì í ṣe torí pé ẹni tá a fún lẹ́bùn gbà á tayọ̀tayọ̀ nìkan ni, bí kò ṣe bó ṣe máa ń rí lára ẹni tó fúnni lẹ́bùn náà. Àbájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Bẹ́ẹ̀ ni, tẹ́ni tá a fún lẹ́bùn bá mọyì ẹ̀bùn tó gbà gan-an, ayọ̀ ẹni tó fúnni lẹ́bùn máa túbọ̀ pọ̀ sí i.

Kí lo lè ṣe kí ẹ̀bùn tó o fúnni lè mú kí ìwọ àti ẹni tó o fún ní ayọ̀ tòótọ́? Tó bá sì jẹ́ pé kò ṣeé ṣe fún ẹ láti fúnyàn lẹ́bùn tó “dáa jù,” kí lo lè ṣe káwọn èèyàn lè mọyì ohun tó o bá fún wọn dáadáa?