Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÍ ỌLỌ́RUN ṢE PA​—BÍBÉLÌ MỌ́

Ohun Tí Kò Jẹ́ Kí Bíbélì Pa Run

Ohun Tí Kò Jẹ́ Kí Bíbélì Pa Run

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO: Òrépèté àti awọ ni àwọn tó kọ Bíbélì àtàwọn adàwékọ máa ń lò láyé àtijọ́ láti fi kọ̀wé. * (2 Tímótì 4:13) Báwo làwọn ohun èlò yìí ṣe mú kó ṣòro fún Bíbélì láti wà pẹ́ títí?

Òrépèté máa ń tètè fàya, ó máa ń yi àwọ̀ pa dà, kì í sì í pẹ́ gbó. Richard Parkinson àti Stephen Quirke tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa ilẹ̀ Íjíbítì àtijọ́ sọ pé: “Kì í pẹ́ kí àwọn ohun èlò ìkọ̀wé yìí tó gbó, táá sì bẹ̀rẹ̀ sí í rún. Tí wọ́n bá fi pa mọ́, bóyá tí wọ́n tọ́jú rẹ̀ sábẹ́ ilẹ̀, ooru máa mú kó jẹra, eku, kòkòrò tàbí àwọn eèrà sì lè jẹ ẹ́ bà jẹ́.” Lẹ́yìn tí wọ́n rí àwọn ìwé òrépèté kan, kò pẹ́ tí wọ́n fi bà jẹ́, torí pé ooru tàbí ọ̀rinrin pọ̀ níbi tí wọ́n kó wọn sí.

Ìwé awọ ní tiẹ̀ lágbára díẹ̀ ju òrépèté lọ, àmọ́ òun náà máa ń bà jẹ́ téèyàn ò bá bójú tó o dáadáa, bóyá tí wọ́n kó o síbi tí ooru ti mú un tàbí tí ọ̀rinrin tàbí ìmọ́lẹ̀ wà. * Kòkòrò máa ń jẹ ìwé awọ náà. Ìdí nìyí tí ìwé Everyday Writing in the Graeco-Roman East, fi sọ pé “àwọn ìwé àtijọ́ kì í fi bẹ́ẹ̀ pẹ́ lọ títí.” Ká ní Bíbélì náà ti gbó bà jẹ́, àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ náà á ti bà jẹ́ pẹ̀lú rẹ̀.

OHUN TÓ JẸ́ KÍ BÍBÉLÌ WÀ DÒNÍ: Òfin àwọn Júù pa á láṣẹ fún gbogbo ọba pé “kí ó kọ ẹ̀dà òfin yìí sínú ìwé kan fún ara rẹ̀,” ìyẹn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì. (Diutarónómì 17:18) Láfikún sí i, àwọn adàwékọ ṣe àdàkọ ọ̀pọ̀ ìwé Bíbélì débi pé, nígbà tó fi máa dí ìgbà ayé Jésù, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí sínágọ́gù kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì àti làwọn ibi tó jìnnà gan-an bíi Makedóníà téèyàn ò ti ní rí Ìwé Mímọ́! (Lúùkù 4:16, 17; Ìṣe 17:11) Báwo ni àwọn ìwé àfọwọ́kọ yẹn ṣe wá wà títí dòní?

Wọ́n rí ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n pè ní Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, nínú ìkòkò tí wọ́n tọ́jú sí ibi tó gbẹ nínú ihò àpáta, ó sì ti wà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún

Philip W. Comfort tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Májẹ̀mú Tuntun sọ pé: “Àwọn Júù máa ń tọ́jú àwọn àkájọ Ìwé Mímọ́ sínú ìkòkò kó má báa tètè bà jẹ́. Ohun tí àwọn Kristẹni náà sì máa ń ṣe nìyẹn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé inú ìkòkò, ibi tó ṣókùnkùn tàbí inú ihò àpáta ni wọ́n ti rí ọ̀pọ̀ Bíbélì àfọwọ́kọ ayé ìgbàanì. Ó sì máa ń jẹ́ ibi tó gbẹ dáadáa.

ÀBÁJÁDE RẸ̀: Ẹgbẹẹgbẹ̀rún apá kan Bíbélì àfọwọ́kọ, tó ti lé ní ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún ló ṣì wà títí dòní. Kò tún sí ìwé àfọwọ́kọ míì tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tó sì ti pẹ́ láyé tó bẹ́ẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 3 Irúgbìn òrépèté ni wọ́n fi ń ṣe ohun èlò ìkọ̀wé tí wọ́n ń pè ní òrépèté. Awọ ẹran ni wọ́n fi ń ṣe ohun èlò ìkọ̀wé tó jẹ́ awọ.

^ ìpínrọ̀ 5 Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gba òmìnira, ìwé awọ ni wọ́n fi kọ ìkéde òmìnira tí wọ́n fi òǹtẹ̀ ìjọba lù. Ní báyìí èèyàn fẹ́rẹ̀ẹ́ má rí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kà mọ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé kò tíì pé ọgọ́rùn-ún méjì ààbọ̀ [250] ọdún tí wọ́n ṣe ìwé náà.