Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ÌYÈ ÀTI IKÚ?

Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìyè àti Ikú

Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìyè àti Ikú

Tá a bá kà nípa bí lọ́run ṣe ṣẹ̀dá ayé nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì tó jẹ́ ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, a máa rí i níbẹ̀ pé Ọlọ́run sọ fún Ádámù tó jẹ́ ọkùnrin àkọ́kọ́ pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Gbólóhùn yẹn ṣe kedere, torí ó jẹ́ kí Ádámù mọ̀ pé tó bá pa òfin Ọlọ́run mọ́, kò ní kú, kàkà bẹ́ẹ̀ ó máa wà títí láé nínú ọgbà Édẹ́nì.

Àmọ́, ó dunni pé dípò tí Ádámù ì bá fi yàn láti pa òfin Ọlọ́run mọ́ kó sì wà láàyè títí láé, ńṣe ló yàn láti rú òfin náà. Nígbà tí Éfà ìyàwó rẹ̀ fún un lára èso tí Ọlọ́run sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ, ó gbà á, ó sì jẹ ẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) A ṣì ń jìyà ìwà àìgbọ́ràn yẹn títí dòní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ náà lọ́nà yìí: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Ádámù ni “ènìyàn kan” tí ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ. Àmọ́, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, kí sì nìdí tí ẹ̀ṣẹ̀ náà fi yọrí sí ikú?

Ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù dá ni pé ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ó sì rú òfin rẹ̀. (1 Jòhánù 3:4) Ọlọ́run sì ti sọ fún un tẹ́lẹ̀ pé ikú ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà. Ká ní Ádámù àtàwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ gbọ́ràn sí Ọlọ́run ni, wọn ò ní di ẹlẹ́ṣẹ̀, wọn ò sì ní kú rárá. Ọlọ́run kò dá èèyàn pé kó máa kú, kódà ńṣe ló fẹ́ ká wà láàyè títí láé.

Bí Bíbélì ṣe sọ, ikú ti tàn dé “ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn,” kò sì sẹ́ni tó lè jiyàn ẹ̀. Àmọ́, ṣé apá kan lára wa ṣì máa ń wà láàyè tí èèyàn bá kú? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni. Wọ́n gbà pé apá kan lára wa tí wọ́n ń pè ní ọkàn, kì í kú. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ohun tí à ń sọ ni pé Ọlọ́run parọ́ fún Ádámù. Kí nìdí? Tí apá kan lára wa bá lọ ń gbé ní ibòmíì lẹ́yìn téèyàn kú, á jẹ́ pé ikú kì í ṣe ìyà ẹ̀ṣẹ̀ bí Ọlọ́run ṣe sọ nìyẹn. Bíbélì sọ pé: “Kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́.” (Hébérù 6:18) Àmọ́ ká sòótọ́, Sátánì ló parọ́ fún Éfà nígbà tó sọ fún un pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:4.

Ìyẹn wá lè mú ká béèrè pé, Tó bá jẹ́ pé ẹ̀kọ́ èké ni pé ọkàn èèyàn kì í kú, kí ló wá ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá kú?

BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ ÒTÍTỌ́

Ìtàn nípa ìṣẹ̀dá tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá ọkùnrin náà láti inú ekuru ilẹ̀, ó sì fẹ́ èémí ìyè sínú ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “alààyè ọkàn” ni ne’phesh, ó sì tún lè túmọ̀ sí “ẹ̀dá tó ń mí.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:7.

Bíbélì tipa báyìí mú kó ṣe kedere pé Ọlọ́run kò dá ọkàn tí kì í kú mọ́ wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni “alààyè ọkàn.” Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé kò sí ibì kankan nínú Bíbélì tó o ti lè rí ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ọkàn kì í kú.

Ní báyìí tá a ti rí i pé Bíbélì kò sọ pé èèyàn ní ọkàn táwọn kan sọ pé kì í kú, kí wá nídìí tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn fi ń kọ́ni nírú ẹ̀kọ́ yìí? Láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, a máa ní láti ṣàgbéyẹ̀wò ìtàn ilẹ̀ Íjíbítì àtijọ́.

Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN ABỌ̀RÌṢÀ BẸ̀RẸ̀ SÍ Í TÀN KÁLẸ̀

Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan tó ń jẹ́ Herodotus, tó gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni sọ pé àwọn ará Íjíbítì “ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn pé ọkàn èèyàn kì í kú.” Àwọn ará Bábílónì ìgbàanì náà gbà pé ọkàn èèyàn kì í kú. Nígbà tí Alẹkisáńdà Ńlá fi máa ṣẹ́gun àwọn ará Ilà Oòrùn ayé lọ́dún 332 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí nílẹ̀ Gíríìsì ti bẹ̀rẹ̀ sí tan ẹ̀kọ́ yìí kálẹ̀, kò sì pẹ́ tó fi tàn jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì.

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, àwùjọ méjì tó ń ṣe ẹ̀sìn Júù, ìyẹn àwọn Essene àtàwọn Farisí, ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn pé tẹ́nì kan bá kú ọkàn rẹ̀ máa jáde lára rẹ̀, á sì lọ sí ibòmíì. Ìwé náà The Jewish Encyclopedia sọ pé: “Ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì làwọn Júù ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ọkàn èèyàn kì í kú, ní pàtàkì látinú ẹ̀kọ́ ọgbọ́n orí Plato.” Bákàn náà, Josephus tó jẹ́ òpìtàn Júù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní kò sọ pé inú Ìwé Mímọ́ ni ẹ̀kọ́ yìí ti wá, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tó sọ ni pé ó jẹ́ “ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì,” èyí tó gbà pé ó jẹ́ ìtàn àtẹnudẹ́nu lásán.

Bí àṣà àwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì ṣe túbọ̀ ń tàn kálẹ̀, àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni náà tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ àwọn abọ̀rìṣà yìí. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Jona Lendering, sọ pé: “Ohun tí Plato fi kọ́ni ni pé ìgbà kan wà tí ọkàn èèyàn wà nínú ìgbádùn, àmọ́ nígbà tó yá ó ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀, èrò yìí ló mú kó rọrùn fún àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì láti da ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni pọ̀ mọ́ ti Plato.” Torí náà, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì wá fara mọ́ ẹ̀kọ́ àwọn abọ̀rìṣà tó sọ pé ọkàn èèyàn kì í kú, ó sì wá di ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí wọ́n gbà gbọ́.

“ÒTÍTỌ́ YÓÒ SÌ DÁ YÍN SÍLẸ̀ LÓMÌNIRA”

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Èmi ń tẹnu mọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tanni jẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù.” (1 Tímótì 4:1, Bíbélì Mímọ́ Ní Èdè Yorùbá Òde Òní.) Òótọ́ pọ́ńbélé mà lọ̀rọ̀ yìí o! “Ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù” gbáà ni pé ọkàn èèyàn kì í kú. Kò sí ní ibì kankan nínú Bíbélì, ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà àtàwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí láyé ìgbàanì ló ti wá.

Ó dùn mọ́ wa pé, Jésù ní: “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Tá a bá ní ìmọ̀ òtítọ́ Bíbélì lọ́nà tó péye, a máa di òmìnira lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ tó ń tàbùkù sí Ọlọ́run àtàwọn àṣà tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn nínú ayé ń gbé lárugẹ. Láfikún sí i, òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti tú wa sílẹ̀ nínú àjàgà àwọn àṣà ìbílẹ̀ àti ìgbàgbọ́ òdì nípa ipò tí àwọn òkú wà.—Wo àpótí náà “ Ibo Làwọn Òkú Wà?

Ẹlẹ́dàá wa kò dá àwa èèyàn pé ká kàn lo àádọ́rin [70] sí ọgọ́rin [80] ọdún láyé, ká wá papòdà lọ sí ilẹ̀ àwọn ẹ̀mí àìrí, ká sì wà níbẹ̀ títí gbére. Ohun tó ní lọ́kàn ni pé kí àwa èèyàn tá a jẹ́ ẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀ máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, ká sì máa ṣègbọràn sí i. Ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn yìí jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn, kò sì sí oun tó lè yí ohun tó fẹ́ ṣe pa dà. (Málákì 3:6) Ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.

 

Kò sí ibì kankan nínú Bíbélì tó o ti lè rí ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ọkàn kì í kú