Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ti Ṣẹ

Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ti Ṣẹ

Ní ìbẹ̀rẹ̀, a sọ̀rọ̀ nípa bí òrìṣà kan ní ìlú Delphi ṣe tan Croesus jẹ, èyí tó mú kó kàgbákò nígbà tó lọ bá ọba Páṣíà jagun. Àmọ́ Bíbélì ní tiẹ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa ọba Páṣíà, àsọtẹ́lẹ̀ náà sì ṣẹ dórí bíńtín.

Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì [200] ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí ọba yìí rárá ni wòlíì kan tó ń jẹ́ Aísáyà ti sọ pé ọba Páṣíà kan tó ń jẹ́ Kírúsì máa ṣẹ́gun ìlú Bábílónì, wòlíì yẹn tún sọ ọ̀nà tó máa gbà ṣe bẹ́ẹ̀.

Aísáyà 44:24, 27, 28: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, . . . ‘Ẹni tí ń wí fún ibú omi pé, ‘Gbẹ; gbogbo odò rẹ sì ni èmi yóò mú gbẹ táútáú’; ẹni tí ó wí nípa Kírúsì pé, ‘Òun ni olùṣọ́ àgùntàn mi, gbogbo ohun tí mo sì ní inú dídùn sí ni òun yóò mú ṣe pátápátá’; àní nínú àsọjáde mi nípa Jerúsálẹ́mù pé, ‘A óò tún un kọ́,’ àti nípa tẹ́ńpìlì pé, ‘A ó fi ìpìlẹ̀ rẹ lélẹ̀.’”

Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì tó ń jẹ́ Herodotus sọ pé, àwọn ọmọ ogun Kírúsì darí omi odò Yúfírétì tó yí ìlú Bábílónì ká gba ibòmíì. Ọgbọ́n tí Kírúsì dá yìí mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láti fẹsẹ̀ rìn gba àárín odò yẹn kọjá. Lẹ́yìn tí Kírúsì ṣẹ́gun ìlú náà, ó dá àwọn Júù tó wà nígbèkùn sílẹ̀. Ó ní kí wọ́n lọ tún Jerúsálẹ́mù kọ́, ìlú tó jẹ́ pé ó ti tó àádọ́rin [70] ọdún tó ti pa run.

Aísáyà 45:1: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún ẹni àmì òróró rẹ̀, fún Kírúsì, ẹni tí mo di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú, láti tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba níwájú rẹ̀, kí n lè tú àmùrè ìgbáròkó àwọn ọba pàápàá; láti ṣí àwọn ilẹ̀kùn aláwẹ́ méjì níwájú rẹ̀, tí yóò fi jẹ́ pé, àwọn ẹnubodè pàápàá ni a kì yóò tì.”

Àwọn ọmọ ogun Páṣíà gba ẹnu ọ̀nà onílẹ̀kùn-méjì tó wọ ìlú Bábílónì wọlé torí pé àwọn ará ìlú Bábílónì ṣí i sílẹ̀ gbayawu láìmọ̀ọ́mọ̀. Ká sọ pé àwọn ará ìlú Bábílónì mọ̀ pé Kírúsì máa wá gbógun ja àwọn ni, wọn ò bá ti ìlẹ̀kùn wọn pa. Àmọ́ ẹ̀pa ò bóró mọ́.

Èyí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àgbàyanu tí Bíbélì sọ, tó sì ní ìmúṣẹ gẹ́lẹ́ bó ṣe sọ ọ́. * Àwọn kan máa ń sọ pé ẹ̀mí kan ló ṣí asọtẹ́lẹ̀ payá fún àwọn, àwọn míì sì máa ń sọ pé òrìṣà àwọn ló bá àwọn sọ̀rọ̀. Àmọ́ ní ti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì, wọ́n wá látọ̀dọ̀ “Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe.”​—Aísáyà 46:10.

Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà nìkan ló lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ìtúmọ̀ orúkọ yẹn ni “Alèwílèṣe.”  Ìyẹn ni pé ó lè mọ ọjọ́ iwájú, ó sì lè darí nǹkan lọ́nà tó fẹ́, kó bàa lè mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Èyí sì mú kó dá wa lójú pé gbogbo ìlérí tó ti ṣe ló máa mú ṣẹ.

ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ TÓ Ń ṢẸ LÓNÌÍ

Ṣó o fẹ́ mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa àkókò tá a wà yìí? Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún sẹ́yìn, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà.” Ọjọ́ ìkẹyìn kí ni? Kì í ṣe pé ayé yìí máa pa rẹ́ tàbí pé kò ní sí ìran èèyàn mọ́ láyé, àmọ́ ó jẹ́ ọjọ́ ìkẹyìn fún wàhálà, ìnira àti ìyà tó ti ń jẹ aráyé láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wá. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó máa jẹ́ ká mọ àmì “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”

2 Tímótì 3:1-5: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn . . . , àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.”

Ṣé ìwọ náà gbà pé ìwà táwọn èèyàn ń hù lóde òní nìyẹn? Ṣó o kíyè sí pé àwọn tí kò mọ̀ ju tara wọn lọ, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ owó àtàwọn agbéraga ló kún inú ayé yìí? Ṣé ìwọ náà rí i pé àfi kéèyàn máa ṣe sùúrù torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò ṣe tán láti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà? Ó ṣeé ṣe kó o tún ti rí i pé àwọn ọmọ kì í gbọ́rọ̀ sáwọn òbí wọn lẹ́nu mọ́ àti pé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ fàájì ju Ọlọ́run lọ. Kò sì jọ pé nǹkan máa yí pa dà sí rere, ńṣe ló ń burú sí i bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́.

Mátíù 24:6, 7: “Ẹ óò gbọ́ nípa àwọn ogun àti ìròyìn nípa àwọn ogun. . . . Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.”

Ìwádìí fi hàn pé láti ọdún 1914, ó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] mílíọ̀nù èèyàn tí ogun pa. Ìwọ náà wo iye èèyàn tí ìbànújẹ́ máa dorí ẹ̀ kodò nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yẹn. Àmọ́ ṣé àwọn èèyàn tìtorí ìyẹn dáwọ́ ogun dúró?

Mátíù 24:7: ‘Àìtó oúnjẹ yóò wà.’

Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Oúnjẹ Lágbàáyé sọ pé: ‘Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oúnjẹ tó lè tó gbogbo èèyàn wà, síbẹ̀ iye èèyàn tó tó mílíọ̀nù lọ́nà ẹgbẹ̀rin ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [815,000,000] lebi ń pa. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àìmọye èèyàn ni kì í rí oúnjẹ tó ṣara lóore jẹ.’ Lọ́dọọdún, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta àwọn ọmọdé ni ebi ń pa kú.

Lúùkù 21:11: ‘Ìsẹ̀lẹ̀ yóò wà.’

Ó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta [50,000] ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀ tó ń wáyé lọ́dọọdún. Nǹkan bíi ọgọ́rùn ún [100] nínú wọn ló sì ba odindi ilé jẹ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ọdọọdún làwọn ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára gan-an máa ń wáyé. Ìwádìí fi hàn pé, láàárín ọdún 1975 sí 2000, àwọn 471,000 ló pàdánù ẹ̀mí wọn nítorí ìmìtìtì ilẹ̀.

Mátíù 24:14: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ, wọ́n sì ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ogójì [240] ilẹ̀. Ibi gbogbo ni wọ́n máa ń lọ láti kéde ìhìn rere fún àwọn èèyàn, bóyá láàárín ìlú àbí inú abúlé. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí tún jẹ́ ká mọ̀ pé tí iṣẹ́ ìwàásù yẹn bá ti débi tí Ọlọ́run fẹ́, ‘òpin yóò dé.’ Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé òpin máa dé bá ìjọba èèyàn, Ìjọba Ọlọ́run sì máa bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso. Àwọn ìlérí wo ló máa ní ìmúṣẹ nínú Ìjọba Ọlọ́run? Wàá rí ìdáhùn níwájú.