Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orí àti Ẹsẹ​—Ta Ló Fi Wọ́n Sínú Bíbélì?

Orí àti Ẹsẹ​—Ta Ló Fi Wọ́n Sínú Bíbélì?

KÁ SỌ pé ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lo gbáyé, tó o sì jẹ́ Kristẹni. Ìjọ rẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Bó o ṣe ń gbọ́ tí wọ́n ń kà á, o kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú “ìwé mímọ́,” ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. (2 Tímótì 3:15) O lè máa rò ó pé, ‘Ó wù mí láti mọ ibi tó ti fa ọ̀rọ̀ yẹn yọ.’ Àmọ́ ìyẹn lè má rọrùn. Kí nìdí?

KÒ SÍ ORÍ ÀTI ẸSẸ

Wo bí àkájọ “ìwé mímọ́” tó wà nígbà ayé Pọ́ọ̀lù ṣe rí. Apá kan lára àkájọ ìwé Aísáyà ló wà nísàlẹ̀ yìí. Kí lo rí níbẹ̀? Ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ pọ̀, kò lámì ìdánudúró, kò sì ní àwọn orí àti ẹsẹ èyí tá a mọ̀ dáadáa lónìí.

Àwọn tó kọ Bíbélì kò pín ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sí orí àti ẹsẹ. Ńṣe ni wọ́n kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fún wọn sílẹ̀ kí àwọn tó máa kà á lè ka gbogbo ìsọfúnni náà látòkèdélẹ̀, kì í kàn ṣe kí wọ́n ka apá kékeré lára rẹ̀. Ó dájú pé ohun kan náà lo máa ṣe tó o bá gba lẹ́tà pàtàkì látọ̀dọ̀ ẹni tó o nífẹ̀ẹ́. Gbogbo ẹ̀ lo máa kà látòkèdélẹ̀, kì í kàn ṣe apá kan lára rẹ̀.

Àmọ́, bí Bíbélì ò ṣe láwọn orí àti ẹsẹ mú kó ṣòro láti fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí Pọ́ọ̀lù kàn máa ń sọ tó bá fẹ́ fa ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ yọ ni pé “gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀” tàbí “gan-an gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti wí ní ìgbà ìṣáájú.” (Róòmù 3:10; 9:29) Ó sì máa ṣòro láti mọ ibi tó ti fa ọ̀rọ̀ yẹn yọ àfi tó o bá mọ gbogbo “ìwé mímọ́.”

Bákan náà, gbogbo “ìwé mímọ́” kì í ṣe ìwé kan ṣoṣo látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fi máa parí, ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló para pọ̀ di Bíbélì! Ìdí nìyẹn tí inú ọ̀pọ̀ èèyàn fi dùn láti ní àwọn orí àti ẹsẹ nínú Ìwé Mímọ́, èyí tó mú kó rọrùn láti tọ́ka sí àwọn ibi pàtó nínú Bíbélì, irú bí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí Pọ́ọ̀lù ti fa ọ̀rọ̀ yọ nínú àwọn lẹ́tà rẹ̀.

Èyí lè mú kó o máa béèrè pé, ‘ta ló fi àwọn orí àti ẹsẹ sínú Bíbélì?’

TA LÓ FI ÀWỌN ORÍ SÍNÚ BÍBÉLÌ?

Àlùfáà ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó ń jẹ́ Stephen Langton tó di Bíṣọ́ọ̀bù àgbà ní ìlú Canterbury ló ṣètò pípín Bíbélì sí àwọn orí. Àsìkò tó ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní yunifásítì ìlú Paris lórílẹ̀-èdè Faransé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹtàlá Sànmánì Kristẹni ló ṣe iṣẹ́ yìí.

Ṣáájú ìgbà ayé Langton ni àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ti ń lo oríṣiríṣi ọ̀nà láti pín Bíbélì sí àwọn ìsọ̀rí kéékèèké, bóyá kó lè rọrùn láti tọ́ka sí. Ìwọ náà lè fojú inú wo bó ṣe máa rọrùn tó fún wọn láti wá àyọkà kan nínú orí kan, dípò tí wàá fi ka gbogbo ìwé náà látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Bí àpẹẹrẹ, wo bó ṣe máa ṣòro tó láti wá àyọkà kan nínú ìwé Aísáyà tó ní orí mẹ́rìndínláàádọ́rin [66]!

Síbẹ̀, ìṣòro kan jẹ yọ́. Ńṣe ni àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n yìí pín Bíbélì sí onírúurú ìsọ̀rí tí kò bára mu. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan pín ìwé Ìhìn Rere Máàkù sí orí àádọ́ta [50] dípò orí mẹ́rìndínlógún [16] tá a ní báyìí. Nílùú Paris láyé Langton, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wá láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n sì gbé Bíbélì tí wọ́n ń lò lágbègbè wọn dání. Àmọ́, ó ṣòro fún àwọn olùkọ́ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti tọ́ka sí Bíbélì. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn ìsọ̀rí tí wọ́n pín Bíbélì kálukú sí kò bára mu.

Langton wá ṣètò ọ̀nà tuntun tó gbà pín Bíbélì sí ìsọ̀rí. Ìwé náà The Book—A History of the Bible sọ pé àwọn tó ń kàwé àtàwọn tó ń kọ̀wé gbádùn ọ̀nà tuntun tí Langton pín Bíbélì sí yìí, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í lo ọ̀nà tuntun yìí jákèjádò ilẹ̀ Yúróòpù. Ètò ìsọ̀rí tí Langton ṣe yìí ló wà nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì títí dòní.

TA LÓ FI ÀWỌN ẸSẸ SÍNÚ BÍBÉLÌ?

Ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Faransé tó ń jẹ́ Robert Estienne túbọ̀ mú kí kíká Bíbélì rọrùn. Ohun tó fẹ́ ni pé kí ọ̀pọ̀ èèyàn túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó rí i pé ó máa ṣàǹfààní tí àwọn orí àtàwọn ẹsẹ bá bára mu nínú gbogbo Bíbélì.

Estienne kọ́ ló kọ́kọ́ gbèrò láti pín Bíbélì sí àwọn ẹsẹ. Àwọn kan ti ṣe iṣẹ́ yẹn tẹ́lẹ̀. Láwọn ọgọ́rùn-ún ọdún díẹ̀ ṣáájú ìgbà ayé Estienne, àwọn adàwékọ tó jẹ Júù ti pín Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù táwọn èèyàn mọ̀ sí Májẹ̀mú Láéláé sí àwọn ẹsẹ, àmọ́ wọn kò fi orí sí i. Ìṣòro tó tún jẹ yọ ni pé onírúurú ọ̀nà tí kò bára mu làwọn èèyàn pín àwọn ẹsẹ inú Bíbélì sí.

Estienne wá pín Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì táwọn èèyàn mọ̀ sí Májẹ̀mú Tuntun sí àwọn ẹsẹ, ó sì ṣe é kó lè bara mu pẹ̀lú Májẹ̀mú Láéláé táwọn kan ti ṣe ṣáájú. Lọ́dún 1553, ó tẹ odindi Bíbélì àkọ́kọ́ jáde ní èdè Faransé, tó ní àwọn orí àtàwọn ẹsẹ. Ọ̀nà tó pín àwọn orí àtàwọn ẹsẹ Bíbélì sì ni ọ̀pọ̀ Bíbélì ń lò títí dòní. Àwọn kan wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí pé ńṣe làwọn ẹsẹ tí wọ́n pín Bíbélì sí mú kí Bíbélì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, ó wá dà bíi pé àwọn ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n jàn pọ̀ ló para pọ̀ dí Bíbélì. Àmọ́, àwọn òǹtẹ̀wé míì fara mọ́ ọ̀nà tí Estienne gbà tẹ Bíbélì rẹ̀, àwọn náà sì ṣe tiwọn bẹ́ẹ̀.

Ó ṢÀǸFÀÀNÍ FÁWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ

Ó dájú pé ó dáa bí àwọn orí àtàwọn ẹsẹ ṣe wà nínú Bíbélì. Ó ti mú kó rọrùn láti tọ́ka sí ẹsẹ kọ̀ọ̀kan tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Òótọ́ ni pé Ọlọ́run kọ́ ló mí sí bí wọ́n ṣe pín Bíbélì sí òrí àti ẹsẹ, àwọn ibi tí wọ́n sì ti pín in lè mú kó rí bákan nígbà míì. Síbẹ̀, ó ti mú kó rọrùn láti tètè rí àwọn ọ̀rọ̀ kan tá à ń wá tàbí ká fa ilà sí àwọn ẹsẹ tọ́rọ̀ inú rẹ̀ máa ń wọ̀ wá lọ́kàn.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn orí àtàwọn ẹsẹ tí wọ́n fi sínú Bíbélì ti mú kó túbọ̀ rọrùn, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé ohun tó ṣe pàtàkì ni pé ká lóye gbogbo ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lápapọ̀. Torí náà, jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ka àkópọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì dípò kó o máa dá ka àwọn ẹsẹ kọ̀ọ̀kan. Èyí máa jẹ́ kó o túbọ̀ lóye gbogbo “ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.”—2 Tímótì 3:15.