Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé báwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe dá ọgbọ́n sí àbùdá èèyàn ti jẹ́ ká ní ẹ̀mí gígùn?

Àwọn Èèyàn Ń Wá Ẹ̀mí Gígùn

Àwọn Èèyàn Ń Wá Ẹ̀mí Gígùn

“Mo ti rí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún ọmọ aráyé láti mú kí ọwọ́ wọn dí. Ó ti ṣe ohun gbogbo rèǹtèrente ní ìgbà tirẹ̀. Kódà ó ti fi ayérayé sí wọn lọ́kàn.”​Oníwàásù 3:​10, 11.

Ọ̀RỌ̀ tí ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì sọ yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀mí gígùn jẹ aráyé lógún. Ọjọ́ pẹ́ tí aráyé ti ń wá bí wọ́n ṣe máa ní ẹ̀mí gígùn, torí pé ẹ̀mí èèyàn kúrú, ikú ò sì ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìtàn àti ìtàn àtẹnudẹ́nu ló wà tó fi hàn pé àwọn èèyàn ń wá bí wọ́n ṣe máa mọ àṣírí bí èèyàn ṣe lè ní ẹ̀mí gígùn.

Àpẹẹrẹ kan ni ti Gilgamesh tó jẹ́ ọba àwọn ará Súmà. Ọ̀pọ̀ ìtàn àròsọ làwọn èèyàn ti sọ nípa ìgbésí ayé rẹ̀. Ọ̀kan lára ẹ̀ ni Ìtàn Akọni Gilgamesh tí wọ́n sọ pé ó rin ìrìn-àjò eléwu kan kó lè ṣe ìwádìí nípa béèyàn ò ṣe ní kú mọ́. Àmọ́ pàbó ni gbogbo ìwádìí náà já sí.

Ẹnì kan tó mọ̀ nípa oògùn wà nínú ilé tó ti ń po oògùn ní nǹkan bíi ọdún 500 ṣáájú Sànmánì Kristẹni

Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún ṣáájú Sàmánì Kristẹni, àwọn tó mọ̀ nípa oògùn ní orílẹ̀-èdè Ṣáínà gbìyànjú láti ṣe àjídèwe kan, torí àwọn èèyàn gbà pé ó máa fún àwọn ní ẹ̀mí gígùn. Wọ́n ṣe ohun mímu kan tó ní èròjà mercury àti arsenic nínú. Èròjà yẹn ni wọ́n sọ pé ó pa àwọn olú ọba Ṣáínà kan. Ní nǹkan bíi 500 sí 1500 ọdún ṣáájú Sàmánì Kristẹni, àwọn tó mọ̀ nípa oògùn nílẹ̀ Yúróòpù gbìyànjú láti fi góòlù ṣe oògùn tí èèyàn lè lò, torí pé wọ́n gbà pé góòlù kì í bà jẹ́, nípa bẹ́ẹ̀ ó lè mú ẹ̀mí èèyàn gùn.

Ní báyìí, àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè àtàwọn onímọ̀ nípa àbùdá èèyàn ń sapá láti mọ ìdí táwọn èèyàn fi ń darúgbó. Bíi tàwọn tó ń gbìyànjú láti ṣe àjídèwe, ìwádìí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì náà fi hàn pé àwọn èèyàn ṣì ń wá ọ̀nà tí wọn ò fi ní darúgbó tàbí kí wọ́n kú. Àmọ́, kí ni àbájáde irú àwọn ìwádìí yẹn?

ỌLỌ́RUN TI “FI AYÉRAYÉ SÍ WỌN LỌ́KÀN.”​—ONÍWÀÁSÙ 3:​10, 11

ÌWÁDÌÍ NÍPA ÌDÍ TÁ A FI Ń DARÚGBÓ LÓNÌÍ

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ń ṣèwádìí nípa sẹ́ẹ̀lì (ìyẹn àwọn ohun tín-tìn-tín) inú ara ti ṣàwárí pé ó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọ̀nà lọ tí wọ́n lè gbà ṣàlàyé ìdí tá a fi ń darúgbó tá a sì ń kú. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀ nípa ohun tó gbé ara ró ti ṣàṣeyọrí nínú lílo àbùdá àti èròjà purotéènì láti mú kí ẹ̀mí èèyàn àti ti ẹranko túbọ̀ gùn. Irú àwọn ìtẹ̀síwájú yìí ti mú kí àwọn èèyàn pàtàkì láwùjọ ná owó wọn sórí ìwádìí nípa ìdí tá a fi ń kú.” Báwo ni wọ́n ṣe ṣe àwọn ìwádìí náà?

Wọ́n sapá láti mú kí ẹ̀mí èèyàn gùn sí i. Àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè gbà pé nǹkan pàtàkì tó ń mú kí ẹ̀mí èèyàn gùn wà nínú ṣóńṣó orí àbùdá tí wọ́n ń pè ní telomeres. Àwọn ṣóńṣó orí àbùdá yìí ló máa ń dáàbò bo àwọn ìsọfúnni tó wà nínú sẹ́ẹ̀lì ara wa bí wọ́n ṣe ń mú irú tiwọn jáde. Àmọ́ bí àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ṣe ń pín ni àwọn ṣóńṣó orí àbùdá náà á máa kéré sí i. Tó bá wá yá, àwọn sẹ́ẹ̀lì náà kò ní máa pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ mọ́, èèyàn á wá bẹ̀rè sí í darúgbó.

Elizabeth Blackburn tó gba àmì ẹ̀yẹ Nobel lọ́dún 2009 ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ láti ṣàwárí èròjà kan tí kì í jẹ́ kí ṣóńṣó orí àbùdá tètè kéré, èyí ò sì ní jẹ́ kí sẹ́ẹ̀lì tètè darúgbó. Àmọ́, àwọn náà sọ nínú ìwádìí wọn pé ṣóńṣó orí àbùdá kì í dá ẹ̀mí èèyàn sí lọ́nà àràmàǹdà, ìyẹn ni pé wọn kì í mú kí ẹ̀mí èèyàn gùn kọjá ọjọ́ orí téèyàn máa ń gbé.”

Wọ́n sapá láti ṣe àtúntò sẹ́ẹ̀lì inú ara. Ìyẹn ni ọ̀nà kejì tí wọ́n sọ pé ó lè mú kí ẹ̀mí èèyàn gùn. Tí àwọn sẹ́ẹ̀lì ara bá ti darúgbó débi pé wọn ò lè mú tuntun míì jáde mọ́, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìsọfúnni òdì ránṣẹ́ sí àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń gbógun ti àrùn, ìyẹn ló sì máa ń fa ara wíwú, ìrora gbogbo ìgbà àti àrùn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nílẹ̀ Faransé tí ṣe àtúntò sẹ́ẹ̀lì tí wọ́n gbà lára àwọn àgbàlagbà kan táwọn kan nínú wọn ti ju ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún lọ. Ọ̀jọ̀gbọ́n Jean-Marc Lemaître tó jẹ́ olórí àwọn tó ṣèwádìí náà sọ pé iṣẹ́ wọn fi hàn pé èèyàn lè “yí bí sẹ́ẹ̀lì inú ara ṣe ń darúgbó pa dà.”

ṢÉ ÌMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ LÈ MÚ KÍ Ẹ̀MÍ ÈÈYÀN GÙN?

Kì í ṣe gbogbo àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló gbà pé àwọn oògùn tí kì í jẹ́ kéèyàn darúgbó lè mú kí ẹ̀mí èèyàn gùn kọjá ọjọ́ orí téèyàn máa ń gbé. Òótọ́ ni pé láti ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún ni ìlera ẹ̀dá èèyàn ti ń sunwọ̀n sí i. Ìdí sì ni pé, àwọn èèyàn túbọ̀ ń fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó, wọ́n ń lo àwọn oògùn tó ń pa kòkòrò inú ara, wọ́n sì tún ń gba abẹ́rẹ́ àjẹsára. Àwọn kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa àbùdá èèyàn gbà pé ọjọ́ orí èèyàn kò lè gùn ju bó ṣe wà náà lọ.

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3,500) ọdún sẹ́yìn, Mósè tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé: “Àádọ́rin (70) ọdún ni gígùn ọjọ́ ayé wa, tàbí kó jẹ́ ọgọ́rin (80) ọdún tí èèyàn bá lókun tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Síbẹ̀, wàhálà àti ìbànújẹ́ ló kún inú wọn; wọ́n á kọjá lọ kíákíá, a ó sì fò lọ.” (Sáàmù 90:10) Bo tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ti sapá láti jẹ́ kí ọjọ́ ayé wa gùn, síbẹ̀ ọjọ́ orí wa kì í ju bí Mósè ṣe sọ ọ́ náà lọ.

Àmọ́, àwọn ẹran omi kéékèèké tí wọ́n ń pè ní sea urchin tàbí irú òkòtó òkun kan tí wọ́n ń pè ní quahog clam lè gbé ohun tó ju ọgọ́rùn-ún méjì (200) ọdún láyé, bákan náà igi ńláńlá bíi sequoia lè gbé ẹgbẹ̀rún ọdún mélòó kan láyé. Tá a bá sì fi gígùn ọjọ́ ayé wa wé ti àwọn nǹkan alààyè yìí àtàwọn míì, á mú ká bi ara wa pé, ‘Ṣé àwa èèyàn ò wá lè lò ju 70 tàbí 80 ọdún láyé ni?’