ILÉ ÌṢỌ́ No. 1 2025 | Ṣé Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Kò Ní Sí Ogun Mọ́?
Ṣé ó wù ẹ́ kí ogun àti rògbòdìyàn di ohun ìgbàgbé láyé? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wù kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ wọ́n gbà pé àlá tí kò lè ṣẹ ni. Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí táwọn èèyàn ò fi lè fòpin sí ogun àti rògbòdìyàn. Ó tún jẹ́ kó dá wa lójú pé àlàáfíà máa wà níbi gbogbo kárí ayé, kódà kò ní pẹ́ mọ́.
Nínú ìwé yìí, tá a bá lo ọ̀rọ̀ náà “ogunʺ àti “rògbòdìyàn,ʺ à ń tọ́ka sí ìjà láàárín àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń lo ohun ìjà láti gbógun ti ara wọn. A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú ìwé yìí.
Ogun Kì Í Bímọọre
Sójà àtàwọn ará ìlú ló máa ń fara gbá aburú tó máa ń tẹ̀yìn ogun yọ.
Gbogbo Wa Ni Ogun àti Rògbòdìyàn Ń Ṣàkóbá Fún
Ogun máa ń ba nǹkan jẹ́ gan-an, ó sì máa ń sọ orílẹ̀-èdè di ẹdun arinlẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan.
Ṣé Àwa Èèyàn Lè Fòpin sí Ogun àti Rògbòdìyàn?
Àwọn èèyàn ṣì ń wá bí wọ́n ṣe máa fòpin sí ogun àti rògbòdìyàn, àmọ́ ṣé wọ́n máa ṣàṣeyọrí?
Ìdí Táwọn Èèyàn Ò Fi Lè Dáwọ́ Ogun àti Rògbòdìyàn Dúró
Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí tí ogun àti rògbòdìyàn fi ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé.
Bí Ogun àti Rògbòdìyàn Ṣe Máa Dópin
Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí ogun kárí ayé, á sì mú kí àlàáfíà àti ìfọkànbalẹ̀ wà láyé.
Ọkàn Ẹ Lè Balẹ̀ Láìka Ohun Tí Ogun àti Rògbòdìyàn Ti Fojú Ẹ Rí
Bíbélì ń ran àwọn tí ogun ti hàn léèmọ̀ lọ́wọ́ kí ọkàn wọn lè balẹ̀.
Ṣé O Ti Béèrè Àwọn Ìbéèrè Yìí Rí?
Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí kò ní sí ogun mọ́? Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè mí ì, àwọn ìdáhùn náà sì máa tù ẹ́ nínú.

