ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ October 2017

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti November 27 sí December 24, 2017, ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Bá Ṣe Ìfẹ́ Rẹ̀

Lọ́dún 1952, Olive Matthews àti ọkọ rẹ̀ gbà láti lọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè Ireland. Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún wọn?

“Kí A Nífẹ̀ẹ́ . . . ní Ìṣe àti Òtítọ́”

Báwo la ṣe lè fi hàn pé ìfẹ́ tá a ní dénú, ó sì jẹ́ látọkàn?

Idà Ni Òtítọ́ Ń Mú Wá, Kì Í Ṣe Àlàáfíà

Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé òun mú idà wá, báwo ló sì ṣe kàn ẹ́?

Jósẹ́fù ará Arimatíà Lo Ìgboyà

Ta ni Jósẹ́fù ará Arimatíà? Kí ló pa òun àti Jésù pọ̀? Kí lo lè rí kọ́ nínú ìtàn yìí?

Bí Àwọn Ìran Tí Sekaráyà Rí Ṣe Kàn Ẹ́

Àkájọ ìwé kan tó ń fò lókè, obìnrin kan tí wọ́n dé mọ́nú apẹ̀rẹ̀ ńlá, àtàwọn obìnrin méjì tí wọ́n ní ìyẹ́ apá bíi ti ẹyẹ àkọ̀, tí wọ́n sì ń fò lójú ọ̀run. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí Sekaráyà rí àwọn ìran tó lágbára yìí?

Àwọn Kẹ̀kẹ́ Ẹṣin àti Adé Kan Ń Dáàbò Bò Ẹ́

Àwọn òkè bàbà, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí wọ́n fi ń jagun àti àlùfáà àgbà tó di ọba. Kí ni ìran tí Sekaráyà rí kẹ́yìn fi dá àwọn èèyàn Ọlọ́run lójú lónìí?

Oore Kan Tó Sèso Rere

Báwo ni inú rere tẹ́nì kan ṣe ṣe mú kí ẹni tó ń ta ko àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí nìdí tí Jésù fi dẹ́bi fún àwọn tó ń búra?