Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìlú Praslin, lórílẹ̀-èdè Seychelles, níbi tí Ọ̀gágun Gordon ti rí ibi tó pè ní ọgbà Édẹ́nì lọ́dún 1881

Ṣé Ayé Máa Di Párádísè Lóòótọ́?

Ṣé Ayé Máa Di Párádísè Lóòótọ́?

Párádísè! A rí ìwé pẹlẹbẹ kan tí wọ́n ya àwòrán mèremère sí. Àwòrán náà lẹ́wà débí pé ó wù wá láti rìnrìn àjò lọ sọ́nà jíjìn níbi tí “Párádísè” wà, ká lọ gbafẹ́, ká sì gbàgbé gbogbo ìṣòro wa. Àmọ́, tá a bá lọ̀ tá a sì pa dà dé, a tún máa pa dà wá bá àwọn ìṣòro wa tá a fi sílẹ̀.

Síbẹ̀, ó máa ń wu wá pé ká wà nínú Párádísè. Torí náà, a lè máa ṣe kàyéfì pé: ‘Ṣé “Párádísè” wà lóòótọ́, àbí ńṣe la kàn fi ń dánú ara wa dùn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí ló wá dé tó fi ń wù wá? Ṣé ayé máa di Párádísè lóòótọ́?’

ỌJỌ́ PẸ́ TÍ PÁRÁDÍSÈ TI Ń WU WÁ

Ọ̀rọ̀ nípa Párádísè ti ń múnú àwọn èèyàn dùn látọjọ́ tó ti pẹ́. Ohun tó jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí Párádísè ni ohun tí Bíbélì sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe “gbin ọgbà kan ní Édẹ́nì, síhà ìlà-oòrùn.” Kí ló mú kí ọgbà náà máa wùùyàn? Ìtàn náà sọ fún wa pé: “Jèhófà Ọlọ́run mú kí olúkúlùkù igi tí ó fani mọ́ra ní wíwò, tí ó sì dára fún oúnjẹ hù.” Ọgbà tó tura tó sì lẹ́wà ni lóòótọ́. Ohun tó wá fani mọ́ra jù ni pé “igi ìyè pẹ̀lú [wà] ní àárín ọgbà náà.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:8, 9.

Láfikún sí i, ìwé Jẹ́nẹ́sísì tún mẹ́nu bà á pé odò mẹ́rin ń ṣàn jáde látinú ọgbà náà. Méjì lára àwọn odò náà ṣì wà títí dòní, ìyẹn odò Tígírísì (tàbí, Hídẹ́kẹ́lì) àti odò Yúfírétì. (Jẹ́nẹ́sísì 2:10-14) Odò méjèèjì yìí ń ṣan lọ sí ibi tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Páṣíà. Ibẹ̀ la wá mọ̀ sí orílẹ̀-èdè Ìráàkì báyìí, tó jẹ́ ara ilẹ̀ Páṣíà tẹ́lẹ̀.

Kò yani lẹ́nu pé Párádísè orí ilẹ̀ ayé wà lára àṣà àjogúnbá àwọn ará Páṣíà. Àwọn ará Páṣíà ṣe kápẹ́ẹ̀tì kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún, wọ́n sì ya àwòrán ọgbà tó ní odi sí i lára. Oríṣiríṣi igi àti òdòdó ló wà nínú ọgbà náà, wọ́n sì gbé kápẹ́ẹ̀tì yìí sí ilé ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí tí wọ́n ń pè ní Philadelphia Museum of Art, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọ̀rọ̀ tí àwọn ará Páṣíà máa ń lò fún “ọgbà tó ní odi” tún túmọ̀ sí “Párádísè.” Àwòrán tí wọ́n yà sára kápẹ́ẹ̀tì yìí ṣàpẹẹrẹ bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ọgbà Édẹ́nì.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àṣà àti èdè ló máa ń sọ ìtàn àtẹnudẹ́nu nípa Párádísè. Ìdí ni pé bí àwọn èèyàn ṣe ń ṣí káàkiri ayé, wọ́n ń sọ ìtàn nípa ọgbà Édẹ́nì fún àwọn tí wọ́n bá pàdé, débí pé ìtàn náà wá di ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́, tó sì wá di ìtàn àtẹnudẹ́nu. Títí di báyìí, àwọn èèyàn ṣì máa pe àgbègbè tó bá rẹwà lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ ní Párádísè.

WỌ́N Ń WÁ IBI TÍ PÁRÁDÍSÈ WÀ KIRI

Àwọn olùṣàwárí kan ti sọ pé àwọn ti rí Párádísè tó sọnù. Bí àpẹẹrẹ, Charles Gordon, tó jẹ́ ọ̀gágun ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan rìnrìn àjò lọ sí ìlú Seychelles lọ́dún 1881. Ẹ̀wà àrà ọ̀tọ̀ tí àgbègbè kan tí wọ́n ń pè ní Vallée de Mai ní, wú u lórí débi tó fi pe ibẹ̀ ní ọgbà Édẹ́nì. Ibẹ̀ ti wá di ọ̀kan lára àwọn ibi tí wọ́n kà sí pàtàkì láyé, ìyẹn World Heritage site. Arìnrìn-àjò ojú òkun ni Christopher Columbus tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Ítálì. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún, ó rìnrìn-àjò lọ sí àgbègbè kan. Nígbà tó dé erékùṣù Hispaniola, tó ti wá di orílẹ̀-èdè Dominican Republic àti Haiti báyìí, ó ronú pé bóyá lòun ò ti rí ọgbà Édẹ́nì.

Ìwé ìtàn òde òní kan wà tí wọ́n pè ní Mapping Paradise. Ìwé yìí ní ọgọ́sàn-án [190] àwòrán ilẹ̀ ayé àtijọ́. Ọ̀pọ̀ lára àwòrán náà jẹ́ ti Ádámù àti Éfà nígbà tí wọ́n wà nínú ọgbà Édẹ́nì. Wọ́n tún wá rí ẹ̀dà àwòrán ilẹ̀ kan tó ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹtàlá, tó jẹ́ ti Beatus of Liébana. Àmì kékeré kan tó ní igun mẹ́rin wà lápá òkè rẹ̀, ó sì ní àwòrán Párádísè nínú. Wọ́n ya àwòrán odò mẹ́rin tí wọ́n pè ní “Tígírísì,” “Yúfírétì,” “Indus” àti “Jọ́dánì” sì ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn igun náà, wọ́n sì sọ pé ó ṣàpẹẹrẹ bí ẹ̀sìn Kristẹni ṣe tàn dé orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mọ ọ̀gangan ibi tí Párádísè ìpilẹ̀ṣẹ̀ wà, síbẹ̀ àwọn àwòrán yìí fi hàn pé àwọn èèyàn ò tíì gbàgbé rẹ̀ àti pé ó ṣì ń fa wọ́n mọ́ra.

Gbajúmọ̀ ni John Milton, tó jẹ́ akéwì ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní nǹkan bí ọdún 1700. Ọ̀gbẹ́ni yìí kéwì nípa Párádísè tó sọnù, ó pè é ní Paradise Lost, ewì yìí dá lórí ìtàn inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù dá àti bí Ọlọ́run ṣe lé e kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì. Nínú ewì náà, ó ṣàlàyé bí àwọn èèyàn á ṣe tún máa wà láàyè títí lórí ilẹ̀ ayé, ó wá sọ pé: “Nígbà yẹn, gbogbo ayé ló máa di Párádísè.” Lẹ́yìn náà, Milton kọ ewì míì tó dá lórí bí Párádísè náà ṣe pa dà wá, ó sì pè é ní Paradise Regained.

ÈRÒ ÀWỌN ÈÈYÀN YÍ PA DÀ

Ó ṣe kedere pé tipẹ́tipẹ́ làwọn èèyàn ti ń ronú nípa Párádísè orí ilẹ̀ ayé tá a pàdánù. Àmọ́ kí ló fà á tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi ronú nípa ẹ̀ mọ́ báyìí? Àkíyèsí tí ìwé Mapping Paradise ṣe ni pé, “àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn . . . ti yí èrò wọn pa dà nípa ibi tí Párádísè wà.”

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n ń kọ́ pé ọ̀run ni wọ́n ti máa gbádùn ìyè ayérayé, kì í ṣe nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ohun tí Sáàmù 37:29 sọ ni pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” Àmọ́ ní báyìí tí ayé kì í ṣe Párádísè, ǹjẹ́ a nírètí kankan pé ìlérí yìí ṣì máa ṣẹ? *

Ó DÁJÚ PÉ AYÉ MÁA DI PÁRADÍSÈ

Jèhófà Ọlọ́run tó dá Párádísè àkọ́kọ́ tá a pàdánù ti ṣèlérí pé òun máa dá a pa dà. Báwo ló ṣe máa ṣe é? Rántí pé Jésù kọ́ wa ká máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Ìjọba tí Jésù Kristi máa jẹ́ alákòóso rẹ̀ yìí ló máa rọ́pò gbogbo ìjọba àwa èèyàn, ó sì máa kárí ayé. (Dáníẹ́lì 2:44) Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, gbogbo ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nípa Párádísè pátá ló máa ṣẹ.

Ọlọ́run ti mí sí wòlíì Aísáyà láti ṣe àkọsílẹ̀ bí nǹkan ṣe máa rí nínú Párádísè tó ṣèlérí. Kò ní sí rògbòdìyàn tàbí ohunkóhun tó máa kó wa lọ́kàn sókè mọ́ níbẹ̀. (Aísáyà 11:6-9; 35:5-7; 65:21-23) A rọ̀ pé kó o lo àkókò díẹ̀ láti ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn nínú Bíbélì rẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ kí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé túbọ̀ dá ọ lójú. Àwọn tó bá wà láyé nígbà yẹn á gbádùn Párádísè, wọ́n á sì rí ojúure Ọlọ́run, èyí tí Ádámù pàdánù.—Ìṣípayá 21:3.

Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé ayé máa di Párádísè lóòótọ́? Bíbélì sọ ìdí náà fún wa, ó ní: “Ní ti ọ̀run, ti Jèhófà ni ọ̀run, ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.” Tí pé ayé máa pa dà di Párádísè jẹ́ ohun tí “Ọlọ́run, ẹni tí kò lè purọ́, ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́.” (Sáàmù 115:16; Títù 1:2) Ẹ ò rí i pé ìlérí àgbàyanu lèyí jẹ́, ìyẹn ni pé ayé máa di Párádísè títí láé!

^ ìpínrọ̀ 15 Ó gba àfiyèsí pé a kà nínú Kùránì sura 21 Aya 105, Al-Anbiya’ [Àwọn Wòlíì], pé: “Olododo laaarin awọn iranṣẹ Mi ni yoo jogun ilẹ-aye.”