ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ October 2016

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti November 28 sí December 25, 2016 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Tó Dáa

Ìṣírí táwọn Kristẹni tó dàgbà dénú bá fún wa lè mú ká láfojúsùn gidi. Thomas McLain sọ báwọn kan ṣe fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún un àti bóun náà ṣe ran àwọn mí ì lọ́wọ́.

“Ẹ Má Gbàgbé Aájò Àlejò”

Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo àwọn àjèjì? Kí lo lè ṣe láti ran àwọn tó wà láti ilẹ̀ àjèjì lọ́wọ́ kára wọn lè mọlé níjọ wa?

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Rẹ Jó Rẹ̀yìn Tó O Bá Ń Sìn Nílẹ̀ Àjèjì

Ohun tó ṣe pàtàkì jù sáwa Kristẹni ni kí ìgbàgbọ́ wa àti ti ìdílé wa fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa. Àmọ́ àwọn ìṣòro kan wà téèyàn máa ní tó bá wà níjọ tó ń sọ èdè àjèjì.

Ǹjẹ́ Ò Ń “Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ọgbọ́n Tí Ó Gbéṣẹ́”

Kí ló mú kí ọgbọ́n yàtọ̀ sí ìmọ̀ àti òye? Mímọ ìyàtọ̀ yìí máa ṣe ẹ́ láǹfààní.

Bó O Ṣe Lè Mú Kó Túbọ̀ Dá Ẹ Lójú Pé Ìlérí Ọlọ́run Máa Ṣẹ

Àpẹẹrẹ àwọn tó nígbàgbọ́ láyé àtijọ́ àti lóde òní lé fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Báwo lo ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ rẹ lágbára?

Máa Lo Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà

Kí ni ìgbàgbọ́? Ní pàtàkì jù lọ, báwo lo ṣe lè lo ìgbàgbọ́?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Báwo ni agbára táwọn Róòmù fún ilé ẹjọ́ àwọn Júù ní ọgọ́rùn-⁠ún ọdún kìíní ṣe pọ̀ tó? Ṣé lóòótọ́ ni pé láyé àtijọ́ àwọn kan máa ń fún èpò sínú oko ẹlòmí ì?