KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NÌDÍ TÍ JÉSÙ FI JÌYÀ TÓ SÌ KÚ?
Ṣé Lóòótọ́ Ló Ṣẹlẹ̀?
Wọ́n pa Jésù ará Násárétì nígbà ìrúwé ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn án ni pé ó dìtẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì lù ú ní àlùbami kí wọ́n tó kàn án mọ́gi. Ikú oró ló kú. Àmọ́, Ọlọ́run jí i dìde, ó sì pa dà sí ọ̀run lẹ́yìn ogójì [40] ọjọ́ tó jíǹde.
Inú ìwé Ìhìn Rere Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù ni ìtàn yìí wà. Àmọ́ ṣé lóòótọ́ ló ṣẹlẹ̀? Ìbéèrè pàtàkì lèyí jẹ́, torí pé tí kò bá ṣẹlẹ̀, á jẹ́ pé alá tí kò lè ṣe ni ìrètí tí àwa Kristẹni ní pé ayé máa di Párádísè, asán sì ni ìgbàgbọ́ wa. (1 Kọ́ríńtì 15:14) Lọ́wọ́ kejì, tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí bá wáyé lóòótọ́, á jẹ́ pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa fún àwa èèyàn, a sì máa ní láti sọ nípa rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíì. Torí náà, ṣé òótọ́ pọ́ńbélé lohun tí àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nípa Jésù àbí ìtàn àròsọ lásán ni?
OHUN TÍ Ẹ̀RÍ FI HÀN
Àwọn ìwé Ìhìn Rere yìí kò dà bí àwọn ìwé ìtàn àròsọ, torí pé ó ṣe àwọn àkọsílẹ̀ tó péye àti àwọn àlàyé tó kún rẹ́rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sọ orúkọ oríṣiríṣi ìlú tó ṣì wà títí dòní. Wọ́n tún sọ nípa àwọn èèyàn tó gbé ayé nígbà yẹn, tí àwọn òpìtàn ayé àtijọ́ náà sì sọ̀rọ̀ nípa wọn.—Lúùkù 3:1, 2, 23.
* Ohun tí àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere sọ nípa bí wọ́n ṣe pa Jésù bá ọ̀nà tí àwọn ará Róòmù máa ń gbà pa àwọn èèyàn nígbà yẹn mu. Láfikún sí i, kò sí àbùmọ́ tàbí àyọkúrò èyíkéyìí nínú ohun tí wọ́n kọ. Kódà, wọ́n sọ ìwà tó kù díẹ̀ káàtó tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fúnra wọn hù. (Mátíù 26:56; Lúùkù 22:24-26; Jòhánù 18:10, 11) Gbogbo èyí fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé ni àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere sọ nípa Jésù, ó sì péye.
Àwọn òǹkọ̀wé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti ìkejì pàápàá sọ̀rọ̀ nípa Jésù.ÀJÍǸDE JÉSÙ WÁ Ń KỌ́?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ gbà pé Jésù gbáyé ó sì kú, síbẹ̀ àwọn kan ò gbà pé Jésù jíǹde. Kódà, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kò kọ́kọ́ gbà gbọ́ nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jésù ti jíǹde. (Lúùkù 24:11) Àmọ́ wọ́n kò ṣiyèméjì mọ́ nígbà tí wọ́n rí Jésù ní àsìkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lẹ́yìn tó jíǹde. Ó tiẹ̀ nígbà kan tí Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] lọ.—1 Kọ́ríńtì 15:6.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù mọ̀ pé àwọn lè fẹ̀wọ̀n gbára tàbí kí wọ́n pa àwọn, síbẹ̀ wọ́n fi ìgboyà sọ nípa àjíǹde Jésù fún gbogbo èèyàn, kódà fún àwọn tó ṣekú pa Jésù. (Ìṣe 4:1-3, 10, 19, 20; 5:27-32) Ṣé ó máa ṣeé ṣe fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ní irú ìgboyà bẹ́ẹ̀ tí kò bá dá wọn lójú pé Jésù ti jíǹde? Torí pé Jésù jíǹde lóòótọ́ ló mú kí ẹ̀sìn Kristẹni lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nígbà yẹn àti lóde òní.
Àwọn ẹ̀rí fi hàn pé òótọ́ tí kò ṣeé já ní koro ni àwọn àkọsílẹ̀ nípa ikú àti àjíǹde Jésù tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Tá a bá fara balẹ̀ ka àwọn ìwé Ìhìn Rere yìí, ó máa dá wa lójú pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Ìgbàgbọ́ tá a sì ní máa túbọ̀ lágbára sí i tá a bá mọ ìdí tí wọ́n fi ṣẹlẹ̀. Àpilẹ̀kọ tó kàn máa ṣàlàyé èyí.
^ ìpínrọ̀ 7 Tacitus, tí wọ́n bí ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Kristẹni kọ̀wé pé “Kristi táwọn Kristẹni fi sọ ara wọn lórúkọ ni Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn baálẹ̀ wa dájọ́ ikú fún tí wọ́n sì pa nígbà ìjọba Tìbéríù.” Àwọn míì tó tún mẹ́nu kan Jésù ni Suetonius tó gbáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní; òpìtàn Júù náà Josephus tó gbáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti Pliny Kékeré tó jẹ́ gómìnà Bítíníà tó gbáyé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kejì.