KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Kí Nìdí Tí Jésù Fi Jìyà Tó sì Kú?
“Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan [Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12
Kí lo máa sọ tí wọ́n bá bi ẹ́ pé, “Ṣé o fẹ́ wà láàyè títí lọ fáàbàdà?” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa sọ pé àwọn fẹ́ bẹ́ẹ̀. Àmọ́, bí ohun tí kò ṣeé ṣe nírú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa jọ lójú wọn. Wọ́n máa ń sọ pé awáyé máà kú ò sí.
Ká sọ pé wọ́n bi ẹ́ ní ìbéèrè yẹn lọ́nà míì, pé, “Ṣé o ti ṣe tán tó o fẹ́ kú?” Ó dájú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa dáhùn pé rárá o. Kí ni èyí fi hàn? Èyí jẹ́ ká rí i pé ó máa ń wu àwa èèyàn láti wà láàyè láìka ìṣòro yòówù ká máa kojú. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run dá wa lọ́nà táá fi wù wá láti máa wà láàyè. Kódà ó sọ pé, “àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà wọn.”—Oníwàásù 3:11.
Àmọ́ ní báyìí, àwa èèyàn ń kú. Kí ló fà á? Ǹjẹ́ Ọlọ́run ti ṣe ohunkóhun láti gbà wá lọ́wọ́ ikú? Bíbélì fún wa láwọn ìdáhùn tó ń fini lọ́kàn balẹ̀, àwọn ìdáhùn náà sì jẹ́ ká mọ ìdí tí Jésù fi jìyà tó sì kú.
BÍ NǸKAN ṢE DOJÚ RÚ
Orí mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà, láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Ó sì sọ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè máa wà láàyè nìṣó. Àkọsílẹ̀ náà sọ bí wọ́n ṣe ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, tí wọ́n sì pàdánù àǹfààní yẹn. Torí pé Bíbélì kàn sọ ìtàn náà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, àwọn kan sọ pé ìtàn àròsọ lásán ni. Àmọ́, bí àwọn àkọsílẹ̀ ìwé Ìhìn Rere ṣe jẹ́ òótọ́ pọ́ńbélé, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àkọsílẹ̀ inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì jẹ́ òótọ́ pọ́ńbélé. *
Kí wá ni àbájáde àìgbọràn Ádámù? Bíbélì dáhùn pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Ádámù di ẹlẹ́ṣẹ̀ torí pé ó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ó tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù àǹfààní tó ní láti wà láàyè títí láé, ó sì kú nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Torí pé àtọmọdọ́mọ Ádámù ni wá, a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ rẹ̀. Èyí sì máa ń mú ká ṣàìsàn, ká darúgbó, ká sì kú. Àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa ìdí tá a fi ń kú bá ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ mu, ìyẹn ni pé ohun tí àwọn òbí bá ní ni ọmọ máa jogún. Àmọ́, ǹjẹ́ Ọlọ́run ti ṣe ohunkóhun láti gbà wá lọ́wọ́ ikú?
OHUN TÍ ỌLỌ́RUN TI ṢE
Ọlọ́run ṣètò láti ra ohun tí Ádámù gbé sọnù pa dà fún àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀, ìyẹn ni àǹfààní láti wà láàyè títí lọ fáàbàdà. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ṣe èyí?
Ìwé Róòmù 6:23 sọ pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” Èyí fi hàn pé ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀. Ádámù dẹ́ṣẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi kú. Bẹ́ẹ̀ ni àwa náà jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ìdí sì nìyẹn tá a fi ń kú. Àmọ́, kì í ṣe ẹ̀bi wa pé a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ torí pé ńṣe la jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́. Ṣùgbọ́n torí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ó rán Jésù Ọmọ rẹ̀ kó lè wá san ‘owó ọ̀yà ẹ̀ṣẹ̀’ náà nítorí wa. Báwo ni èyí ṣe ṣeé ṣe?
Ádámù tó jẹ́ ẹni pípé ṣàìgbọràn, èyí ló fa ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Torí náà, ká tó lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, a nílò ẹni pípé tó máa jẹ́ onígbọràn títí dójú ikú. Bíbélì ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà yìí: “Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ àìgbọràn ènìyàn kan ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a sọ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bákan náà pẹ̀lú ni ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbọràn ènìyàn kan, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a ó sọ di olódodo.” (Róòmù 5:19) Jésù ni ẹnì kejì tí Bíbélì yìí ń tọ́ka sí. Ó fi ọ̀run sílẹ̀, ó di èèyàn tí kò lẹ́ṣẹ̀ *, ó sì kú fún wa. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wa láti rí ojúure Ọlọ́run, ká sì nírètí láti wà láàyè títí lọ fáàbàdà.
ÌDÍ TÍ JÉSÙ FI JÌYÀ TÓ SÌ KÚ
Kí wá nìdí tó fi pọn dandan kí Jésù kú kó tó lè gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú? Ṣé Ọlọ́run ò kàn lè sọ pé kí àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù máa wà láàyè títí lọ? Ó kúkú lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ èyí máa ta ko òfin tó sọ pé ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀. Òfin yìí kì í sì ṣe òfin tó ṣeé fọwọ́ rọ́ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan tàbí tó ṣeé yí pa dà nígbàkigbà. Títẹ̀lé òfin yìí máa fi hàn pé Ọlọ́run ń ṣe ìdájọ́ òdodo.—Sáàmù 37:28.
Tí Ọlọ́run bá gbójú fo ìdájọ́ òdodo nínú ọ̀rọ̀ yìí, èyí lè mú ká máa ronú pé bóyá ni Ọlọ́run ò ni gbójú fo ìdájọ́ òdodo nínú àwọn ọ̀rọ̀ míì tó ṣe pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, ṣé Ọlọ́run máa ṣe ìdájọ́ tó yẹ tó bá fẹ́ pinnu àwọn tó máa wà láàyè títí láé nínú
àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù? Ṣé ọkàn wa máa balẹ̀ pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ? Àmọ́, Ọlọ́run ò gbójú fo ìdájọ́ òdodo nínú bó ṣe ṣètò ìgbàlà fún wa. Èyí sì jẹ́ kó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ni Ọlọ́run máa ṣe ohun tó tọ́.Nípasẹ̀ ikú Jésù, Ọlọ́run ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún wa ká lè wà láàyè títí lọ fáàbàdà nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Jésù sọ nínú ìwé Jòhánù 3:16 pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Ikú Jésù jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run kì í bo ìdájọ́ òdodo mọ́lẹ̀, àmọ́ ní pàtàkì ó jẹ́ ká rí i pé ìfẹ́ tó jinlẹ̀ ni Ọlọ́run ní fún àwa èèyàn.
Ṣùgbọ́n, kí nìdí tí Jésù fi jẹ adúrú ìyà tó jẹ láyé tó sì tún wá kú ikú oró bí àwọn ìwé Ìhìn Rere ṣe sọ? Sátánì Èṣù sọ pé kò sẹ́ni tó máa jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run tó bá rí àdánwò, àmọ́ bí Jésù ṣe jẹ adúrú ìyà yẹn títí tó fi kú fi hàn pé irọ́ gbuu ni Èṣù pa. (Jóòbù 2:4, 5) Ohun tí Sátánì sọ yìí jọ òótọ́ nígbà tó tan Ádámù tó jẹ́ ẹni pípé láti dẹ́ṣẹ̀. Àmọ́, Jésù tóun náà jẹ́ ẹni pípé bíi ti Ádámù jẹ́ olóòótọ́ láìka adúrú ìyà tó jẹ. (1 Kọ́ríńtì 15:45) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé Ádámù náà lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run ká sọ pé ó pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí Jésù ṣe fara da àdánwò jẹ́ àpẹẹrẹ tó yẹ ká tẹ̀ lé lónìí. (1 Pétérù 2:21) Ọlọ́run wá san ọmọ rẹ̀ lẹ́san torí ìgbọràn rẹ̀ nípa fífún un ní àìleèkú ní ọ̀run.
BÓ O ṢE LÈ JÀǸFÀÀNÍ
Lóòótọ́ ni Jésù kú. Ní báyìí, ọ̀nà ìyè ayérayé ti ṣí sílẹ̀. Ṣé ó wù ẹ́ láti wà láàyè títí lọ fáàbàdà? Jésù sọ ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe, ó ní: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.
Àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí ń rọ̀ ẹ́ pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ àti Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. O sì tún lè rí ìsọfúnni tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lórí ìkànnì wa, ìyẹn www.jw.org/yo.
^ ìpínrọ̀ 8 Wo àkòrí tá a pè ní “The Historical Character of Genesis,” nínú ìwé Insight on the Scriptures, Apá kìíní, ojú ìwé 922. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
^ ìpínrọ̀ 13 Ọlọ́run fi ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ sínú Màríà, ó sì lóyún. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run sì dáàbò bo Jésù kó máa bàa jogún ẹ̀ṣẹ̀ látara Màríà.—Lúùkù 1:31, 35.