Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìràpadà ni ẹ̀bùn tó dáa ju gbogbo ẹ̀bùn lọ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tó sì mú kí ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | Ẹ̀BÙN WO LÓ JU GBOGBO Ẹ̀BÙN LỌ?

Kí Ni Ẹ̀bùn Tó Dáa Ju Gbogbo Ẹ̀bùn Lọ?

Kí Ni Ẹ̀bùn Tó Dáa Ju Gbogbo Ẹ̀bùn Lọ?

“Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè, nítorí a máa sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá.” (Jákọ́bù 1:17) Ẹsẹ Bíbélì yẹn ń sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà Ọlọ́run, Baba wa ọ̀run ṣe jẹ́ ọ̀làwọ́ tó. Síbẹ̀, nínú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ti fún aráyé, ọ̀kan wà níbẹ̀ tó dáa ju gbogbo èyí tó kù lọ. Kí ni ẹ̀bùn náà? Ọ̀rọ̀ Jésù kan tá a mọ̀ dáadáa tó wà nínú Jòhánù 3:16 sọ pé: “Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”

Ẹ̀bùn náà ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run, òun ni ẹ̀bùn tó ta yọ jù lọ tí gbogbo wa rí gbà, torí òun ló jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀, ọjọ́ ogbó àti ikú. (Sáàmù 51:5; Jòhánù 8:34) Kò sí bá a ṣe lè gbìyànjú tó, kò sí ohun tá a lè ṣe fúnra wa láti gbara wa sílẹ̀ nínú ìdè yìí. Àmọ́ torí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó pèsè ohun tá a nílò ká lè bọ́. Bí Jèhófà ṣe pèsè Jésù Kristi, Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fún wa gẹgẹ bí ìràpadà ti mú káwọn tó bá jẹ́ onígbọràn nírètí láti wà láàyè títí láé. Ṣùgbọ́n kí ni ìràpadà? Kí nìdí tá a fi nílò rẹ̀? Ọ̀nà wo ló sì lè gbà ràn wá lọ́wọ́?

Ìràpadà ni ohun kan téèyàn san láti gba ohun tó ti sọnù pa dà tàbí láti gbani kúrò nínú ìdè. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà láìní ẹ̀ṣẹ̀, kí wọ́n sì máa gbádùn ayé wọn títí láé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé pẹ̀lú àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28) Ó bani nínú jẹ́ pé wọ́n gbé gbogbo ìyẹn sọnù nígbà tí wọ́n yàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀. Kí wá ni àbájáde rẹ̀? Bíbélì dáhùn pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 5:12) Dípò táwa àtọmọdọ́mọ Ádámù á fi jogún ìwàláàyè pípé lára rẹ̀, ńṣe ló tì wá sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.

Lórí ọ̀rọ̀ ìràpadà, ohun tá a san gbọ́dọ̀ dọ́gba pẹ̀lú ohun tó sọnù. Nígbà tí Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ó dẹ́ṣẹ̀, àbájáde rẹ̀ sì ni pé kì í ṣe ẹni pípé mọ́, ó sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀. Bíbélì sì jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tó ṣe yẹn ló mú káwa àtọmọdọ́mọ Ádámù máa dẹ́ṣẹ̀ ká sì máa kú. Ìyẹn ló tún mú kó gba pé kẹ́ni pípé míì fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀. Jésù ló wá fẹ̀mí rẹ̀ rúbọ ká lè bọ́ nínú ìdè yìí. (Róòmù 5:19; Éfésù 1:7) Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ló mú kó rà wá pa dà, èyí ló mú kó ṣeé ṣe fún aráyé láti nírètí pé a máa gbádùn nǹkan tí Ádámù gbé sọnù, ìyẹn ìwàláàyè títí láé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé.​—Ìṣípayá 21:3-5.

Bá a ṣe wá rí ohun tí ìràpadà náà ṣe fún wa, kò sí iyèméjì pé ẹ̀bùn ìràpadà tí Ọlọ́run fún wa, tó mú ká nírètí ìyè àìnípẹ̀kun, ni ẹ̀bùn tó dáa ju gbogbo ẹ̀bùn lọ. Ká lè mọyì bó ṣe jẹ́ “ọrẹ pípé” tó, ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe tan mọ́ àwọn kókó tó jẹ́ ká mọ bí ẹ̀bùn kan ṣe níye lórí tó, bá a ṣe jíròrò ní àkòrí tó ṣáájú.

Ohun tó wù wá. Kì í wu àwa èèyàn láti kú, bí Ọlọ́run ṣe dá a mọ́ wa nìyẹn. (Oníwàásù 3:11) Torí pé kò sóhun tá a lè dá ṣe láti mú ikú kúrò, ìràpadà yẹn ló ràn wá lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé: “Nítorí owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.”​—Róòmù 6:23.

Ohun tá a fẹ́. Àwa èèyàn kò lè pèsè ìràpadà yẹn. Bíbélì sọ pé: “Iye owó ìtúnràpadà ọkàn wọn ṣe iyebíye tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi jẹ́ pé ó ti kásẹ̀ nílẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sáàmù 49:8) Torí náà, a nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run lójú méjèèjì ká lè bọ́ nínú ìdè ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Àmọ́ “nípasẹ̀ ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà tí Kristi Jésù san,” Ọlọ́run pèsè ohun tá a nílò gẹ́lẹ́.—Róòmù 3:23, 24.

Ó bọ́ sásìkò gẹ́lẹ́. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé: “Nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:8) Torí a rí ìràpadà náà gbà “nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀,” èyí jẹ́ ká rí bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó láìka pé a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. Ó sì tún jẹ́ ká máa retí ọ̀pọ̀ nǹkan lọ́jọ́ iwájú bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ṣì ní láti máa fara da èrè ẹ̀ṣẹ̀.

Ó fi hàn pé Ọlọ́run ní èrò tó dáa sí wa. Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó sún Ọlọ́run láti fi Ọmọ rẹ̀ rúbọ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà, ó ní: “Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀. Ìfẹ́ náà jẹ́ lọ́nà yìí, kì í ṣe pé àwa ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, bí kò ṣe pé òun nífẹ̀ẹ́ wa.”​—1 Jòhánù 4:9, 10.

Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọyì ẹ̀bùn tó dáa ju gbogbo ẹ̀bùn yìí? Rántí ohun tí Jésù sọ nínú Jòhánù 3:16 pé àwọn tó bá ń “lo ìgbàgbọ́” nínú òun nìkan ló máa rí ìgbàlà. Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú Bíbélì, ìgbàgbọ́ ni “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí.” (Hébérù 11:1) Ká lè ní ìdánilójú yẹn, a nílò ìmọ̀ tó pé. Torí náà, a rọ̀ ẹ́ pé kó o fara balẹ̀ kọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Olùfúnni ní “ọrẹ pípé” yìí, kó o sì mọ ohun tó o gbọ́dọ̀ ṣe kó o lè gbádùnìyè àìnípẹ̀kun tí ìràpadà Jésù ti mú kó ṣeé ṣe fún wa.

O lè kọ́ nípa gbogbo èyí tó o bá ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣàlàyé nípa wọn lórí ìkànnì www.jw.org/yo. Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó dá wa lójú pé bó o ṣe ń kọ́ nípa ẹ̀bùn tó dáa jù tó o sì ń jàǹfààní nínú rẹ̀, á sún ẹ láti fayọ̀ sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!”​—Róòmù 7:25.