Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Jésù Ṣe Rí Gan-an?

Báwo Ni Jésù Ṣe Rí Gan-an?

Kò sẹ́nì kankan tó rí fọ́tò Jésù rí. Jésù ò ya fọ́tò rí, kò sì dúró kí wọ́n gbẹ́ ère rẹ̀. Síbẹ̀, ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń yàwòrán Jésù.

Kò sí àní-àní pé àwọn ayàwòrán yìí kò mọ bí Jésù ṣe rí gan-an. Ohun tí wọ́n fi ń pinnu bí wọ́n ṣe máa yàwòrán Jésù ni, àṣà ìbílẹ̀, ẹ̀sìn àtohun tí ẹni tó fẹ́ yàwòrán fẹ́. Síbẹ̀, àwòrán tí wọ́n ń yà lè mú káwọn èèyàn ní èrò tí kò tọ́ nípa Jésù àtàwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Àwọn kan máa ń yàwòrán Jésù bí ẹni tí kò lókun nínú, tí irun orí ẹ̀ gùn, tó ní irùngbọ̀n yẹ́úkẹ́, tójú ẹ̀ sì máa ń le. Àwọn míì máa ń yàwòrán Jésù bí ẹni tó ní agbára àràmàǹdà, tó wà nínú ìmọ́lẹ̀ ògo tàbí ẹni tí kì í fẹ́ kẹ́ni kankan sún mọ́ òun. Ṣẹ́ àwọn àwòrán yìí sọ irú ẹni tí Jésù jẹ́ lóòótọ́? Báwo la ṣe lè mọ bí Jésù ṣe rí gan-an? Ọ̀nà kan ni pé ká wo àwọn gbólóhùn mélòó kan nínú Bíbélì, tó máa jẹ́ ká lóye díẹ̀ nípa ìrísí Jésù. Á sì ràn wá lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ́ nípa rẹ̀.

“ÌWỌ TI PÈSÈ ARA KAN FÚN MI”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà tí Jésù ń ṣe ìrìbọmi ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nínú àdúrà tó gbà sí Baba rẹ̀. (Hébérù 10:5; Mátíù 3:​13-17) Báwo ni ara yẹn ṣe rí? Ní nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ọdún ṣáájú àkókò yìí, áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún Màríà pé: “Ìwọ yóò lóyún nínú ilé ọlẹ̀ rẹ, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, . . . Ọmọ Ọlọ́run.” (Lúùkù 1:​31, 35) Torí náà, ẹni pípé ni Jésù, bí Ádámù ṣe rí nígbà tí Ọlọ́run dá a. (Lúùkù 3:38; 1 Kọ́ríńtì 15:45) Ó dájú pé Jésù ò lè ní àbùkù kankan lára, ó sì ṣeé ṣe kí ìrísí rẹ̀ jọ ti Màríà ìyá rẹ̀ tó jẹ́ Júù.

Jésù náà dá irùngbọ̀n sí gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn Júù, àmọ́ àṣà àwọn ará Róòmù kò fàyè gba dídá irùngbọ̀n sí. Ẹni iyì ni àwọn Júù ka ẹni tó bá dá irùngbọ̀n sí, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn; irùngbọ̀n náà kì í gùn, ó sì máa ń ṣe rẹ́mú-rẹ́mú. Kò sí àní-àní pé Jésù á máa gé irun orí rẹ̀ àti ti àgbọ̀n rẹ̀ déédéé. Kìkì àwọn tí wọ́n jẹ́ Násírì, irú bí Sámúsìnì, nìkan ni kì í gé irun wọn.​—Númérì 6:5; Àwọn Onídàájọ́ 13:5.

Ọ̀pọ̀ ọdún ni Jésù fi ṣe iṣẹ́ káfíńtà, bẹ́ẹ̀ sì rèé kò sí àwọn ẹ̀rọ tó lè múṣẹ́ rọrùn bíi tòde òní nígbà yẹn. (Máàkù 6:3) Torí náà, ó ṣeé ṣe kí Jésù lókun nínú dáadáa. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó dá nìkan lé “gbogbo àwọn tí wọ́n ní àgùntàn àti màlúù jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì, ó sì da ẹyọ owó àwọn olùpààrọ̀ owó sílẹ̀, ó sì sojú àwọn tábìlì wọn dé.” (Jòhánù 2:​14-17) Ẹni tó bá lókun nínú tó sì lágbára ló lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Jésù lo ara tí Ọlọ́run ti pèsè fún un láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́, ó sọ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Ó gba kéèyàn lókun nínú dáadáa, kó tó lè fẹsẹ̀ rìnrìn-àjò jákèjádò ilẹ̀ Palẹ́sínì láti wàásù ìhìn rere.

“Ẹ WÁ SỌ́DỌ̀ MI, . . . ÈMI YÓÒ SÌ TÙ YÍN LÁRA”

Bí ojú Jésù ṣe tutù pẹ̀sẹ̀ tó sì fani mọ́ra ló máa mú kó rọrùn fún àwọn “tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn” láti nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Mátíù 11:28-30) Bó ṣe jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ àti onínúure máa mú kó lè mára tu àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Àwọn ọmọdé pàápàá fẹ́ sún mọ́ Jésù, torí Bíbélì sọ pé: “Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn.”​—Máàkù 10:13-16.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù jẹ̀rora kó tó kú, síbẹ̀ kì í ṣẹni tó máa ń kárí sọ. Bí àpẹẹrẹ, ó mú kí àríyá tí wọ́n ṣe níbi ìgbéyàwó kan ní Kánàtúbọ̀ lárinrin nígbà tó sọ omi di ọtí wáìnì. (Jòhánù 2:1-11) Níbi àpéjọ míì, ó kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ tí wọn ò ní gbà gbé.​—Mátíù​9:9-13; Jòhánù 12:1-8.

Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé ọ̀nà tí Jésù gbà ṣe iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ mú káwọn èèyàn nírètí ìwàláàyè títí láé, èyí sì máa ń fúnni láyọ̀. (Jòhánù 11:25, 26; 17:3) Nígbà tí àádọ́rin [70] àwọn ọmọ ẹ̀yìn ròyìn àṣeyọrí tí wọ́n ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù fún un, Jésù ní “ayọ̀ púpọ̀,” ó sì sọ pé: “Ẹ yọ̀ nítorí pé a ti ṣàkọọ́lẹ̀ orúkọ yín ní ọ̀run.”​—Lúùkù 10:​20, 21.

“ÀMỌ́ ṢÁ O, Ẹ̀YIN KÒ NÍ JẸ́ BẸ́Ẹ̀”

Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn nígbà ayé Jésù dá ọgbọ́n táá mú kí wọ́n máa gbayì lójú àwọn èèyàn, tí wọ́n á sì máa jẹ ọ̀gá lé wọn lórí. (Númérì 15:​38-40; Mátíù 23:​5-7) Jésù ò fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dà bí i wọn, torí náà ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe “jẹ olúwa” lé àwọn míì lórí. (Lúùkù 22:​25, 26) Ní kúkúrú, Jésù kìlọ̀ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n ń fẹ́ láti máa rìn káàkiri nínú aṣọ ńlá, tí wọ́n sì ń fẹ́ ìkíni ní àwọn ibi ọjà.”​—Máàkù 12:38.

Ìwà Jésù yàtọ̀ pátápátá sí èyí, ó máa ń dàpọ̀ mọ́ àwọn èrò débí pé, ó máa ń ṣòro láti dá a mọ̀ nígbà míì. (Jòhánù 7:10, 11) Kódà, kò dá yàtọ̀ láàárín àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Ìdí nìyẹn tí Júdásì fi fún àwọn jàǹdùkú tó wá mú Jésù ní “àmì” pé ẹni tí òun bá fẹnu kò lẹ́nu ni kí wọ́n mú.​—Máàkù 14:44, 45.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jésù, síbẹ̀ ohun tó dájú ni pé kì í ṣe bí Jésù ṣe rí ni ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe máa ń yàwòrán rẹ̀. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni ipò tí Jésù wà báyìí, kì í ṣe ìrísí rẹ̀ gan-an nígbà tó wà láyé.

“NÍ ÌGBÀ DÍẸ̀ SÍ I, AYÉ KÌ YÓÒ SÌ RÍ MI MỌ́”

Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn tí Jésù sọ̀rọ̀ yìí ló kú tí wọ́n sì sin ín. (Jòhánù 14:19) Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ “gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Ní ọjọ́ kẹta, Ọlọ́run jí i dìde “nínú ẹ̀mí” ó sì “yọ̀ǹda fún un láti fara hàn kedere” fún àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (1 Pétérù 3:18; Ìṣe 10:40) Báwo ni Jésù ṣe rí nígbà tó fara han àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà yẹn? Ó ṣeé ṣe kí ìrísí rẹ̀ yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀, torí pé àwọn tó sún mọ́ ọn dáadáa pàápàá kò dá a mọ̀ nígbà tí wọ́n rí i. Màríà Magidalénì rò pé olùṣọ́gbà ni; àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó ń rìn lọ lọ́nà ìlú Ẹ́máọ́sì sì rò pé àjèjì ni.​—Lúùkù 24:​13-18; Jòhánù 20:​1, 14, 15.

Àwòrán wo ló yẹ ká ní lọ́kàn nípa Jésù lóde òní? Ní nǹkan bí ọgọ́ta [60] ọdún lẹ́yìn tí Jésù kú, àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran kan nípa Jésù. Jòhánù kò rí ẹnì kan tó ń kú lọ lórí àgbélébùú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rí “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa,” ìyẹn Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Láìpẹ́, Jésù máa pa àwọn ọ̀tá Ọlọ́run run, ìyẹn àwọn ẹ̀mí èṣù àtàwọn èèyàn burúkú, á sì mú ìbùkún tí kò lópin wá fún aráyé.​—Ìṣípayá 19:16; 21:3, 4.