Yorùbá
Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/2020090/afrn/art/2020090_afrn_sqr_xl.jpg
wp20 No. 2 ojú ìwé 16

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, àmọ́ ṣó o ti béèrè rí pé kí ni Ìjọba Ọlọ́run, kí ló sì ń bọ̀ wá ṣe?

WO OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:

  • Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

    Ó jẹ́ ìjọba kan ní ọ̀run, Jésù Kristi sì ni Ọba Ìjọba náà.​—Àìsáyà 9:​6, 7; Mátíù 5:3; Lúùkù 1:​31-33.

  • Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe?

    Ó máa fòpin sí gbogbo nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé, á sì mú àlàáfíà ayérayé wá fún àwọn tó wà láyé.​—Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10.

  • Kí ló túmọ̀ sí láti máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́?

    Ó túmọ̀ sí pé ká máa ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn, ká sì gbà pé òun nìkan ló lè mú kí ayé rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́.​—Mátíù 6:33; 13:44.